Méjì nínú àwọn tí Abba Kyari ń bá jẹ́jọ́ oògùn olóró rí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì he
Méjì nínú àwọn tí Abba Kyari ń bá jẹ́jọ́ rí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì he

Oríṣun àwòrán, @Abba Kyari facebook
Ile ẹjọ giga to n gbọ ẹsun ti wọn fi kan ọga ọlọpaa, Abba Kyari, ti ran awọn eeyan meji ti NDLEA ni wọn n ba Kyari ṣiṣẹ papọ lẹwọn ọdun mẹfa.
Orukọ awọn eeyan naa ti wọn fẹsun gbigbe oogun oloro kan ni Chibunna Patrick Umeibe ati Emeka Alphonsus Ezenwane.
Adajọ Emeka Nwite dajọ pe ki awọn eeyan naa lọ fi aṣọ penpe roko ọba lori ẹsun mẹta lara awọn ẹsun ti NDLEA fi kan wọn.
Ti ẹ ko ba gbabe, papakọ ofurufu Akanu Ibiam to wa niluu Enugu ni wọn ti mu awọn ọdaran naa lasiko ti wọn n gbiyan lati gbe oogun oloro cocaine wọ Naijiria.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ keje, oṣu Kẹta ni wọn gbe Kyari, awọn meji ti ile ẹjọ ran lẹwọn yii atawọn ọlọpaa mẹrin mii ,ACP Sunday J. Ubia, Insp. Simon Agirigba, Insp. John Nuhu, ati ASP Bawa James lọ sile ẹjọ lori ẹsun pipadi apo pọ pẹlu awọn to n gbe oogun oloro.
A gba pe a jẹbi ẹsun ti NDLEA fi kan wa
Awọn afurasi meji naa, Umeibe ati Ezenwanne sọ pe awọn gba pe lootọ ni awọn jẹbi ẹsun ti NDLEA fi kan awọn.
Bo tilẹ jẹ pe adajọ Nwite kọkọ fẹ sun ẹjo ọhun siwaju lati ṣe ayẹwo awọn ẹri to wa niwaju rẹ lẹẹkan si.
Amọ agbẹjọro NDLEA, Sunday Jospeh sọ fun ile ẹjọ naa pe oun ti ba awọn afurasi meji naa sọrọ, wọn si ti fọwọ si idunadura kan pe awọn gba pe awọn jẹbi ti wọn fi kan awọn.
NDLEA tun ni awọn ọdaran naa ti gba lati ṣe ẹlẹri fun NDLEA ninu igbẹjọ naa to n lọ lọwọ paapaa lati jẹri tako Abba Kyari.
Lẹyin naa ni adajọ ọhun ṣedajọ ọdun meji-meji fun awọn eeyan naa lori ẹsun mẹta ti wọn fi kan wọn.
Ẹwẹ, ile ẹjọ naa tun sọ pe awọn afurasi naa kabamọ iwa ti wọn wu, nitori naa adajọ ni iye ọdun ẹwọn wọn yoo bẹrẹ lati ọjọ ti wọn ti fi panpẹ ofin mu wọn.












