Ìjọba Buhari gbé owó tabua wá fún Igboho, pé kó dẹ̀yìn lẹ́yìn Yoruba Nation àmọ́ ó kọ̀ jálẹ̀ - Akintoye
Banji Akintoye: Ìfẹ́ ará àríwá sí Tinubu kò dénú, wọ́n le kẹ̀yìn si láti dìbò fún Atiku

Oríṣun àwòrán, @thecableng
Adari ẹgbẹ ajijagbara Yoruba Nation, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti sọ pe ẹṣin aayan lasan ni awọn oloṣelu iha Ariwa Naijiria n gbe Bola Ahmed Tinubu gun lẹyin ti wọn sọ pe awọn ṣe atilẹyin fun lati di Aarẹ Naijiria lọdun to n bọ.
Akintoye ni oun gbagbọ pe laipẹ lai jina, awọn oloṣelu naa yoo kọ ẹyin si Tinubu lati ṣalitlẹyin fun ọmọ wọn to jẹ oludije ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar.
Ọjọgbọn Akintoye lo sọ ọrọ naa ninu ifẹrọwerọ pẹlu ileesẹ iroyin BBC Yoruba ni Benin Republic.
O ni lootọ ni pe awọn eeyan kan le ma woye pe o yẹ ki wọn jawọ ninu ọrọ Yoruba Nation lati ṣatilẹyin fun Tinubu nitori o jẹ ọmọ ilẹ Yoruba, amọ ẹtanjẹ lasan ni.
Akintoye sọ pe “Awọn kan le maa sọ pe ẹ jẹ ka ṣatilẹyin fun Tinubu nitori ọmọ Yoruba ara wa naa ni... ẹ jẹ ka dan wo boya yoo ṣe daadaa, amọ ti ẹ ba wo finni-finni, wọn kan n tan Tinubu jẹ ni.”
“Fun apẹrẹ, awọn eeyan PDP sọ pe awọn ko gbagbo ninu ki a maa pin ipo Aarẹ si ẹlẹkunjẹkun, ṣugbọn ni kete ti Atiku jawe olubori gẹgẹ ẹni ti yoo dije ninu ẹgbẹ PDP ni awọn gomina iha Ariwa ni awọn yoo ṣatilẹyin fun Tinubu.”
“Irọ ni o, wọn kan ṣatilẹyi fun Tinubu pẹlu ẹnu lasan ni, Atiku ni wọn maa dibo fun, fun idi eyi, ko tọ ki a pa ilepa wa fun Yoruba Nation ti nitori pe Tinubu fẹ du ipo Aarẹ.”
Aburo mi ni Tinubu, amọ mi o fọwọ si ko di Aarẹ
Nipa ibaṣepọ to wa laarin Ọjọgbọn Akintoye ati Bola Tinubu, Akintoye sọ pe bo tilẹ pe oun ati Tinubu kii sọrọ, amọ o da oun mọ.
O ni “Mi o ni iṣoro kankan pẹlu Tinubu, aburo lo jẹ si mi, ẹgbọn ni mo si jẹ si pẹlu, amọ ohun to jẹmilogun ni bi Yoruba ṣe maa kuro lara Naijiria, ti igbeaye irọrun yoo si de ba awọn eeyan wa.”
“Lootọ, ka ni pe nnkan n lọ bo ṣe yẹ ni, ti wọn si ni ki n lọ mu ọmọ Yoruba to dantọ lati ṣe Aarẹ wa, mo maa mu Tinubu, amọ lọwọ yii nnkan ko ṣenu ire.”
“Wọn n pa awọn eeyan wa nilu Owo nipinlẹ Ondo, wọn n pa wọn ni Ekiti, Igangan, Ibarapa ati bẹẹ bẹẹ lọ, ẹ wa sọ pe ọrọ Aarẹ lo kan, rara o!”
Akintoye sọ pe oun ko ni ṣegbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kankan lọdun 2023 ju ki Yoruba Nation da wa nikan.
Ijọba Buhari gbe owo tabua fun Sunday Igboiwo lati sẹ Yoruba Nation amọ o kọ jalẹ
Ni ti ọrọ oloye Sunday Adeyemo Igboho, baba Akitoye ni ijọba orilẹ-ede Benin ti fi Igboho silẹ ko maa ba tirẹ lọ awọn ololufẹ rẹ si gba tirẹ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, olori ileeṣẹ ọmọ Naijiria ana, Lt. Gen. Tukur Buratai, gbe owo nlan kan fun Igboho ko le pada lẹyin ijijagbara fun ominira ilẹ Yoruba amọ o kọ lati gba owo naa, bẹẹ si ni ko tọwọ bọwe ọhun.
Akintoye ni “Wọn wa gbe owo nla fun ọmọkunrin naa amọ o kọ jalẹ, melo ninu awọn ọdọ aye ode oni lo le kọ irufẹ owo beẹ?”
“Tukur Buratai wa ba ninu ẹwọn, o si ṣeleri ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu naira fun ti o ba le tọwọ bọwe kan ti Buratai gbe wa pe oun yoo dẹyin lẹyin Yoruba Nation amọ Igboho ni ko jọ.”
O yamilẹnu pe Osinbajo fẹ di Aarẹ, amọ mo mọ pe ko le wọle

Ni ti igbiyanju igbakeji Aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo lati dije du ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Ọjọgbọn Akintoye ni iyalẹnu lo jẹ fun oun.
Gẹgẹ nii ohun to sọ, oun ko dunnu pe Osinbajo padanu ipo naa amọ ko jẹ iyalẹnu pe ko wọle.
O ni “Nigba ti wọn n sọ pe awọn ara iha Ariwa wa lẹyin Osinbajo mo kan n rẹrin ni, nitori mo mọ pe Osinbajo ko ni gbongbo bii Tinubu.
“Ọkan lara awọn ọlọpọlọ pipe ti a ni ni Naijireia ni Osinbajo ṣugbọn ko ni gbongbo.”
Yoruba Nation nikan ni a fẹ
Baba Akintoye pari ọrọ rẹ si igba ti yoo pada wa si Naijiria lẹyin to lọ si Benin Republic.
O ni “Mo maa pada wa si Naijiria o, amọ kii ṣe lẹyin ti Buhari ba kuro lori alefa.”
“Bi mo ṣe wa yi, mi o ni kaadi idibo, nitori mi o fẹ dibi ni Naijiria.”
“Mo maa pada wa si Naijiria ti a ba ti gba ominira ilẹ Yoruba.”
“Mo le sọ akoko ti yoo ṣẹlẹ amọ mi o tii ni mẹnu lọ sibẹ bayii.”












