Ọlọ́pàá bá òkú ènìyàn 46 nínú ọ̀kọ̀ tí wọ́n wà gúnlẹ̀

Texas migrant deaths: Ọlọ́pàá bá òkú arìnrìnàjò 46 nínú ọ̀kọ̀ tí wọ́n wà gúnlẹ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O kere tan eniyan mẹrindinlaadọta ti wọn ri ninu ọkọ nla ni wọn ti gbẹmi mi ni agbegbe San Antonio, Texas, lorilẹede Amẹrika.

Oṣiṣẹ panapana lorilẹede naa ni eniyan mẹrindinlogun ti ọmọde mẹrin wa ninu wọn ni wọn ti gbe lọ si ileewosan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti wọn gbe lọ si ileewosan naa ni ara wọn gbona gidigidi.

Wọn ni oṣeeṣe ko jẹ ooru ati aisi omi lo pa awọn eniyan naa nitori ọkọ to gbe wọn ko ni ẹrọ amuletutu AC, tini awakọ ọkọ naa ti salọ

Agbegbe tiu iṣẹlẹ naa ti waye sumọ ẹnu ibode Mexica si Amẹrika ti ọpọlọpọ arinrinajo ti ko ni iwe igbelu si ma n yọ wọle lati ibẹ.

Iwadii fihan pe awọn to ma n fi eniyan ṣe owo ẹru ma n lo ọkọ nla akẹru yii lati fi gbe awọn arinrinajo yii wọle nitori wọn ko ni iwe, kete ti wọn ba ti wọle si ilẹ Amẹrika.

Ileeṣẹ ọlọpaa fikun un pe wọn ti mu eniyan mẹta lori iṣẹlẹ naa ti iwadii si n lọ lọwọ.

Ni ọdun 2017, arinrinajo mẹwaa ni wọn ba oku wọn ninu tirela ni agbegbe Walmart.

Òkú èèyan ogún sùn nílé ijó South Africa, àwọn míì farapa

Aworan awọn ọlọpaa nibi tawọn eeyan ti ku

Oríṣun àwòrán, Reuters

O kere tan, wọn ti ba oku eeyan ogun ninu ile ijo kan ni South Africa.

Inu ile ijo Enyobeni Tavern ni wọn ti ṣawari oku awọn eeyan naa ni afẹmọju ọjọ Aiku, nibi ti ọpọ awọn mii ti farapa.

Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa, Brigadier Tembinkosi sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.

O ni “A ti bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣẹlẹ nibi, a ko tii le sọ ohunkohun lọwọ yii, amọ iwadii ti bẹrẹ.”

Oniruru awọn adoola ẹmi lo ti peju siwaju ile ijo naa bayii to wa lagbegbe Eastern Cape.

Ọlọpaa ni awọn mọlẹbi awọn ti ọrọ naa kan ko tii ri awọn ẹbi wọn, wọn yoo si gbe ile ijo naa ti pa lasiko yii.

Kọmiṣọna ọlọpaa agbegbe Eastern Cape, Nomthetheleli Lilian sọ fun ileesẹ iroyin SABC pe o to awọn leti pe ṣe ni awọn eeyan tẹ ara wọn ninu ile ijo naa.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le sọ boya lootọ ni wọn tẹ ara wọn pa nile ijo naa, SABC ni wọn ti ko eeyan mẹrin lọ sile iwosan.

Brigadier Kinana ni iye ọjọ ori pupọ ninu awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ ko ju ọdun mejidinlogun si ogun ọdun lọ.

Night club South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oṣojumi koro kan sọ fun ileeṣẹ iroyin Daily Dispatch pe ṣe ni awọn oku naa sun lera wọn.

Agbẹnusọ kan fun ileeṣẹ eto ilera ni Eastern Cape ni wọn ti ko awọn to jade laye lọ si awọn ile igbokupamọ si to wa nitosi.

O ni awọn yoo bẹrẹ si n se ayẹwo awọn oku naa laipẹ lati mọ ohun to ṣokunfa iku wọn.