2023 General Elections: Ẹ gba ìpínlẹ̀ Eko kúrò lọ́wọ́ àwọn àjòjì - Atiku sí Bode George

Bode George àti Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Igbákejì Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó tún jẹ́ olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà, Alahji Atiku Abubakar ti pàrọwà sí àwọn àgbààgbà àti ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) ní ìpínlẹ̀ Eko láti gba àkóso ìpínlẹ̀ Eko níbi ètò ìdìbò gbogbogboò tó ń bọ̀.

Atiku pàrọwà yìí nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí àgbà olóṣèlú ẹgbẹ́ PDP, olóyè Olabode George ní ilé ìgbé rẹ̀ tó wà ní Ikoyi, ìpínlẹ̀ Eko.

Atiku ní ó pọn dandan fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Eko láti fìmọ̀ ṣọ̀kan tí wọ́n bá fẹ́ ní àṣeyọrí níbi ètò ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà.

Ó ní gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP lápapọ̀ mọ̀ wí pé orin ìṣọ̀kan ni òun máa ń kọ fún nítorí àti lè ṣe àṣeyè tí alákàn ń ṣepo.

Ó fi kun wí pé tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP yóò bá kẹ́sẹ járí ní ìpínlẹ̀ Eko, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfarajìn ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yóò ṣe.

Bákan náà ló pàrọwà sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adarí wọn kí ẹgbẹ́ náà le wà ní ìṣọ̀kan.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀gá ni ooru Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ orílẹ̀èdè ti mo ti wálé; Bí mo ṣe parí iṣẹ́ 'AC' tó ń ló iná òòrùn rèé'

Nígbà tó ń fèsì sí ọ̀rọ̀ Atiku, Bode George ní kò sí àní àní wí pé Atiku mọ tinútẹ̀yìn Nàìjíríà nítorí ìrírí tó ti ní nígbà tó jẹ́ igbákejì Ààrẹ Nàìjíríà.

Bode George ní ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún 2023 ní ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní láti gba àkóso orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí àwọn sì gbọdọ̀ rún tapá titan àwọn si.

Ó fi kun pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nílò ẹni tó ní ìrírí àti ìmọ̀ kíkún nípà Nàìjíríà láti darí rẹ̀ tó sì jẹ́ pé Atiku ni fìlà náà yẹ.

Bákan náà ló ní àwọn gbọdọ̀ fìmọ̀ ṣọ̀kan ní ìpínlẹ̀ Eko nítorí ó pọn dandan fún àwọn láti gba ìpínlẹ̀ Eko lọ́wọ́ àwọn àjòjì.

Àkọlé fídíò, 'Gbogbo àgbáyé kódà America ló ń bọ̀ wá sí Omuo-Ekiti láti wá forí balẹ̀ ní Ààfin ńlá tí yóò sọ̀kalẹ̀ látọ̀run'