Ilorin River Dead body: Àwọn wò ló sọ òkú tí wọn dè lọ́wọ́ àti ẹnu sínú odò Asa ní Ilorin?

Oríṣun àwòrán, Kwara Fire Service
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori oku arakunrin kan ti wọn ri ninu odo Asa lọjọ Aje.
Oku yi ti wọn ko le sọ pato ẹni tii ṣe la gbọ pe wọn de lokun lọwọ ti wọn si fun aṣọ mọ lẹnu.
Alukoro ọlọpaa Kwara, Ajayi Okasanmi sọ pe nkan bi ago mẹta ọjọ Aje tawon gbo pe oku arakunrin naa lefo lori omi ni awọn sare lọ sibẹ.
O sọ fun BBC Yoruba pe ni nigba tawọn yoo fi de eti odo naa, awọn ileeṣẹ panapana ti gbe oku naa jade.
''Lootọ ni wọn gbe oku yi jade taa si ri pe wọn de arakunrin naa lokun lọwọ ati lẹnu.''
Okasanmi tẹsiwaju pe pẹlu bawọn ti ṣe ri oku yi, o daju pe awọn kan lo ṣekupa arakunrin naa ki wọn to ju oku rẹ sinu odo.
- Wo bí ọ̀rọ̀ ikú ọmọbìnrin tó fẹ́ fa àríyànjiyàn láàrín Nàìjíríà àti Ivory Coast ṣe jẹ́
- Wo ẹja tó ní eyín bíi eyín èèyàn tí apẹja kan rí he
- Wọ́n gbé ẹyin ẹlẹ́yin IVF sínu obìnrin kan, àṣírí bá tú lọ́jọ́ ìkúnlẹ̀ pé ọmọ ọlọmọ ló bí
- Ọmọ mi ti kọ́kọ́ bọ́ra sí hòhò l'àdúgbò, àbúrò rẹ̀ ń mójú tóo nílé ló sá lọ lu Lẹ́ksọrà lọ́jọ́ kejì - Baba Captain Walz
- Ẹ wo Ajá tó ń gbọ́ òórùn àìsàn ibà, ẹja tí a kò gbọdọ̀ pa àti ọọ̀nì tó ń gbọ́ àdúrà ní Ìbàdàn
''Kọmiṣana ọlọpaa ti pa wa laṣẹ lati bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yi ti a o si maa fi to yin leti bo ba ti ṣe n lọ''
O ni awọn ko ni akọsilẹ pe awọn eeyan maa n ju oku sinu odo yi ati pe ohun ti iwadii yoo fidi rẹ mulẹ ni awọn to wa nidi iru iwa yi.














