Adeoye Damilare disabled shoe maker: Bí ẹ̀sẹ̀ mi méjèjì ṣe dédé di jọwọlọ láàrin òru ọ̀gànjọ́ ní kékeré nìyí

Àkọlé fídíò, 'Tí kìí bá ṣe pé mo rọ lẹ́sẹ̀, àwọn èèyàn sì kọ̀ láti gbé mi lọ ilé ẹ̀kọ́, ó yẹ kí ń ti dí "Lawyer" àmọ́...'

"Wọn o bi mi bayii, awọn obi mi sọ fun mi pe mo n rin titi di ọmọ ọdun kan amọ ni oru ọjọ kan..."

Adeoye Oluwadamilare di ẹni to n ṣe bata nitori ko ki n si ẹni ti yoo maa gbe e lọ si ile ẹkọ alọ ati abọ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ̀ nipa ohun toju rẹ ri.