Ohun tí mo rí, ẹ̀yin kò ri ní mo ṣe di èèyàn burúkú lójú àwọn olóṣèlú - Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday Igboho
Gbajugbaja ajafẹtọ iran Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti wu ọrọ to fa ija iran Yoruba to bẹrẹ si ni gbe nigba naa lọhun to fi di wahala mọ ọ lọwọ bayii sita.
Igboho wu ọrọ yii sita nigba to fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si ẹbi awọn to fara gba ikọlu to waye ni ijọ Katoliki ilu Owo ni ipinlẹ Ondo ni ọjọ Aiku ọjọ Karun oṣu Karun.
Ninu fọnran ohun ohun Igboho ti wọn fi ṣọwọ si BBC Yoruba, Sunday Igboho ki gbogbo idile ti awọn eeyan wọn fori sọta iṣẹlẹ naa.
O si gbadura pe Ọlọrun Ọba yoo tu wọn ninu, ko si ni jẹ ki iru rẹ ṣẹlẹ mọ, yoo si doola ẹmi gbogbo eeyan.
Igboho ni: “Ẹyin baba mi ẹyin mama mi, ohun ti mo n sọ lo n ṣẹlẹ yii, ti mo n pariwo, ti mo wa di eeyan buruku loju ọpọlọpọ gomina ati Sẹnetọ.
Ohun ti mo ri ẹyin o rii, mi o ba gomina, sẹnetọ tabi họnọrebu kankan ja, ohun ti mo ri ẹyin o rii”.
Igboho ni amọ igbesẹ ti awọn afurasi Fulani n gbe ko boju mu rara nipa bi wọn ṣe ni n pa awọn ọmọ Yoruba ni gbogbo igba.
Lori iṣẹlẹ to waye ni ilu Ọwọ, ni awọn eeyan ti n fi ẹsun kan pe awọn afurasi Fulani lo wa nidi rẹ.
Amọ awọn agbofinro ko tii ri ẹnikẹni mu ninu awọn to ṣiṣẹ laabi naa tori naa, a ko le fidi ọrọ naa mulẹ rara.

Ṣe ẹ ti wa rii daadaa bayii nípa ohun tí mo ń sọ tẹ́lẹ̀, tí wọn ní mo fẹ́ da ilú rú?
“Awọn kan n sọ pe Igboho lo n da ilu ru, o fẹ da ilu ru ni ni gbogbo igba. Ṣe ẹ ti wa rii nisinsiyi bayii? Ki ni wahala ti mo fẹ da silẹ?
Sunday Igboho ṣalaye pe gbogbo nkan ti Ọlọrun fun eeyan lo fun oun naa,”ṣugbọn ohun temi n sọ ni pe taa ba n sọ pe ko kan mi ko kan mi, to ba kan eeyan to sun mọ wa nkọ, ohun ni mo ṣe n pariwo ti mo n pa yẹn wipe ka tete jọ fọwọsowọpọ”.
Igboho tun tẹnu mọ ọ pe idi niyi ti oun fi n pariwo pe ki wọn jẹ gbogbo awọn tawọn jọ jẹ ọdọ ti awọn ṣi ni okun ti wọn ni akinkanju nilẹ Yoruba jọ pawọpọ gbeja iran Yoruba lọwọ awọn Fulani.
“Ọṣẹ ti afurasi Fulani adaluru ti ṣe wa nilẹ Yoruba ti pọ”
Igboho ni awọn afurasi Fulani ti yi gbogbo ilẹ Yoruba patapata ka to si ni ati ọdun to lọ ni oun ti n ke toripe nkan ti oun ri awọn eeyan ko rii.
“Amọ o ṣi ba naa ni ko tii bajẹ, mo fẹ ki gbogbo ẹyin baba wa, ẹyin Ọba ẹyin ijoye, ẹyin alagbara ẹyin gomina... kẹẹ dide kẹẹ pe wa papọ ko to di pe aṣọ ko ni ba ọmọyẹ mọ”
Igboho ni oun ko ba ẹni kankan ja o ati pe Ọlọrun n ri oun pe gbogbo nkan to ṣẹlẹ si oun nigba ti wọn fi si ẹwọn lorilẹede Benin Republic oun ti gba kamu pe bi Ọlọrun ṣe kọ ọ ni.
“Ẹ jẹ ki gbogbo wa pa ẹnu pọ ka gba ara wa lọwọ awọn eeyan yii, iwa wa, iṣesii wa ko papọ a o jọra rara tori naa ni mo ṣe n rọ ẹyin baba mi pe kẹẹ dide”.
Igboho ni ti oun ba ti ṣẹ ẹnikẹni ki wọn dari ji oun toripe ọmọde loun bi oun si ṣe mọọ ṣe loun n ṣe e yii amọ ki awọn agba Yoruba dide si gbogbo nkan to n ṣẹlẹ yii ki wọn si pe awọn ọdọ sii.
















