"Mo sá lọ sílé ìyàgbẹ́ nígbà tí agbébọn wọlé ìjọsìn àmọ́ wọ́n pa ìyá ìyá mi"
Ọjọ buruku esu gbomimu, ọjọ manigbagbe ti yoo si maa duro si ọpọlọ ọpọ eeyan fun aimọye ọdun ni ọjọ Aiku, ọjọ Karun osu Kẹfa ọdun 2022.
Idi ni pe ọjọ yii gan ni awn agbebọn kan ya lọ sile ijọsin St Francis Catholic Church, Owalowa nilu Owo nipinlẹ Ondo, ti wọn si seku pa ọpọ eeyan, nigba ti aimọye farapa.
Koda, ado iku ni wọn kọkọ yin mọ awọn olujọsin ijọ naa lasiko ti isin n lọ lọwọ, ki wn wa maa rọ ojo ọta ibọn le wọn lori.
Lẹyin o rẹyin, ijọ naa fi ikede sita pe eeyan mejidinlogoji lo ba isẹlẹ naa lọ sọrun alakeji nigba ti aimọye olujsin naa si fara pa pẹlu.
Lara awọn eeyan ti ẹmi rẹ bọ sinu ikọlu naa ni obinrin mama agba kan ti wn n pe ni iya alakara.
“Eeyan rere ni mama agba, iku wọn dun mi gan ni”
Nigba to n salaye bi iku mama naa se waye, ọkan lara ọmọ-ọmọ mama naa sọ fun BBC Yoruba pe ni kete ti iro ibọn n dun lakọ lakọ ni oun ti sa lọ sile iyagbẹ to wa lẹyin pẹpẹ ninu ijọ naa.
O ni nigba ti rogbodiyan naa lọ silẹ, ti oun si jade lati wa mama agba oun, ni oun ri pe o ti dagbere faye.
Ọmọde binrin yii tun salaye bi ikọlu awọn agbebọn naa se waye, oun ti oju rẹ ri lọjọ naa ati iru eeyan ti oloogbe iya rẹ jẹ.
A fẹ ki ijọba se awari awn agbebọn to wa sisẹ ibi ni sọọsi Owo- -Ọmọ oloogbe
Bakan naa ni awọn ọmọ mama to ku ọhun plu awn aladugbo rẹ salaye fun BBC Yoruba pe eeyan daada, to lawọ, to si nifẹ ọmọ nikeji ni iya agba naa.
Awọn ọmọ oloogbe wa n ke si ijọba lati sawari awn agbebọn to da ẹmi iya awọn legbodo laipe ọjọ, ki wn le fi imu ko ata ofin.
Bakan naa ni wn n rọ ijọba atawọn osisẹ eleto aabo lati dide giri si ojuse wọn nidi ipese aabo to peye fawọn ọmọ orilẹede yii, ki awn apaniyan yii yee da ẹmi wọn legbodo lọsan gangan.














