Apẹja náà ní ó ti pẹ́ tí òun ti ń gbèrò láti pa irúfẹ́ ẹja bẹ́ẹ̀

Jennette's Pier

Oríṣun àwòrán, Jennette's Pier

Iwọ apẹja kan ti ri ẹja kan to ni eyin bii ti eeyan he nilẹ Amẹrika.

Ẹja naa ni wọn ri he nibi kan ti wọn n pe ni Jannette's Pier to gbajumọ fun ẹja pipa lagbegbe North Carolina.

Ẹja ọhun ni eyin lẹnu, eyin ọhun si farajọ eyin ọmọ eniyan eyii ti wọn ni o maa n lo lati fi mu ijẹ.

Iroyin ni ọkunrin kan ti orukẹ rẹ n jẹ Nathan Martin to maa n ṣabẹwo si Jannette's Pier lo ri ẹja naa he ninu odo.

Martin ni o ti to ọjọ mẹta kan ti oun ti n gbero lati ri iru ẹja bẹẹ mu ki oun to ri eyii ti eyin kun ẹnu rẹ yii.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho Update: Igboho ti sọ ohun tó fẹ́ kí a ṣe tí ọ̀rs bá bẹ́yìn yọ- Saheed Yusuf

O sọ fun ileeṣẹ iroyin McClatchy News pe "Ko rọrun lati ri ẹja mu ninu ibu ṣugbọn inu mi dun pe mo ri eyii mu, o si dun lẹnu gigi."

Ọpọ awọn eeyan lo ti bẹrẹ si n sọ erongba wọn nipa ẹja naa lori ayelujara lẹyin ti wọn fi aworan rẹ lede.

Bi awọn kan ṣe n fi oju kayeefi wo ẹja naa, lawọn mii n sọ pe ẹyin ẹja ọhun fẹẹ pọ ju ti awọn lọ.

Àkọlé fídíò, Olawale Dada: Igbá bárà kọ́ ló kàn, àwa náà n ṣoríire láyé pẹ̀lú ìpèníjà 'Cerebral Palsy'