A kò mọ ohunkóhun pé wọ́n mú afurasí lórí ìkọlù agbébọn ní Owo - ọlọ́pàá

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ti ní àwọn ò mọ nǹkankan nípa ìròyìn pé wọ́n ti náwọ́ gán àwọn afurasí agbébọn tó ṣe ìkọlù sí ilé ìjọsìn Aguda St Francis, Owaluwa, Owo, ìpínlẹ̀ Ondo.
Nínú fọ́nrán kan tó gba orí ayélujára kan ni Olowo ti ìlú Owo, Ọba Gbadegesin Ajibade Ogunoye ti kéde fún àwọn ará ìlú Owo pé ọwọ́ ti tẹ awọn agbébọn tó wá ṣe ìkọlù náà.
Ọba Ogunoye ṣísọ lójú ọ̀rọ̀ ọ̀hún nígbà tí àwọn ará ìlú ṣe ìwọ́de lọ sí ààfin Ọba náà lórí ìkọlù tó mú ẹ̀mí àwọn tó tó ogójì lọ.
Ẹ ó rántí pé ni ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹfà ni àwọn agbébọn yawọ ilé ìjọsìn Aguda St Francis tó wà ní Owaluwa, ìlú Owo, ìpínlẹ̀ Ondo.
Kọmíṣọ́nà ètò ìlera ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo ní ènìyàn mẹ́tàdínláàdóje ló forí ṣọta ìkọlù náà ṣùgbọ́n àwọn ogójì ló pàdánù ẹ̀mí wọn.
Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Ibukun Odunlami ní àwọn ò mọ́ nǹkankan nípa ìròyìn tó jọ bẹ́ẹ̀.
“Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ò mọ nǹkankan nípa rẹ̀ o, a ò ní ìròyìn tó jọ bẹ́ẹ̀.”
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ohun tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ń ṣe láti lè tètè rii pé àwọn tó ṣiṣẹ́ náà kò sí páńpẹ́ òfin, Odunlami ní ìwádìí ti ń lọ lábẹ́lẹ̀.
Aráàlú ṣe ìwọ́de torí ìkọlù agbébọn, Olowo ní ọwọ́ ti tẹ àwọn tó ṣiṣẹ́ ibi náà

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Olowo tilu Owo, Ọba Gbadegesin Ajibade Ogunoye ti kede fun awọn araalu Owo pe ọwọ ti tẹ awọn agbebn to wa se ikọlu si sọọsi aguda nilu naa.
Ọba Ogunoye sisọ loju ọrọ yii ninu fidio kan to gba ori ayelujara kan eyi to waye lasiko ti awọn araalu se iwọde lọ si aafin rẹ lati tako ikọlu agbebọn naa.
Ninu fidio naa ni Olowo ti salaye fawọn oluwọde naa ni ede Owo pe awọn ọmọ Owo kii se ọlẹ amọ akinkanju ni wọn.
“A ti se gudugudu meje ati yaya mẹfa lati ri pe ogun ko ja ilu Owo, to si jẹ pe gomina Akeredolu, ilu yii lo ti wa.
Owo ni akikanju, ẹ ka lọ ni suuru, ohun ti mo fẹ sọ fun yin ni pe awọn to sisẹ ibi naa, wọn ti ri wọn mu.”
Ikede naa lo dun mọ awọn araalu ninu, ti wn si pariwo nla ni kete ti wọn gbọ ikede naa.
Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ buruku ni ọjọ Aiku, ọjọ karun osu kẹwa nilẹ wa nigba ti awn agbebọn kan ya bo ile ijọsin Katoliki St Francis nilu naa, ti wọn si pa eeyan to to ogoji.
Bakan naa ni ọpọ eeyan to le ni ọgbọn fi ara gba ọgbẹ gidi ninu ikọlu ọhun eyi ti ọpọ eeyan nilẹ wa n koro oju si.
Ilana atunto la n fẹ ni Najiria lati fopin si ikọlu agbebọn - Afenifere
Wayi o, ẹgbẹ Afenifere nilẹ Yoruba ti se abẹwo ibanikẹdun si awọn eeyan ilu Owo lori ikọlu awọn agbebọn to waye lọjọ nilu naa lọjọ Aiku.
Ikede kan ti alagba Ayo Adebanjo fisita loju opo Twitter rẹ lo sisọ loju eleyi.
Ikede naa ni ẹgbẹ Afenifere lasiko abẹwo wn naa se ago laafin si Olowo tilu Owo lati ba kẹdun lori isẹlẹ laabi naa.
Ẹgbẹ naa tun n tẹnu mọ ibeere rẹ pe ilana atunto orilẹede yii nikan ni awn n fẹ eyi ti yoo fi idi Naijiria mulẹ bi orilede alajọsepọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post

Awọn alaṣẹ orilẹede Naijiria ti ni awọn fura pe awọn gbẹ alakatakiti Islami State West Africa lo ṣe ikọlu aburu to waye ni ijọ Aguda St. Francis ti ilu Owo eyi to waye ni ọjọ Aiku to kọja nibi ti eeyan ogoji ti dero ọrun ti ọpọlọpọ si fara ya yanayana.
Minisita fun ọrọ abẹnu, Ọgbẹni Rauf Aregbesola lo fi eyi lede nilu Abuja nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade kan nipa aabo ilu eyi ti aarẹ Muhammadu Buhari dari nile aarẹ.

Bakan naa ni Aregbesola ti ni awọn oṣiṣẹ alaabo ti gba aṣẹ lọwọ ijọba lati wa awọn oniṣẹ ibi naa kan.
Bakan naa, Ọga agba awọn ọlọpaa Usman Alkali Baba sọ pe awọn ti kẹfin iru ọwọ awọn to ṣe ikọlu naa, bo tilẹ jẹ pe ko tii si ẹni ti wọn mu amọ o ni awọn si ti n foju sun lati mu wọn.
Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo naa ti kede pe eeyan mẹtadinlaadoje lapapọ lo faragba nibi iṣẹlẹ naa to si ni eeyan mọkanlelọgọta lo n gba iwosan lọwọ nileewosan ti wọn si tun ti da eeyan mẹrindinlọgbọn silẹ lati lọ sile.
Ṣe iru ikọlu ISWAP yii ti waye ri?
Eyi ni yoo jẹ igba akọkọ ti awọn alaṣẹ Naijiria yoo da ẹbi iru ikọlu yii ru ẹgbẹ kan.
Bi o ba si wa di pe ootọ ni, ohun ni yoo jẹ igba akọkọ ti awọn ologun IS yoo ṣekọlu si iha Guusu Naijiria eyi to n ṣafihan pe iṣẹ ibi wọn ti n fẹ loju sii.
Tẹlẹ, apa Ariwa Naijiria ni ẹgbẹ yii ti maa n ṣọṣẹ ti wọn si ti gba ẹmi ọpọlọpọ latẹyin wa ni aarin gbungbun ipinlẹ Kogi naa eyi to pa ala ibode pọ pẹlu ipinlẹ Ondo nibi ti ikọlu ti ijọ Katoliiki yii ti waye laipẹ.
Titi di asiko yii, ẹgbẹ Islamic State ko tii sọ ọrọ kankan.















