APC Oyo Primaries: Shina Peller àti Teslim Folarin ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn

Shina Peller/Teslim Folarin

Oríṣun àwòrán, @ShinaPeller

Gbas gbos ti n waye laarin oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo, Sẹnetọ Teslim Folarin ati ẹni to n ṣoju ẹkun Iseyin/Itesiwaju/Kajola/Iwajowa nile igbimọ aṣofin l'Abuja, Sẹnetọ Shina Peller.

Iroyin ni Shina Peller fẹsun kan Teslim Folarin pe o ran awọn janduku ati agbanipa kan lati gbẹmi oun amọ oun moribọ.

Ṣugbọn Folarin fesi ninu atẹjade kan pe irọ nla gbaa ni ọrọ naa ati pe oun kii ṣe apaniyan, bẹẹ si ni oun ko ni awọn apaniyan kankan ni ikawọ tabi ran ẹnikẹni lati gbẹmi Peller.

Awọn janduku ti ọwọ agbofinro tẹ lọna Iseyin

Ki lo ṣẹlẹ ni Isẹyin to lọ mọ Shina Peller lẹsẹ?

Ṣaaju ni fidio kan ti kọkọ n tan kalẹ lori ayelujara, nibi ti awọn agbofinro ti mu awọn janduku kan loju ọna Iseyin.

Fidio ọhun ṣafihan awọn ọkunrin bii mẹrinla ti ọwọ awọn agbofinro tẹ, ti awọn afurasi naa si ni awọn ohun elo ipolongo ti wọn kọ orukọ Sẹnetọ Teslim Folarin si lara.

Lara awọn ohun elo ipolongo ibo naa ni ọkọ ayọkẹle, awọn fila, atawọn nnkan mii.

Oṣojumikoro kan sọ fun awọn akọroyin pe Teslim Folarin gan funra rẹ lo ṣaaju awọn afurasi janduku naa lati wa da ilu Iseyin ru nitori ọrọ ibo.

Àkọlé fídíò, 'Ó ṣì wù mí kí n fi ojú mi ríran padà, owó India ni kò sí! Hip hop yìí nìkan ni mo fi ń gbéra'

Teslim Folarin fesi

Ẹwẹ, Sẹnetọ Teslim Folari ti fesi si awọn ẹsun idunkokomọni ti Shina Peller fi kan an .

Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Aiku, o ni iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin to ni oun ran awọn janduku lati ṣekupa Shina Peller.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, o ni oun ko ran apaniyan kankan lati gbẹmi Pelle tabi ẹlomiran.

O ni "O jẹ ohun to buru jai pe Shina Peller sọ fun gbogbo aye pe mo ran awọn apaniyan si oun lai sọ eredi to ni mo fi ṣe bẹẹ."

Àkọlé fídíò, Ko sọna ni APC ati PDP

"Mo kọ lati faramọ ẹsun ti Shina Peller fi kan mi, mo si ke si awọn agbofinro lati yẹ idi ọrọ naa wo."

"O ṣeni laanu pe gomina Makinde n lo Peller lati ṣakoba fun ipolongo ibo mi ati lati da ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ oyo ru ṣaaji eto idbo gbogbogbo ọdun 2023."

Folarin pari ọrọ rẹ pe oun ko ni faramọ ibalorukọjẹ kankan, ati pe oun ti ke si awọn agbẹjọro oun lati pe Shina Peller lẹjọ lori igbiyanju rẹ lati ba orukọ rere oun jẹ.

Àkọlé fídíò, Lasisi Jasper:Wo ìtàn ayé ọ̀gọ́ àgbà iléẹ̀kọ́ Adeniran Memorial ni Ogbomoso