Oluwo fi ohùn ránṣẹ́ sí Oyetola lórí ọ̀nà Osogbo-Iwo-Ibadan

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo
Oluwo ti ilu Iwo, Oba Abdulrosheed Adewale Akanbi, Telu Kinni ti ke sawọn oloṣelu lati dẹkun titi ọwọ oṣelu bọ idagbasoke ilu.
Oluwo ni iwa bẹẹ maa n fa aago idagbasoke ilu sẹyin ni.
Oluwo tun ke si ijọba ipinlẹ Osun lati ṣe atunṣe oju ọna Osogbo si Iwo si Ibadan.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Alli Ibraheem fi ṣọwọ si fawọn akọroyin ni Oluwo ti sọ ọrọ naa.
Gẹgẹ bii Oluwo ti sọ, atunṣe oju ọna ọhun yoo tubọ jẹ ki eto ọrọ aje laarin ipinlẹ Oyo ati Osun burẹkẹ si.
Oluwo ni opopona Osogbo-Iwo-Ibadan ni opopona kan ṣoṣo to so ipinlẹ Eko pọ mọ ilu Ibadan ati Osun.
O ni anfani nla si ni opopona naa n ṣe fun Naijiria ati agbegbe to wa.
“Bo tilẹ jẹ pe mo gboriyin fun ijọba ipinlẹ Osun ati Oyo fun ibaṣepọ wọn lori opopona ọhun.
Amọ mi o fẹ ki wọn fi akoko kankan ṣofo lori atunṣe ọna naa rara.”
Oluwo ṣalaye pe atunṣe ọna ọhun yoo ran eto ọrọ aje ipinlẹ Osun lọwọ.
O ni eyi yoo si mu aye dẹrun fun awọn araalu to n gba oju ọna naa ni gbogbo igba.
"Opopona ti ko ba dara ni ọdaran fi n se ibuba"
Oluwo fikun pe “Ipo ti opopona naa wa ti mu ki ọpọ awọn oniṣowo yẹba fun ipinplẹ Osun.
O ni eyi ri bẹẹ nitori bo ṣe so ilu Osogbo-Iwo-Ibadan papọ, ti ko si si ọna miran ti wọn le gba.”
“Opopona yii lo so ipinlẹ Osun pọ mọ ọpọ awọn ipinlẹ mii, nitori naa, o yẹ ki awọn to n fẹ ilọsiwaju ilu gbe ọrọ oṣelu ti sẹgbẹ, ki wọn si ṣatunṣe opopona ọhun.”
Oluwo pari ọrọ rẹ pe opopona ti ko ba dara, ni awọn ọdaran maa n fi ṣe ibuba.
Lẹyin naa lo ke si gomina Gboyega Oyetola lati tete wa nnkan ṣe si oju naa, ki inu awọn eeyan ipinlẹ Osun le dun.














