Derbyshire River: Ẹ wo obìnrin tó rí ikú he lẹ́yìn tó ki ara bọ inú omi tútù láti ṣe ara lóge

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arabinrin ẹni ọdun mọkandinlogoji ti ri iku he lẹyin to ti ara rẹ bọ inu odo tutu lati tun ara ṣe.
Arabinrin naa to wa lati agbegbe Manchester, ni Ilẹ Gẹẹsi lẹyin ti awọn oṣiṣẹ pajawiri de odo to wa ni Derbyshire.
Arakunrin Kevin O'Neill of Breatheolution ti o ti ṣe iru rẹ fun Coleen Rooney ati gbajugbaja oṣere Stephen Graham lo n ṣe ara logẹ fun obinrin naa.
Ninu ọrọ rẹ, O'ńeil ni inu oun bajẹ gidigidi ti oun ko si le sun daradara.
Ni oju opo rẹ ni O'neil ti ni iṣẹ ribiribi ni omi tutu n ṣe paapaa lati ṣetọju oju egbo lasiko ere idaraya tabi ipaya.
O fikun un loju opo naa pe o le ni ẹgbẹrun eniyan ti oun ti kolo si oju omi to fimọ Peak District ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, BREATHEOLUTION
Oju opo naa rọ awọn eniyan lati kọkọ lo omi tutu ni baluwẹ , ki o mọ wọn lara ki wọn to kan si oju odo lati wẹ, amọ ki wọn ṣọ ara ṣe.
Iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori iṣẹlẹ naa.
Ni ọpọ igba ni ileeṣẹ pajawiri ti kilọ fun awọn eniyan lati maṣe wọ inu omi tabi odo to wa ni gbangba.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn oṣiṣẹ pajawiri lo pe awọn pe wọn n toju arabinrin kan to ko si inu omi tutu.
Amọ o ni o ṣeni laanu pe arabinrin naa to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogoji ku loju ẹsẹ.
















