To bá ń ta Naira tàbí ra Naira lójú agbo ìnáwó, o ti wọ gàù - CBN

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Banki apapọ orilẹede Naijiria, CBN ti bẹrẹ si ni fi ọwọ ṣinku ọlọpaa mu ẹnikẹni to ba n ta owo orilẹede Naijiria, Naira nibi inawo.
Bi o tilẹ jẹpe asa to wọpọ ni ki awọn eniyan maa ra owo Naira tuntun nibi ayẹyẹ ni Naijiria, eleyii ti wọn yoo na loju agbo.
O kere tan eniyan mẹrinla ni ọwọ tẹ ni ilu Kano nibi ti wọn ti n ṣẹ owo .
Orukọ wọn ni Alhaji Ubandi Hotoro, Haruna Yahaya, Rabiu Ibrahim,Ismaila Umar,Nura Aminu,Nasiru Adamu, ati Nazef Lawal.
‘Eeyan mẹrinla tọwọ wa tẹ, to n ra Naira loju agbo yoo foju wina ofin ’’
Ajọ eleto aabo DSS ni ọwọ awọn tẹ awọn wọnyii lasiko ayẹyẹ ni ilu Kano, ti awọn si mu eniyan mẹrinla to fi mọ ọbinrin kan.
Ẹsun ti wọn fi kan awọn ti ọwọ tẹ yii ni tita ati rira owo lọna aitọ.
Adari ikọ NSCDC ni ilu Kano, Adamu Zakari ni wọn ti fi oju awọn eniyan han ki awọn eniyan le kọ ẹkọ lara wọn.
Wọn ni tita Naira tuntun tako ofin CBN Act, Section 20 to ni ko gbọdọ si tita, rira abi ki wọn gbe igba atẹ owo Naira.
Gbogbo owo ti araalu ba fẹ gba gbọdọ jẹ lati banki.
Iwadii ti n lọ lọwọ lati mọ bi awọn owo wọnyii ṣe n jade ninu banki ti wọn yoo si fi awọn to ba rufin jofin.















