Wo ọmọ Nàíjíríà tó ń gbèjà ilẹ̀ Baba rẹ̀ lọ́wọ́ àbùkù àti ìkórira pẹ̀lú ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu
Deji Ige: Bí mo kúrò ní Nàíjíríà, ọkàn mi kò kúrò torí tá à bá tún ilé ṣe, ọjọ́ iwájú kò ní dárí jìn wá

Owe Yoruba kan lo ni nibi ti n pa ọ wa, ni n o gba ọ wa nitori eeyan meji kii binu iyọ lọja, bi eeyan kan ba tu, eeyan kan yoo.
Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ọmọ Naijiria lo n wa bi wọn yoo se sa kuro lorilede yii, paapaa awọn ọdọ amọ ọkunrin kan ree, to ni afori-afọrun, Naijiria ni oun yoo duro ti.
Deji Ige nii se onkọwe ati akewi, to si n lo ijinlẹ ede Yoruba ati Gẹẹsi lati tako iwa abuku ati ikorira ti ọpọ ọmọ Naijiria n hu silẹ baba wọn.
Nigba to n ba BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, Deji Ige salaye idi to se n gbe igbesẹ yii, to se n fi ijinlẹ ede tun oruk ati ayanmọ Naijiria se nile ati lẹyin odi.
Gẹgẹ bi Ige ti wi, bi oun tilẹ kuro ni Naijiria, ko seese lati ko gbogbo ẹbi oun tabi ọkan oun kuro nitori tiwa n tiwa, akisa ni ti aatan.
Idi ree ti mo se n fi ede ẹnu gbeja Naijiria – Deji Ige
Ninu alaye rẹ, Deji Ige ni isẹ ologun lo kọkọ wu oun lati se ni aarọ ọjọ aye oun, ti oun si gbiyanju nigba mẹrin ọtọọtọ amọ ti wọn ko gba oun si isẹ ologun.
O ni idi ree ti oun se mu gege ikọwe oun lati maa se awọn akọsilẹ ọpọ isẹlẹ to n waye lorilẹede yii, boya ire abi ibi.
Ige ni lati ipasẹ eyi ni oun ti bẹrẹ si ni sọrọ kaakiri agbaye, boya lori redio ni tabi mohunmaworan, ti ohunsi tun n fi ewi gba a lẹgbẹ.
“Ebi lo n ba ọpọ eeyan finra ni Naijiria, ti ọwọn gogo epo si ti di ọmọ Naijiria, ojoojumọ lawọn olukọ fasiti n dasẹ silẹ, tawọn osisẹ ilera si n sa kuro lorilede yii.”
Mo n ri awọn isẹlẹ to n waye ni agbegbe mi, idi ree ti ẹnu mi ko fi le dakẹ si ọpọ awọn aidaa to n waye naa.
Amọ ti mo ba ri ohun to dara nipa Naijiria, ko yẹ ki n dakẹ nitori ba se n ri aidaa, naa la n ri awọn ohun to dara.”
O salaye pe oun gbọgbọ pe akọsilẹ oun ni lati di gbajumọ asọrọgbayi nitori oun ko lero pe isẹ miran wa, ti ko ba gbe oun de ibi ti oun de lonii yii.
“Ọrọ Naijiria jẹ mi logun, tori ko sibi to dabi ile”






