Kó gbogbo ọ̀rọ̀ to sọ nípa Atiku jẹ bíbẹ́ẹ̀kọ́... PDP fún Obasanjo lésì

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ti sọ fún Ààrẹ àná ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo láti sọ húlẹ̀húlẹ̀ ohun tó túmọ́ sí nípa pé òun ṣe àbámọ̀ wí pé òun yan Atiku gẹ́gẹ́ bí igbákejì ní ọdún 1999.
Obasanjo nígbà tó ń bá àwọn ọ̀dọ́ kan sọ̀rọ̀ ní ìlú Abeokuta, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ogun lọ́jọ́ Àbámẹ́ta sọ wí pé yíyan Atiku bí igbákejì òun wà lára àwọn àṣìṣe tí òun ṣe ní ìgbésí ayé òun.
Atiku Abubakar tó jẹ́ olùdíje sípò Ààrẹ lọ́dún 2023 lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ló ṣe igbákejì Obasanjo ní 1999 sí 2007.
Ẹ̀wẹ̀, nígbà tó ń fèsì sí ọ̀rọ̀ tí Obasanjo sọ, alága ìgbìmọ̀ tẹ̀ẹ́kótó ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Walid Jibrin ní kí Obasanjo sọ ohun tó túmọ́ sí wí pé òun ṣe àbámọ̀ wí pé òun yan Atiku bí igbákejì.
Jibrin ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Obasanjo kò dárúkọ Atiku nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ àmọ́ ó hàn wí pé gbangba wí pé Atiku ló ń báwí.
Ó ní ó pọn dandan kí Obasanjo wá ṣe àfọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní kíákíá láàárín wákàtí méjìdínláàdọ́ta nítorí ìgbà náà ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP yóò fun ní èsì ọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa.
Ó ní àwọn ń retí kí Obasanjo jáde láti sọ wí pé àwọn akọ̀ròyìn ni kò gbọ́ òun yé tàbí bóyá òun mọ ohun tí òun ń sọ nígbà náà ni wọn yóò gbọ́ wirínwirìn ọọ̀rọ̀ lẹ́nu òun.
Ó fi kun wí pé nígbà náà ni òun yóò tú ìdí Obasanjo tí òun yóò sọ irú ènìyàn tí Obasanjo jẹ́ àti bí Atiku ṣe ran Obasanjo lọ́wọ́ láti ṣe ìjọba.
Bákan náà ló ni Atiku ló kọ̀ jálẹ̀ fún Obasanjo láti gbégbá ìbò fún sáà kẹta.
Àṣìṣe ńlá ní mo ṣe láti kọ̀ fún Amẹ́ríkà pé kó fi mí pamọ́, kí Abacha tó gbé mi sáhàámọ́ – Obasanjo
Amẹrika kìlọ̀ fún mi pé kí ń wá forí pamọ́ torí Abacha fẹ́ mú mi àmọ́ mo yarí - Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Olusegun Obasanjo Library
Aarẹ Naijiria nigba kan ri, Oloye Olusegun Obasanjọ ti n fi ika hanu lori awọn aisse to se latẹyinwa.
Lara awn asise ti Obasanjo mẹnuba pe oun se tẹlẹ ni yiyan ẹni to jẹ igbakeji oun lasiko ti oun wa nipo aarẹ Naijiria.
Obasanjo sisọ loju ọrọ yii lasiko to n dahun ibeere latọdọ awọn akẹkọ ileẹkọ girama to kopa nibi asekagba eto afihan ati igbamiẹyẹ, to wa labẹ aburada ajọ SAGE, eyiun Advancement of Global Entreneurship.
Nibi eto naa to waye nile iyawe kawe aarẹ ana naa nilu Abeokuta ni Olusegun Obasanjo ti sisọ loju rẹ pe asise nla ni ẹni ti oun yan nigbakeji oun lasiko ti oun jẹ aarẹ orilẹede yii amọ Ọlọrun jẹ ki oun tete bori rẹ.
“Asise keji ti mo tun se laye mi ni bi Abach se mu mi si ahamọ nitori asoju ilẹ Amẹrika ti kọkọ sin mi ni gbẹrẹ ipakọ nipa erongba Abacha lati mu mi pamọ.
Orilẹede Amẹrika si sọ fun mi pe awn ti setan lati gba mi laaye, ki n wa fi ori pamọ si ọdọ awọn amọ mo yari pe rara pe n ko wa.
Asise nla ni igbesẹ naa nitori n ko ba ti ku, ki ẹmi mi si ba isẹlẹ naa lọ ninu ahamọ.
Mo si n kede pe ọpọ isoro ni mo ti se sẹyin amọ Ọlọrun jẹ ki n bori wn patapata.”
Oloye Obasanjo wa gba awọn ọdọ naa nimọran lati tẹwọgba iwa rere, ododo, orukọ rere, ko to seese fun wọn lati gba ipo asaaju lọwọ awọn agbaagba.
















