“Ìkùnà ìjọba àpapọ̀ àti ẹ̀ṣọ́ aláàbò ló fá ìkọlù agbébọn ní Owo”

Owo

Ẹgbẹ apapọ isọkan ilu Owo ati ibasepọ ijọba ibilẹ Ose ni ipinlẹ Ondo, ti kesi ijọba apapọ lati tẹra mọ ipese aabo to peye fawọn ara ìlú.

Ẹgbẹ naa ni eyi se pataki, ni pápá julọ, ipese aabo ní ipinlẹ Òndó lẹyin iṣẹlẹ isekupani tí o wáyé laipẹ ni ìlú Ọwọ.

Asoju ẹgbẹ ọhun, Oloye Akinboro Ariwajoye wa tọka sì ikuna ìjọba apapọ ati awọn ikọ ẹṣọ alaabo láti tètè kẹfin awọn agbebọn náà ṣáájú iṣẹlẹ ọhun.

Akinboro, ninu ọrọ rẹ ṣe àkàwé bi wọn se gbẹmi ọba Adeusi, tii se Olufon ti ilé ifon ní òpópónà Owo si Ifon lọdun méjì sẹ́yìn àti awọn ọpọlọpọ iwa ijinigbe mii ní agbègbè náà.

Ẹgbẹ apapọ isọkan ilu Owo ati ibasepọ ijọba ibilẹ Ose ni ipinlẹ Ondo wa rọ ìjọba láti fí agbára kún ikọ Amotekun lati kọjú awọn iṣẹlẹ bíi eleyii ní yajoyajo.

Lara awọn eeyan pataki ti o wa ní ibì ìpàdé oniroyin ọhun ni Amofin agba Adesuyi Olateru ati Olajumoke Anifowose, to ti fi igbakan jẹ Amofin agba ni ipinlẹ Òndó.

Anifowose ninu ọrọ rẹ, rọ ìjọba àpapọ̀ lati pese ohùn ìjà ìgbàlódé fún awon ikọ ọlọpaa láti kojú awọn agbesunmọmi.

Owo
Pẹ̀lú Àdá àti ọ̀bẹ ni àwọn ọmọ ìta kàn fi ya wọlé ilé ìwòsàn Fasiti ìpínlè Osun

Osun University hospital clash: Wàhálà ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ ìta wá fágidí gba òkú nílé ìwòsàn Osogbo

Àwòrán àwọn awọn ọmọ ita pẹlu ada

Oríṣun àwòrán, screenshot

Awọn ọmọ ita sẹ ikọlu si ile iwọsan Fasiti Osun State Teaching Hospital niluu Osogbo latari bi ile wọsan naa se ko lati gbe oku okan lara wọn to jade laye lẹyin ti ibon ba sile.

 Eeyan meji ni iroyin ni o jade laye latari bi awọn ita se fa rogbodiyan laarin ara wọn lojo isẹgun ose yii

 Okan lara wọn ti ibon ba nibi iṣẹlẹ rogbodiyan naa ni wọn gbe lọ si ile wọsan fasiti Osun State University, ti o si jade laye ni be.

Wàhálà ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ ìta wá fágidí gba òkú nílé ìwòsàn Osogbo

Lẹyin iku arakurin naa ni awọn ọmọ ita yabo ile wọsan pẹlu okada lati gbe oku arakurin naa.

Sugbọn awọn eleto ilera ile wọsan naa si koo lati gbe oku naa sile nitori awọn ayewo ati akolẹ ti wọn si gbinyaju lati se fun oloogbe naa .

Eyi ni ko ba awọn ọmọ ita naa lara mu ti wọn si fẹ tipa tikuku ya wo ile wọsan naa pẹlu awọn ohun ija lorisirisi.

Oseojumikoro kan to ba awọn akoroyin sọrọ ni pẹ

“Pẹlu ohun ija ni wọn fẹ fi ja ilekun abawole ile wọsan.

“Ada, aake, ọbẹẹ ati ọpọlọpọ ogun ni o wa lọwọ awọn ọmo ita naa.

“wọn leri pẹ ti wọn ba

“Kete ti a ri wọn ni ọpọlọpọ wa ati nurse, dokita ati awọn osise ile wọsan ba isẹ wa sọrọ ki awọn olopaa to de”

Alaga fun awọn onigbanimoran ni ile wọsan, Babatunde Afolabi fi idi iṣẹlẹ naa mule sugbọn o ni alafia ti pada si ile wọsan, ti wọn si yan ọrọ naa pẹlu awọn ọmọ ita naa lati gbe oku naa lọ fun ẹto isinku.