Atiku wins PDP Primaries: Wo bí Atiku Abubakar ṣe la Wike mọ́lẹ̀ tí Saraki náà sáré lọ kìí kú oríire

Oríṣun àwòrán, PDP
Igbakeji Ààrẹ Naijiria tẹ́lẹ̀ rí, Atiku Abubakar tí gbegba oroke ninu ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, Peoples Democratic Party gẹ́gẹ́ bíi ẹnikan ṣoṣo tí yóò dije du ipo Ààrẹ pelu àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú mii ni ọdun 2023.
Ibo ọọdurun o lè mọkanlelaadorin (372) eyi sì lo fi la oludije to sún mọ́ ọ gbagba, gomina Ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesome Wike to ni ibo ìgbà ó lè mẹtaledinlogoji (237).
Atiku ẹni ọdun marundinlọgọrin yìí to jẹ gbajumọ olóṣèlú tipẹ tipẹ bori ibo abẹle ẹgbẹ́ wọn ní òru mọ́júmọ́ ọjọ Ẹti.
O fẹrẹẹ to ọgọ́rin eeyan ti wọn jẹ aṣojú ẹgbẹ́ náà jákèjádò Naijiria to dibo níbi idibo abẹ́nú naa ti wọn si kún inú gbọngan papa ìṣeré MKO Abiola ni Abuja.
Awọn eekan wo ni Atiku fi ẹyin wọn gbolẹ?
Atiku Abubakar ba awọn eekan ba awọn eekan olóṣèlú míì nínú ẹgbẹ́ PDP figagbaga. Àwọn bíi, Nyesome Wike ati Bukola Saraki.
Ní báyìí, o ti pe fun ifọwọsowọpọ ẹgbẹ́ pe ki awọn lo ààtò ẹgbẹ́ awọn yanjú ìkùnsínú to bá wà dípò kí àwọn èèyàn máa gbé ara lọ ilé ẹjọ́.
Èyí ni yóò jẹ ìgbà kẹfà tí Atiku ń dije du ipo Ààrẹ.
O fìdí rẹ'mi lọdun 2019 to sì bọ mọ Ààrẹ Buhari to wa lori aleefa báyìí lọwọ.
Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party tí ṣe ijọba lorileede yìí fún ọdún mẹ́rìndínlógún títí di ìgbà tí APC gba wọn da síta lọdun 2015 nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ yàn Ààrẹ Buhari nigba naa lọhun.
Ẹwẹ, ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni tiwọn ti sun idibo abẹ́nú wọn síwájú di ọ̀sẹ̀ kini nínú oṣù kẹfà láti oludije wọn fún ipò Ààrẹ tú I'd idibo gbogbogbo yóò wáyé nínú oṣù kejì ọdún tó m bọ.
Lára àwọn tó ń figagbaga lọdọ tiwọn ni Bola Ahmed Tinubu, Ọjọ gbọn Yemi Osinbajo àti laarin awuyewuye pé Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Goodluck Jonathan náà lè gbé ìgbà idibo lábẹ́ Asia ẹgbẹ́ APC kan naa.















