Freedom Jacob Caesar: Ìdí tí mo fi ń sin ẹkùn méjì bí ẹran ọ̀sín nínu ilé mi rèé

Oríṣun àwòrán, Instagram/Freedom Jacob Caesar
Awọn ara adugbo ti n fi ero wọn han lori bi gbajugbaja oniṣowo, Freedom Jacob Caesar ṣe n sin ẹkun meji ninu ile rẹ gẹgẹ bi ẹran ọ̣sin.
Awọn ara adugbo ni agbegbe naa ke gbajare sita pe ẹkun mejeeji naa ti ṣekọlu si eniyan meji, ti wọn si farapa amọ eleyii ko fidi mulẹ.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa fi idi rẹ mulẹ pe awọn gba iroyin pe wọn n sin ẹkun laarin igboro ti awọn eniyan n gbe.
Awọ̣n ẹ̣kun mejeeji lo jẹ ti oniṣowo Nana Kwame Bediako ti gbogbo eniyan mọ si Freedom Jacob Ceasar.
Awọn to fi ẹjo sun ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ẹranko naa n run nitori ile nla kan ni wọn ti wọn mọ, ti wọn ko si ri aye gba afẹfẹ to dara.
''Ni kete ti won ba ti ṣi ilẹkun bayii ni oorun ti ko dara yoo jade ninu ile ti wọn kọ wọn si naa.
Idi ti mo fi n sin ẹkun ninu ile mi re e…
Freedom Jacob Caesar sọ fun awọn oniroyin pe oun gbe awọn ẹranko inu igbo naa wa si inu ilu nitori ki wọn le ma a lo fun igbafẹ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Freedom Jacob Caesar
Ceasar ni ajumọsọ ti n waye laarin oun ati ẹka to n risi ọrọ igbafẹ ni orilẹede Ghana lọna ati mu idagbasoke ba ẹka eto igbafẹ nibẹ.
'' Ohun ti mọ fẹ ni lati ripe Ghana di orilẹede akọkọ ni iha Guusu Afrika ti yoo ni awọn ẹranko inu igbo yii ti awọn eniyan le wa ma a wo''.
''Nitori naa ni mo ṣe ra ọmọ ẹkun to je abo ati akọ ni Dubai ti ọjọ ori wọn si jẹ oṣu mẹfa.''
Nibayii, ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti yan awọn ọlọpaa lati lọ ṣọ agbegbe naa titi wọn yoo fi gbe awọn ẹranko naa kuro ni agbegbe ọhun, lọ si ibi to yẹ ki wọn wa.
Wọn ni eyi yoo da abo bo awọn araalu ati ara agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, Ghana Police Service
















