Ajínigbé rélùweè Kaduna tún t'u èrò míì sílẹ̀ nínú àwọn tó wà ní àhámọ́

Oríṣun àwòrán, NRC
Awọn agbebọn ajinigbe to ji ero ọkọ reluwee gbe nilu Kaduna ti tu diẹ silẹ ninu awọn to wa ni ahamọ wọn lọjọ Abamẹta.
A gbọ pe awọn ajinigbe yi kọ lati mu adehun wọn ti wọn ṣe tẹlẹ lati tu gbogbo obinrin to wa ni igbekun wọn silẹ.
Gẹgẹ bi oludasilẹ ile iṣẹ iwe iroyin Desert Herald,Malam Tukur Mamu to jẹ ẹni to n duna dura laarin ijọba ati awọn ajinigbe yi ṣe sọ, obinrin mẹfa ati ọkunrin marun un ni wọn tu silẹ lẹyin ọpọ idunadura.
Ọkan lara awọn mọlẹbi ti wọn tu eeyan wọn silẹ fidi ọrọ mulẹ fun BBC pe wọn ti tu ẹbi awọn to jẹ ọkunrin silẹ.
Lọjọ Aje ọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun yi lawọn ajinigbe kọlu ọkọ reluwee to n gbe ero bọ lati Abuja si Kaduna.
Eeyan meje lo padanu ẹmi wọn ninu ikọlu yi ti ọpọ si farapa.
Wọn ji pupọ ninu awọn ero naa gbe salọ .
Ohun ti ijọba Naijiria sọ si ni pe ikọ agbesunmọmi ISWAP pẹlu awọn janduku kan ni wọn gbimọran pọ gbe awọn eeyan wọnyi.
Bi ijọba ko ba tu awọn ọmọ wa silẹ awa naa ko ni tu awọn taa jigbe silẹ
Awọn ti o mọ binkan ṣe n lọ lori iṣẹlẹ yi sọ fun ẹni to n duna dura laarin ijọba ati awọn ajinigbe yi pe awọn ajinigbe ti mu adinku ba iye awọn eeyan ti wọn ṣadehun fun ijọba pe awọn yoo tu silẹ.
O ni bayi, wọn ti la awọn ofin nkan ti wọn fẹ silẹ fun ijọba.
Gẹgẹ baa ṣe gbọ lẹnu eeyan kan to ni ki wọn ma darukọ oun, ''wọn ko tu awọn eeyan kan silẹ nitori ailera ara wọn.''
Malam Tukur Mamu to jẹ ẹni to n duna dura laarin awọn ajinigbe ati ijọba sọ pe ''Adehun tẹlẹ ni pe ki wọn tu gbogbo awọn obinrin to wa ni ahamọ silẹ ti wọn yoo si tẹsiwaju pẹlu idunadura lori awọn to ku.Ṣugbọn wọn mu adinku ba iye eeyan ti wọn tu silẹ nitori ijọba lawọn fẹ ki wọn tu awọn to rẹ tabi to farapa pupọ silẹ''
Awọn ajinigbe naa gẹgẹ baa ṣe gbọ tiu wa ni awọn yoo tu awọn eeyan miran ti ijọba beere yi silẹ lopin igba ti wn ba tu awn ọmọ ti wọn naa to wa ni ahamọ awọn ọmọ ogun ti ọjọ ori wọn ko si to ogun ọdun.
''Iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe ẹni to n duna dura sọ pe oun s fun awọn ajinigbe yi pe ijọba ko ni faramọ eyi tori naa wọn yoo ni lati tu lara awọn to wa ni ahamọ wọn silẹ ni.''
Ni bayi a tun gbọ pe Malm Tukur Mamu ko sọ boya ijọba Naijiria ti tu awọn ọmọ tawọn ajinigbe yi beere silẹ .















