Àwọn agbébọn tún gbẹ̀mí àlùfáà ìjọ Àgùdà míì ní Edo

Oríṣun àwòrán, Catholic church
Àlùfáà ìjọ Àgùdà kan, ẹni ọ̀wọ̀ Christopher Odia ni àwọn agbébọn tún jígbé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú tí wọ́n sì ṣekúpa á.
Ní nǹkan bí ago mẹ́fà àbọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ni àwọn agbébọn náà gbé Àlùfáà náà gbé nígbà tó ń kúrò ní ilé rẹ̀ lọ sí ilé ìjọsìn St Micheal, Ikabigbo, Uzaire, ìpínlẹ̀ Edo.
Lẹ́yìn tí àwọn agbébọn náà jí àlùfáà ọ̀hún gbé, àwọn ọ̀dọ́ agbègbè náà, àwọn fijilanté àti àwọn ẹ̀ṣọ́ àláàbò ya wọ gbogbo àwọn igbó tó wà ní agbègbè náà láti wá àlùfáà náà rí.
Níbi tí wọ́n ti ń wá àlùfáà náà ni àwọn agbébọn yìbọn mọ́ ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nurudeen Umosor tó sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ tí àwọn méjì mìíràn sì farapa.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ìjọ náà, Peter Egielewa fi léde ní ìṣẹ̀lẹ̀ tó bani lọ́kàn jẹ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náààti olóàgbé náà ló ń ṣàkóso ilé ìjọsìn St Micheal kí àwọn agbébọn tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò.
Bákan náà ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé àwọn àwọn méjì nínú àwọn agbébọn náà ni ọwọ́ àwọn fijilanté náà bà.
Iléẹjọ́ ti ju àwọn ọ̣kùnrin kan àtàwọn ọ̀rẹ́ tó na olólùfẹ́ rẹ̀ ní pàṣán ní ìpínlẹ̀ Kwara sí àtìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, IKORO FM
Ile ẹjọ ti paṣẹ ki wọn fi awọn ọdọkunrin mẹrin to din dundu iya fun ọdọbinrin kan ninu fidio kan eyi to lọ kaakiri lori ayelujara laipẹ yii si ahamọ titi di igba ti igbẹjọ wọn yoo fi bẹrẹ.
Awọn ọdọkunrin naa han ninu fidio naa nibi ti ọkan ninu wọn, Jimoh Abdulfatai, to jẹ ọrẹkunrin ọdọbinrin naa ti n naa ti awọn mẹrin yooku, Olamide Babatunde, Afeez Ayomide, Agboola Abdulsamad ati Yakubu Mustapha, to jẹ ọrẹ rẹ si dii lọwọ mu.
Atẹjade kan lati ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, eyi ti alukoro rẹ, SP Ọkasanmi Ajayi fi sita ṣalaye wi pe kete tawọn ọlọpaa nilu Shao kẹfin iroyin naa ati fidio yii ni wọn ti kan lu agbami iṣẹnibi ti wọn ti gbe arabinrin naa lọ sileewosan fun itọju ti wọn si fi panpẹ ofin gbe gbogbo awọn ọdọkunrin ọhun.
Atẹjade naa tun fi kun un pe kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Tuesday Assayomo lo paṣẹ pe ki awọn ọtẹlẹmuyẹ tete pari iṣẹ lori rẹ ki wọn si gbe wọn lọ si ile ẹjọ.

O ṣalaye siwaju sii peawọn afurasi naa jẹwọ pe lootọ lawọn lu arabinrin naa. Wọn ni awọn furasii pe o n ṣoju meji pẹlu ọkan lara wọn to jẹ ọrẹkunrin rẹ, bi o tilẹ jẹ wi pe arabinrin naa sẹ kanlẹ pe oun ko loju meji pẹlu Jimọh Abdulfatai.
Ọrẹkunrin rẹ naa fi tipatipa gba ẹrọ ibanisọrọ alagbeka rẹ ti o si fun ọkan lara awọn ọrẹ rẹ lati maa ka bi wọn ṣe n fi iya jẹ ẹ silẹ lati ju u si ori ayelujara.
Bí ọ̣kùnrin kan àtàwọn ọ̀rẹ́ ṣe na olólùfẹ́ rẹ̀ ní pàṣán rèé tó dèrò àgọ́ ọlọ́pàá ní Kwara
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Fatai, atawọn ọrẹ rẹ mẹta mii lẹyin ti wọn na ọrẹbinrin rẹ, Aduke, lori ẹsun pe o n ba ọkunrin mii dọrẹ.
Iroyin ni awọn afurasi naa pe Aduke, to jẹ akẹkọọ ile ẹkọ Bartholomew College of Health ni ipinlẹ Kwara wa sile Fatai lati fi lilu da lọla lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Nigba to de ile Fatai, o ba oun atawọn ọrẹ rẹ mẹta mii nibẹ, ti wọn si bẹrẹ si n fi ọrọ wa lẹnu wo.
Wọn fi lilu da Aduke lọla
Gẹgẹ bii fidio lilu naa to n milẹ titi lori ayelujara ṣe fi han, awọn ọrẹ Fatai di Aduke lọwọ ati ẹsẹ mu, ti wọn si bẹrẹ n na ni paṣan, iyẹn lẹyin ti wọn ti kọkọ fẹsun kan pe oju rẹ ko gbebikan.
A gbọ pe lẹyin ti wọn na tan ni oun funra rẹ ṣalaye ohun ti oju rẹ lọwọ awọn ọrẹ ololufẹ rẹ loju opo WhatsApp rẹ, to sit un fi fidio lilu naa sibẹ.
Ninu fidio naa Fatai atawọn ọrẹ rẹ ti ka aṣọ Aduke soke, wọn bọ pata rẹ, wọn si n ko paṣan bo idi rẹ ti oun naa si n bẹbẹ fun aanu.
Fidio mii to tun ti wa lori ayelujara ni Aduke funra rẹ, awọn sọja atawọn ọlọpaa kan wa lẹyin ti wọn mu Fatai atawọn ọrẹ rẹ tan.
Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ajayi Okesanmi ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, to si sọ pe iwadii ti bẹrẹ.
Okesanmi ni “Wọn fi ọrọ naa to wa leti a si ti fi ṣikun ofin mu awọn afurasi ọhun.”
“Mẹrin ni wọn, a ti ko wọn lọ si Shao, a si ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.”












