South West Security: Wo kókó tí wọ́n fẹnukò lé lórí níbi ìpàdé àwọn Gómìnà Yorùbá

Aworan awọn Gomina

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rotimi Akeredolu

Awọn Gomina lati Guusu Iwọ oorun Naijiria ti fẹnuko lati gbe awọn igbesẹ ti yoo mu ki eto aabo kajuẹ si ni agbegbe wọn.

Ipinnu yi waye lẹyin ipade kan ti wọn ṣe eleyi ti wọn pe ni kopẹ kopẹ ikọlu awọn agbebọn si ile ijọsin St Francis Catholic Church, Owaluwa , Owo.

Atẹjade ti wọn fi sita mẹnu ba awọn ipinnu meloo kan eleyi ti wọn ni yoo mu iyipada ba eto ọrọ aabo lawọn ipinlẹ kaarọ o jiire.

Yatọ si pe wọn bẹnu atẹ lu ikọlu si ile ijọsin yi, wọn ni kawọn ipinlẹ Yoruba ya ọjọ mẹta idaro sọtọ ni iranti awọn to ba iṣẹlẹ aburu yi lọ.

Ìpàdé yìí sọ̀rọ̀ lórí wíwa ọ̀kadà àti ìgbésẹ̀ àwọn Gomina láti fòfin de irú ìsesí de báyìí kí ètò aàbọ ará ìlú lé dára síi.

Iye ọjọ ti wọn ya sọtọ yi yoo ma kun eleyi ti ipinlẹ Ondo ti ṣaaju kede nidaro awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.

O ti to ọjọ mẹta ti awọn Gomina ṣe iru ipade eleyi ti wọn ṣe yi botilẹ jẹ wi pe wọn ti ni igbimọ to n risi ọrọ aabo lawọn ipinlẹ Yoruba.

Ipade yi lara awọn abajade wọn ti wa ni pinnu pe ki wọn tun ipade igbimọ aabo mi ṣe ki wọn si foju sunnumkun wo ọrọ to niṣe pẹlu ipese aabo.

Aworan Gomina Seyi Makinde ati Minisita Rauf Aregbesola lasiko abẹwo si ipinlẹ Ondo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rotimi Akeredolu

Fifofin de ọkada wiwa jẹ nkan tawọn Gomina gbe yẹwo

Ni paapa wọn ni igbimọ naa yo ṣe agbekalẹ iwadii eleyi ti yoo sọ nipa lilo alupupu taa mọ si ọkada lawọn ipinlẹ Yoruba.

Ọrọ alupupu yi jẹ eleyi ti awọn to n ṣe eto aabo maa n mẹnu ba lọpọ igba.

Wọn a si maa sọ pe lilo ọkada n ṣe akoba fun alaafia ati aabo ilu.

Ipinlẹ Eko to jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba fofin de lilo ọkada lawọn aaye kan ni ipinlẹ naa laipẹ yi.

Eyi ko si sẹyin bi awọn to n lo alupupu fi ṣọrọ aje kan ti ṣe n da omi alaafia ilu ru.

Awọn nkan miran to tun jẹyọ nibi ipade

Kayode Fayemi to jẹ alaga ẹgbẹ awọn Gomina Naijiria naa kan si ilu Owo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rotimi Akeredolu

Awọn Gomina lawọn yoo ṣayẹwo ọrọ ikunsinu araalu lori ọrọ awọn to n gbalẹ to fi mọ awọn ajoji ti wọn ko damọ to n wọ ilẹ Yoruba.

Lori eleyi, wọn lawọn yoo tẹra mọ kikesi awọn ileeṣẹ alaabo lori titọ pinpin awọn to n wa lati tẹdo silẹ Yoruba yi.

Bakan naa ni wọn lan yo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ileeṣe alaabo lati pese abbo to peye faraalu ju ti tẹlẹ lọ.

Ẹwẹ wọn ni ipade mii tawọn yoo ba ṣe ko ni jẹ loju opo ayelujara bi kii ṣe pe awọn yoo foju koju ṣe ipade naa ni.

Ninu awọn Gomina to peju ṣe iapde yi ni Gomina Rotimi Akeredolu ipinlẹ Ondo, Dapo Abiodun Ogun, Kayode Fayemi Ekiti, Babajide Sanwo-Olu Eko ati Gboyega Oyetola ipinlẹ Osun.