Ariwo kò yẹ kóo máa gbé Kùránì dání pẹ̀lú iṣẹ́ aṣẹ́wó tí ò ń se ní wọ́n pa kí wọ́n tó dáná sun òkú náà

Ọkùnrin mẹ́ta gún aṣẹ́wó pa, dáná sun okù rẹ̀ torí wọ́n ba Quran nínú yàrá rẹ̀

Awon ti won n ni ibalopo

Oríṣun àwòrán, Others

Ọkùnrin mẹ́ta gún aṣẹ́wó pa, wọ́n tún dáná sun okù rẹ̀ nítorí wọ́n ba Quran nínú yàrá rẹ̀

Lagos Police

Oríṣun àwòrán, @PoliticalEcono1

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti gbe awọn ọkunrin mẹta kan lọ ile ẹjọ losi ẹsun pe wọn lu obinrin aṣẹwo kan pa, ti wọn tun dana sun oku rẹ.

Awọn afurasi naa gbe igbesẹ ọhun lẹyin ti wọn ba Quran ninu yara rẹ.

Abubakar Musa, Surajo Yusuf àti Sarauta Monsur ni wọn dana sun oku Hanatu Saliu ni agbegbe Alaba Rago ni ipinle Eko

Iroyin ni ọkan lara awọn afurasi naa ti kọkọ ba ologbe naa, Hannah Saliu lopọ, to si fun ni ẹgbẹrun kan naira gẹgẹ bi owo iṣẹ rẹ.

Amọ oloogbe naa ṣakiyesi pe ẹgbẹrun marun un naira ti poora ninu ile oun lẹyin ti wọn ni ajọṣepọ tan.

Eyii lo mu ki oloogbe naa sare tọ onibara rẹ ọhun lọ, to si fẹsun kan pe oun lo ji owo naa, sugbọn ọrọ naa di ariwo nla.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, onibara naa ko awọn ọrẹ rẹ lọ sinu yara oloogbe ọhun lati wa owo to ni o oun ji.

Ibi ti wọn ti n wa owo yii ni wọn ti ṣawari iwe mimọ awọn Musulumi, Al-Qur’an, labẹ irọri rẹ.

Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ fun awọn akọroyin pe wọn bi oloogbe naa lawọn ibere nipa bi Quran ṣe de inu yara rẹ pẹlu pe iṣẹ aṣẹwo lo n ṣe, ti awọn afurasi naa si faraya lori ohun ti wọn foju ganni.

Ẹni naa ni “Ohun to ṣẹlẹ ni pe, aṣẹwo ni obinrin naa, okunrin ọhun ji ẹgbẹrun marun un rẹ, o si le lere lati bere owo naa lọwọ rẹ.”

“Onibrara naa wa sọ fun oloogbe naa pe ki wọn lọ wa yara rẹ lati mọ boya owo to n wa ṣi wa ninu ninu yara rẹ.”

“Ibi ti wọn ti n wa inu yara ọhun ni wọn ti ri Quran labẹ irọri rẹ ti wọn si n bere lọwọ rẹ ohun ti Quran n ṣe ninu ile rẹ gẹgẹ bii aṣẹwo.”

“Lẹyin naa ni awọn ọkunrin ọhun to jẹ ọmọ Oke ọya gun lọbẹ, ti wọn si tun dana sun oku rẹ.”

“Iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Aba Rego ti ọpọ awọn Hausa n gbe, Hausa si ni oloogbe naa pẹlu.”

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin lo fidi iroyin naa mulẹ.