Àwọn ‘olè ọ̀lẹ’ ló wà ní ìdí ìkọlù Ọ̀wọ̀ - Ààrẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter
Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe awọn to ṣekọlu si ile ijọsin ni ilu Owo ko ni lọ lai jiya.
Buhari to ṣe apejuwe wọn gẹgẹ bi ole ni alaini oye ni wọn.
O sọ ọrọ yi ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Garba Shehu fi sita lori bi eto aabo to mẹhẹ ṣe gbinlẹ si to ni Naijiria.
‘Gẹgẹ bi ọlẹ ti wọn jẹ, wọn yoo jiya ẹṣẹ wọn, ti wọn yoo si foju wina ofin.
‘’Mo fi n da yin loju pe gbogbo agbara awọn ileeṣẹ agbonfinro ati ti ọtẹlẹmuyẹ ni Naijiria lo n ṣiṣẹ papọ lati mu awọn aṣebi wọn yii.’’
‘’Fun igba yii, ki gbogbo ọmọ Naijiria sowọpọ fun adura to fi mọ Musulumi ati Kristẹni’’
‘’Ẹ jẹ ka gbadura fun awọn ẹbi ti wọn ṣekupa yii ki oju le ti awọn ika eniyan ọhun’
‘’Ẹ jẹ ki wọn mọ pe orilẹede Naijiria fi ọwọ sowọpọ, ti ko si si mimi kan to le mi wa’’
O kere tan eniyan ogoji lo padanu ẹmi wọn lasiko ti awọn agbebọn ṣe ikọlu si ile ijọsin Aguda lasiko isin Ayajọ Ọjọ Pentecost.
Saaju ni ijọba Naijiria ti ni awọn ikọ ọmọogun ISWAP lo wa ni idi ikọlu naa amọ gomina ipinlẹ Ondo ni ko si aridaju to jọ bẹẹ.
Titi di asiko yii, wọn ko i tii mu ẹnikẹni to lọwọ ninu iṣẹlẹ laabi naa.












