Àwọn agbébọn tún ṣèkọlù sí ilé ìjọ́sìn ní Kaduna, pa àwọn ènìyàn, jí ọ̀pọ̀ gbé lọ

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Kaduna ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn agbébọn tún ṣe ìkọlù sí àwọn ilé ìjọ́sìn méjì àtí àwọn ní ọjọ́ Àìkú ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ní ìpínlẹ̀ náà.
Yàtọ̀ sí àwọn tí àwọn agbébọn náà ṣekúpa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí a kò tíì le fi iye wọn múlẹ̀ ní àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ ni wọ́n jí gbé.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kaduna, Mohammed Jalige nígbà tó ń ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fún BBC ní ọ̀kadà ni àwọn agbébọn náà fi ya wọ àwọn ìlú tí wọ́n ti ṣọṣẹ́.
Ní ìlú Ungwan Fada ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láabi wọn kí wọ́n tó bọ́ sí Ungwan Turawa, Ungwan Makama àti Rubu.
Ní ìlú Rubu ni àwọn agbébọn náà ti ṣèkọlù sí àwọn olùjọ́sìn ní ilé ìjọ́sìn ìjọ Onítẹ̀bọmi Maranatha àti ìjọ Àgùdà St Moses.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ènìyàn mẹ́ta ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ tí wọ́n sì tún dárúkọ àwọn mìíràn tó farapa nínú ìkọlù ọ̀hún.
Bákan náà ni wọ́n já àwọn ṣọ́ọ̀bù, tí wọ́n sì jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ìní gbé lọ.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn kò ì tíì le sọ pé àwọn kan ní pàtó ló ṣe ìkọlù náà àmọ́ ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ láti ṣàwárí àwọn tó ṣọṣẹ́ náà.
Ilé ìjọ́sìn Àgùdà náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ àmọ́ adarí ẹ̀ka ìròyìn ìjọ náà ní àwọn yóò tó fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ léde láìpẹ́.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àwọn agbébọn ń ṣe ìkọlù sí ilé ìjọ́sìn
Ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo ṣètò ìsìnkú ọlọ́pọ̀ èrò fún àwọn ènìyàn ogójì ènìyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù tí àwọn agbébọn ṣe sí ilé ìjọ́sìn Àgùdà St Francis, ìlú Owo ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹfà.
Ìkọlù tí àná yìí ni ìgbà karùn-ún tí àwọn àgbébọn yóò ṣe ìkọlù sí ilé ìjọ́sìn ní ìpínlẹ̀ Kaduna láàárín ọdún 2021 sí àsìkò yìí.
Nínú oṣù Kọkànlá, ọdún 2021, àwọn agbébọn jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùjọ́sìn gbé ní ilé ìjọ́sìn Onítẹ̀bọmi Emmanuel tó wà ní Kakau Daji, ìjọba ìbílẹ̀ Chikun gbé lọ lásìkò tí wọ́n ń jọ́sìn lọ́wọ́.
Lára àwọn tó lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi léde ni báálẹ̀ Ungwan Fada, Peter Madaki, Elisha Ezekiel, tó jẹ́ olùgbé Ungwan Fada àti Ali Zamani tó jẹ́ olórí àwọn ọ̀dọ́ ní Rubu.
Obìnrin kan tí a kò mọ orúkọ rẹ̀ àti Aniro Mai ló farapa nínú ìkọlù náà.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna kọminú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
Adelé gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kaduna, Hadiza Sabuwa Balarabe ti kọminú lórí ìkọlù tí àwọn agbébọn ṣe sí àwọn ìlú àti ilé ìjọ́sìn náà.
Bákan náà ló bá ẹ̀bí àwọn ènìyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ kẹ́dùn, tó sì gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ́ àwọn to ti lọ náà sí afẹ́fẹ́ rere.
Kọmíṣọ́nà fétò ààbò lábẹ́nú, Samuel Aruwan ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè ní ìjọba ìbílẹ̀ Kajuru ni ìkọlù náà ti wáyé.
Bákan náà ló ní àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti wà káàkiri gbogbo agbègbè náà láti dènà irúfẹ́ ìkọlù yìí.












