Mo yá $50k fún ìgbáradì ìdíje 2022 World Championships – Tobi Amusan

Oríṣun àwòrán, oluwatobiloba_amusan/Instagram
Tobi Amusan to gba ami ẹyẹ idije ere sisa ọlọgọrun mita (Women 100m hurdles) ti sọ iriri rẹ ati bo ṣe di alami ẹyẹ naa.
Amusan, to sọrọ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, ni oun gba ẹyawo to le ni ẹgbẹrun lọna aadọta Dọla ($50,000) lati ṣe igbaradi fun igbaradi idije ere sisa lagbaye (World Athletics Championship).
Ọjọ Iṣẹgun ni wọn ṣe atunṣe si iye akoko to lo lati fi sare nigba akọkọ to lọ sare.
Dipo iṣẹju aaya 12s. 06ms ti wọn kọ silẹ fun pe o lo nigba to kọkọ sare naa lati gba ami ẹyẹ, 12s.12ms ni wọn kọ silẹ fun bayii pe o lo lati fi sare naa, lati pari idije agbaye naa.
Amusan lo di ọmọ Naijiria akọkọ yoo gba ami ẹyẹ lanti lanti naa, ti aarẹ Buhari si ti fun ni ami ẹyẹ idanimọ.
"Bi mo ṣe gbaradi fun Idije Agbaye 2022 World Championship ni yii..."
Lasiko to n sọrọ nigba igbaradi rẹ, o ni oun ṣiṣẹ takun takun saaju idije naa.
Amusan to fakọ yọ ni Oregon lo ni, oun saba ma n farapa nitori ere idaraya ti oun yan laayo.
O ni nitori naa ni oun se gba ẹyawo lati ri pe ara oun duro kampe lati wa ni ipo to yẹ fun idije naa.
"Bẹẹ ni mo n ṣèṣe ni ọpọlọpọ igba, ti mo si mọ pe ilera mi ku diẹ kaato.
Ati wa loke tente ninu iṣẹ ti mo yan laayo nilo owo, nitori naa, ni mo se ya owo lati ri pe ilera mi wa nibamu, ki idije to bẹrẹ."
Ọṣẹ to kọja ni aarẹ Buhari fun Tobi Amusan ni ami ẹyẹ Officer of the Order of the Niger (OON) ti orilẹede Naijiria.
Ninu ọrọ rẹ, Amusan ni idunnu ati ayọ lo jẹ fun oun lati ri pe Aarẹ Buhari fun oun ni ami ẹyẹ naa ati pe oun gbe orukọ orilẹede Naijiria ga.












