Àwọn Òṣìṣẹ́ 'National Assembly' fòpin sí ìyanṣẹ́lódì

Awọn Òṣìṣẹ́ Ilé Igbìmọ̀ aṣòfin àgbá ní Abuja wọ́gilé ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n gún le

Ẹgbẹ́ awọn Osisẹ ile Igbimo Aṣofin ni Abuja ti a mọ si Parliamentry Styaff Association of Nigeria (PASAN) ti fopin si iyanṣẹlodi ti wọn gun le.

Lati ọjọ Aje ni wọn ti gun le iyanselodi naa ni eyi ti wọn fi n beere fun awọn ajẹmọnu wọn gbogbo ti ijọba n jẹ wọn.

Ita National Assembly

Oríṣun àwòrán, Others

Alaga ẹgbẹ osise PASAN naa, Sunday Sabiyi salaye lasiko to n ba awon akoroyin sọrọ ni aipẹ yii pe o nidi ti wọn se fopin si iyanselodi naa.

O ni pe awọn fẹnuko lati fopin sii nitori pè awọn ti jọ tọwọ bọ awọn adehun kan pẹlu awọn adari ile igbimọ Asofin.

Awọn osise PASAN naa sọ fun awọn akọroyin pe wọn yoo gunle iyanselodi mii ni kete ti ijóba ba ti kuna lati mu adehun wọn ṣẹ gẹgẹ bi wọn se fẹnuko si.

Gbendeke ti ẹgbẹ naa fun ijọba titi di osu keje ọdun yii lati mu adehun wọn ṣẹ.