Alabi Pasuma, Lalude, Alapini... Ohùn àwọn tí mò ń gbé wọ̀ fi ṣiṣẹ́ jẹun rèé - Ojo Sheu General Olak

Àkọlé fídíò, Lalude, Alapini, Odunlade Adekola pàdé lẹ́nu adẹ́rìínpòṣónú yìí

"Ọjọ 1K, 3K tàbí iṣẹ́ ọ̀fẹ́, bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹ́n àmọ́ lónìí..."

Ẹ ko ni lati gbe oju soke lati mọ pe oṣere Lalude, Alapini, Odunlade Adekola ati bẹẹ bẹẹ lọ lo n sọrọ loju agbo tẹẹ lọ.

General Olak

Amọ nigba tẹ o ba fi sun mọ iwaju, niṣe lẹ o la ẹnu silẹ tẹ o si bọ oju yin walẹ lati rii pe ṣe lootọ kii ṣe awọn ti ẹ n gbọ ohun wọn gangan lo n sọrọ.

Onimọ nipa oriṣiriṣi nkan ni Ojo Sheu ti ọpọlọpọ mọ si General Olak ni ilu Ibadan ati kaakiri Naijiria paapaa nipa igbe aye ati isọrọ si awọn gbajugbaja oṣere fiimu.

Lilo ohun rẹ lati sọrọ gẹlẹ bi awọn oṣere yii ni nkan to n pawo wọle fun General Olak bayii.

Ko lee fi ọkan pe meji rara bi ẹ ba ni ko yi si ohun eeyan mẹrin lọtọọtọ.

Adẹrinpoṣonu yii ja gbangba pẹlu ara ọtọ ọna ti o n gba ṣe ẹfẹ rẹ yii nipa sinsin ohun awọn oṣere jẹ ti ẹ o si ro pe awọn gangan lo n sọrọ bi ẹ ko ba gboju soke wo ẹni naa.

BBC Yoruba ni ifọrọwanilẹnuwo pẹlu adẹrinpoṣonu ẹlẹbun pupọ yii to si ṣalaye bo ṣe bẹrẹ owo kan ṣoṣo to fi n bọ ara rẹ yii.