Muslim-Muslim Ticket: Yíyan Ààrẹ àti Igbákejì láti ẹ̀sìn kán náà lòdì sí ẹ̀sìn Islam- Sheikh Halliru Abdullahi Maraya

Lati igba ti awuyewuye ti n jade lori awọn ti yoo ṣe igbakeji awọn oludije sipo aarẹ ni ọrọ ẹsin ati ẹya ti n jade sii ni Naijiria.
Ọmọwe kan ninu esin Islam lorilede Naijira ti ni iyanyan Aarẹ ati Igbakeji lati ninu ẹṣin kan naa paapaa julọ ni orile-ede ẹlẹsin meji si mẹta tabi ju bẹẹ lọ lodi si ẹsin Islam
Ninu iforowero pẹlu BBC Hausa, ẹni ti o ti fi igba kan jẹ amugbalegbe gomina Kaduna, Sheikh Halliru Abdullahi Maraya ni ofin ẹṣin Islam fẹ ki irepo wa laarin wa ti o si lodi di iyanije pupo.
O tẹsiwaju pe ẹsin Islam ko fa aye gba ki ẹsin kan ma kuto isakoso ijọba orilede
Sheikh ni pe: “Orile-ede Naijiria wa fun awọn Musulumi ati Kristẹni, fun di eleyi, agbodo pe fun ibasepo laarin ẹsin meejeji fun itẹsiwaju orilede Naijira.”
“Ẹsin Islam lodi si pẹ ki Aarẹ ati Igbakeji wa lati ninu ẹsin kan naa nitori pe Islam ko fa aaye gbe ireje laarin awọn musulumi ati awón ti ko sẹ musulumi.”
Eyi ko ṣẹyin bi Bola Tinubu to jẹ Musulumi ṣe di oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC ti Atiku Abubakar to jẹ Musulumi naa jawe olubori gẹgẹ bi oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC.
Eleyii ti mu ki awọn eniyan maa sọrọ nipa ẹni ti wọn yoo mu fun ipo igbakeji wọn.

Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir-El Rufai ni ko si nkankan to buru ninu ki ẹlẹsin Musulumi meji di ipo aarẹ ati igbakeji aarẹ mu ni Naijiria.
Lasiko ti gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai n sọrọ lori Channels Television ni oun ko mọ nipa Muslim-Muslim ticket
O ni ọrọ ẹsin ko ni iṣoro ti Naijiria n dojuko bikoṣe ki awọn ti wọn ba yan ṣiṣẹ takun takun lati mu idagbasoke ba Naijiria.















