Kò sí ǹkan tó ń jẹ́ ‘Cabal’ ní ìṣèjọba Ààrẹ Buhari, Òun ló ń ṣe ìjọba– Garba Shehu
Election 2023: Garba Shehu ni ‘APC Primaries’ fihan pe Buhari fẹ́ràn ìjọba tiwantiwa

Oríṣun àwòrán, Twitter
Agbẹnusọ fun Aarẹ Buhari, Garba Shehu ti ni ipa ti Aarẹ Buhari n ko ninu idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP to kọja ṣafihan iru eniyan ti Aarẹ Buhari jẹ ninu iṣejọba tiwantiwa ni Naijiria.
Garba sọ eyi ninu atẹjade to fi si oju opo ikansiraẹni Twitter rẹ.
O ni Aarẹ Buhari gbe igbesẹ to yatọ si nkan ti iroyin n sọ nipa rẹ, pe Aarẹ Buhari fẹ gbe oludije kan lori awọn eniyan ni Naijiria.
‘’Ko si ohun to n jẹ ‘Cabal’ ni ijọba Aarẹ Buhari, oun fun ara rẹ lo n paṣẹ nkan ti o ba fẹ.’’
‘’Ọpọlọpọ nkan ni awọn eniyan ma n sọ si adari , wi pe o jọba lori ohun gbogbo to si le sọ abajade eto idibo.’’
‘’Amọ fun orilẹede Naijiria to ni Aarẹ Buhari, iṣejọba awarawa lo gbeleke, ti ko si fi imọ tara ẹni nikan ṣe.’’
Garba fikun un pe Aarẹ Buhari ri daju pe otitọ ati ododo jọba lasiko idibo abẹle naa, ti eyi si fa moriya fun awọn eniyan lati ni igbagbọ ninu iṣejọba tiwantiwa.
Bakan naa lo nipe awọn eniyan ti wa ni igbagbọ ninu aarẹ Buhari lati tọ ipa otitọ ati ododo.
‘’Nibayii, a ti yan ẹni ti yoo ṣoju APC to si ni atilẹyin Aarẹ Buhari. Nitori na o daju pe yoo bori.’’
Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lo gbegba oroke ninu idibo abẹlẹ APC gẹgẹ bi ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ oselu naa lati dije du ipo aarẹ ni ibo ọdun 2023.












