Àwọn afurasí ajínigbé bẹ́ orí kánsélọ̀ tó lọ dóòlà ará ìlú rẹ̀ tí wọ́n jígbé

Awọn janduku to mu ada da ni

Oríṣun àwòrán, Other

Inu ifoya ni awọn olùgbé ilu Owupa ati Orokam, to wa ni ìjọba ibilẹ Ogbadigbo, nipinlẹ Benue, lẹyin ti awọn afurasi ajinigbe pa kanselọ kan ati ibatan rẹ.

Iroyin sọ pe kanselọ naa, Paul Ojile, ati ibatan rẹ ọhun, darapọ mọ awọn ọdẹ ati fijilante ni àwọn ilu mejeeji, lati doola awọn eeyan kan ti wọn jigbe lọjọru.

Àwọn ti iṣẹlẹ naa soju wọn sọ fún àwọn akọroyin pe eeyan meji ni wọn kọ́kọ́ jigbe n'ilu Orokam.

Eyi lo mu ki kanselọ naa ati ibatan rẹ darapọ mọ awọn fijilante, ati awọn òṣìṣẹ́ alaabo mii, lati wa àwọn eniyan naa lọ, nitori pe ọdẹ ni oun naa.

Ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ni wọn dibo yan Ọgbẹni Paul Ojile si ipo kanselọ ni ẹkún idibo Orokam Kẹta, to si n duro de ọjọ ti wọn o bura wọlé fun wọn, ki wọn o to o pa oun ati ibatan rẹ. Alaga ìjọba ibilẹ Ogbadigbo, Samuel Onu, sọ fun iwe iroyin Punch pe ṣàadédé ni awọn yooku ri i pe kanselọ naa ati ibatan rẹ ti di awati laarin wọn.

Lẹyin ti wọn doola ẹnikan lara awọn ti ajinigbe gbe lọ, ti wọn si tun mu meji lara awọn ajinigbe naa.

Alaga naa sọ pe ọpọ igba ni àwọn ajinigbe ti gbe eeyan ni ilu Owupa ati Orokam, lẹ́nu ọjọ́ mẹta yii.

"Eeyan to wọn jigbe n'ilu Orokam, nibi ti kanselọ naa n gbe lo mu ko tẹle awọn oṣiṣẹ alaabo wọ inu aginjù, lati doola àwọn ti wọn jigbe.

"Igba ti wọn n pada bọ lọjọbọ, ni àwọn ti wọn jọ lọ ṣakiyesi pe awọn mejeeji ti di awati. Amọ nigba ti wọn o fi padà wọ inu igbo lati wa wọn ní ọjọ Ẹti, oku wọn ní wọn ri, ti wọn ti bẹ ori wọn."

O ni wọn ti ko àwọn afurasi mejeeji ti ọwọ tẹ lọ si ilu Makurdi.

Iṣẹlẹ naa mu ki awọn ọdọ ilu mejeeji ṣe iwọde, ti wọn si di oju ọna marosẹ ni agbegbe naa. Titi di asiko yii, ileeṣẹ ọlọpaa ko tii sọ ohunkohun nipa isẹlẹ naa.