Irọ́ ni wọ́n ń pa o! Lórí Yoruba Nation, a kò yí ìpinnu wa padà - Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gbajugbaja ajafẹtọ iran Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti ni ko si yiyi ipinnu pada lori ija fun ominira ile Yoruba latari ọrọ kan ti o jawọnwọn pe oun ti jawọ ninu ija naa.
Igboho ninu fọnran kan ti o ṣe lati orilede Benin ti o gbe si ori ayelujara Twitter lati ki Olugbon ti Ilegbon, Oba Francis Olusola Alao ku ayẹyẹ ọjọọbi, ni oun pẹlu awọn ti o tẹlẹ oun ko ni ipinnu lati jawọ ninu ija ominira fun ile Yoruba.
“Emi Suday Adeyemo ati awọn ti wọn n tẹle mi lori ọrọ Yoruba Nation ko sẹtan lati jawọ ninu ija fun ominira ile Yoruba, ti ẹni kan ba sọ kini kan, iro ni o, lori ominira ile Yoruba la si wa.”
“A fẹ kuro ninu oko ẹru ti a wa nitori nkan ti Ọlọrun ni fun wa lorii ilẹ wa to waa jẹ, o to wa ṣe orileede wa.”
Igboho wa ro awọn lọbalọba ni ile Yoruba lati pe ipada lori ikolu ti o waye bi yoo ṣe wa sopin ni ile Yoruba ati lati ṣe atilẹyin fun oun lori Ija ominira Ilẹ Yoruba.
“A fẹ ki awọn Ọba ile Yoruba ṣe ipada lori bi ikolu ṣe waye ni ile Yoruba ati lati ṣe atilẹyin fun awa lori ọrọ ille Yoruba”.











