Àwọn ọ̀dọ́ yabo olú ilé ẹgbẹ́ APC ni Abuja, wón lèrí sí Alaga Adamu
Awọn ọdọ lati ipinlẹ Kogi ni wọn yawo olu ile ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn si pariwo ọtẹ le Alaga Abdullahi Adamu lori.
Iroyin to n jade lo sọ pe awọn ọdọ fariga fun Mallam Adamu Abdullahi to jẹ alaga ẹgbẹ APC. Kete ti awọn ọdọ naa rii pe awọn alaga ẹgbẹ naa beere ipade ni wọn ya woo olu ile naa niluu Abuja. Wọn n binu pe ẹgbẹ APC ko fun ọdọ to jawe olubori ni ipinlẹ Kogi ni tikẹẹti bi o ṣe yẹ lẹyin idibo.
Wọn ni awọn agba ẹgbẹ n fi ọwọ ọla gba awọn ewe loju ninu ẹgbẹ naa nipinlẹ Kogi

Awọn ọdọ naa ni wọn fi ẹsun kan ẹgbẹ pe okan lara wọn ti o bori ninu eto idibo abenu fun ọmọ ile igbimo asofin kekere ni wọn gba tikẹẹti lowo rẹ fun ẹlomiran. Pẹlu ariwo ati orin ọte ni awọn ọdọ naa fi leri pe Alaga ẹgbẹ oselu naa,
Abdullahi Adamu ko ribi gba jade ninu olu ile iya ẹgbẹ APC naa ti awọn olopaa si gbe ilekun abawole ti lati ma fun awọn ọdọ naa laye lati wọ inu ile iya ẹgbẹ..
Ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa ‘Muslim-Muslim ticket’ ní Naijiria rèé
Awọn eniyan ti bẹrẹ si ni fi ero wọn han lori awọn oludije fun ẹgbẹ oṣelu ati igbakeji wọn ṣaaju idibo sipo aarẹ ni ọdun 2023.
Eyi ko ṣẹyin bi Bola Tinubu to jẹ Musulumi ṣe di oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC ti Atiku Abubakar to jẹ Musulumi naa jawe olubori gẹgẹ bi oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC.
Muslim-Muslim Ticket for APC: Ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa ‘Muslim-Muslim ticket’ ní Naijiria rèé

Oríṣun àwòrán, Google
Eleyii ti mu ki awọn eniyan maa sọrọ nipa ẹni ti wọn yoo mu fun ipo igbakeji wọn.
Awọn miran bi gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir-El Rufai ni ko si nkankan to buru ninu ki ẹlẹsin Musulumi meji di ipo aarẹ ati igbakeji aarẹ mu ni Naijiria.
Lasiko ti gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai n sọrọ lori Channels Television ni oun ko mọ nipa Muslim-Muslim ticket
Amọ ko si ohun to buru nibẹ nitori ẹlẹsin Kristẹni, Pasitọ Tunde Bakare lo mu ohun lọ si ẹgbẹ oṣelu CPC nigba naa, kii ṣe aarẹ Buhari ti oun si ni ọrẹ to jẹ Kristẹni pupọ.
O fikun un pe ọrọ ẹsin ko ni iṣoro ti Naijiria n dojuko bikoṣe ki awọn ti wọn ba yan ṣiṣẹ takun takun lati mu idagbasoke ba Naijiria.
Musulumi ni igbakeji mi ni idibo 2019, a si wọle – Nasir El-Rufai
‘’Ni ipinlẹ Kaduna, igbakeji mi ni ọdun 2019, obinrin ni, Musulumi ni, ti awọn eniyan nigba naa si sọ pe a ko le wọle nitori awa mejeeji jẹ Musulumi,
amọ ko si ohun to jọ bẹẹ nitori awọn eniyan dibo yan wa daradara.’’
‘’Ibanujẹ lo jẹ fun mi bi a ṣe n gbe ọrọ ẹsin bori ipa ti eniyan le ṣe- eyi ko dara rara. Ẹ jẹ ki a fi oju si eniyan to le ṣiṣẹ takun takun, kayọ ti ọrọ ẹsin kuro.’’
Bakan naa ni Femi- Fani Kayode ni ohun yoo dibo fun Tinubu to ba mu Musulumi gẹgẹ bi igbakeji rẹ, amọ o rọ ọ ki o ro igbesẹ naa daradara.
‘’Ọrọ to kan gbogbo ara ilu ti a si gbọdọ ṣalaye fun wọn daradara ni nitori ọpọlọpọ iṣẹlẹ ti waye to tọkasi pe awọn Kristẹni n sọrọ tako ki awọn Musulumi meji dije papọ’’
‘’A ko le sọ pe bawo ni ọrọ ẹsin ṣe ri ni ọrọ oṣelu loni amọ a ko gbọdọ gbagbe awọn aadọta Kristẹni ti wọn pa ninu ṣọọṣi ni Ọwọ ati awọn mẹtalelọgbọn miran ti wọn pa ni ilu Kaduna’’
‘’Nitori naa, Tinubu gbọdọ rọ ọ daradara ki o to ṣe e, ki o fi ti awọn eniyan ṣe ki o to gbe igbeṣẹ lori igbakeji rẹ, amọ ibi ti Tinubu ba lọ ni awọn yoo tẹle.’’
Awọn to faramọ eyi tun ran awọn eniyan leti idibo ọdun 1993 to gbe MKO Abiola ati Alhaji Babagana Kinigbe wọle gẹgẹ bi aarẹ ni ọdun naa.
Amọ, ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi CAN ti kesi awọn oludije wi pe ẹnikẹni to ba mu ẹlẹsin Musulumi gẹgẹ bi igbakeji rẹ ko ni ri idibo kankan lọwọ awọn Kristẹni ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @El Rufai












