Nàíjíríà méjì ló wà, kí Yorùbá gba òmìnira lọ̀nà àbáyọ - Akintoye

Banji Akintoye

Adari ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti sọ pe ki Naijiria pin nikan ni ọna abayọ si rukerudo to n waye kaakiri, paapaa lori eto abo to mẹhẹ.

Ọrọ yii lo jade lẹyin ọjọ kan ti gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu kede pe ijọba oun yoo ra ibọn fun ikọ Amotekun fun aabo awọn araalu.

Atẹjade kan ti Akintoye fi ṣọwọ si BBC Yoruba lati ọwọ agbẹnusọ ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Maxwell Adeleye lo sisọ loju eleyi.

Ak intoyeni ko si irọ kankan ninu gbogbo ohun ti Akeredolu sọ nipa ojuṣaju to n waye ni Naijiria.

O ni otitọ ni Akeredolu sọ pe Naijiria meji lo wa, apa kan fun awọn alẹnulọrọ, ati ida keji rẹ fun awọn ti wọn n tẹ ẹtọ wọn loju mọlẹ.

Akintoye sọ pe awọn ẹya kan ko ni imọ nipa bo ṣe yẹ ki wọn maa dari Naijiria lo n jẹ ki oniruru laasigbo maa waye, asiko si ti to lati yago fun wọn.

"Ọna abayọ kan ṣoṣo si iṣoro Naijiria ni pe ki Yoruba gba ominira"

Ọjọgbọn naa ṣalaye pe ọna abayọ kan ṣoṣo si rogbodiyan to n waye ni Naijiiria, paapaa oniruru ifẹmiṣofo, ni ki Naijiria pin.

O ni “O yẹ ki gbogbo wa joko ki a si jiroro lori bi ọjọ ọla wa yoo ṣe ri gẹgẹ orilẹ-ede.”

“O si yẹ ki a fẹnuko pe a fẹ pinya, ki a si jiroro lori bi a o ṣe wa ni alaafia pẹlu ara wa lẹyin ti a ba pin tan lai si ogun tabi ọtẹ.”

“Ko si angẹli kankan lati ọrun to le mu iṣọkan wa ni Naijiria mọ bayii.”

“Awọn ọmọ iya wa ti wọn fẹ dije du ipo oṣelu, ọrọ wọn ye mi, nitori inu Naijiria naa ni a ṣi wa amọ ọna odi ni wọn n gbe ọrọ naa gba.”

“Ohun to yẹ ki wọn ṣe ni ki wọn ba awọn eeyan wọn sọrọ lori bi a ṣe maa gba ominiri wa, ki a si ni orilẹ-ede eyii ti kii ṣe ara Naijiria.”

Ohun ti Akeredolu sọ saaju ree nipa amulo ilana ofin meji tijọba apapọ n se:

Bí Katsina bá ra AK47 fáwọn ẹ̀ṣọ́ abẹ́lé rẹ̀, kí ló dí Amotekun lọ́wọ́ láti lo ìbọn? - Akeredolu

Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, @thesignalng

Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe oun ti ṣetan lati ra ohun ija oloro, paapaa ibọn AK-47 fun aabo awọn eeyan oun.

Gomina Rotimi Akeredolu lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Twitter ati Facebook rẹ.

Aketi sọ pe ko ṣeeṣe ki orilẹ-ede jẹ ọkan ṣoṣo, ko si maa fi ofin ọtọtọ ba awọn eeyan rẹ lo.

Ọrọ yii lo n jade lẹyin ti ijọba apapọ kọ lati gba ikọ alabo Amotekun laaye lati maa lo ohun ija oloro.

"Ijọba apapọ n ṣe ojuṣaju laarin awọn ipinlẹ to jọba le lori"

Akeredolu sọ pe oun ti ri fidio kan nibi ti ijọba apapọ ti fun ikọ alaabo ipinlẹ Katsina laṣẹ, lati maa lo ibọn Ak-47.

Amọ o ni o kọ jalẹ pe ki ikọ Amotekun naa ma lo ibọn.

O ni “Pe ikọ alaabo ipinlẹ Katsina le maa lo ibọn Ak-47, ti ikọ alaabo Amotekun ko si le ṣe bẹẹ, tumọ si pe ofin ọtọtọ ni a n lo lorilẹ-ede yii.”

Akeredolu sọ pe igbesẹ naa n tumọ si pe ijọba apapọ n ṣe ojuṣaju laarin awọn ipinlẹ to jọba le lori.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

"A ti ṣetan lati ra ibọn fun abo awọn eeyan wa"

Aketi ni “A fẹ ki gbogbo araalu mọ pe, ko si bi ọbọ ṣe ṣ’ori ti inaki naa ko ṣe o.”

“Ijọba ipinlẹ Ondo ti ṣetan bayii, gẹgẹ bii ojuṣe rẹ labẹ ofin, lati ra ibọn fun abo awọn eeyan rẹ.”

“Igbesẹ yii ṣe pataki, paapaa lasiko yii ti awọn agbesumọmi n ra ibọn bo ṣe wu wọn.”

O pari ọrọ rẹ pe “Ijọba ipinlẹ yii ko ni la oju rẹ silẹ ki awọn agbesumọmi maa pa awọn eeyan wa ni ipakuta lai wa nnkan ṣe si.”

“A o daabo bo awọn eeyan wa.”

Atẹjade ti gomina Rotimi Akeredolu fisita

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu