DSS on Nigierian arrest: Kò sí olóṣèlú kankan tó ń pàṣẹ fún wa pé kí á máa ti aráálú mọ́lé- DSS

DSS

Oríṣun àwòrán, @DSS

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti sọ pe kii ṣe awọn eeyan pataki kan to lagbara lo ni kawọn máa ti awọn ọmọ Naijiria mọlẹ.

Nigba ti o fesi sí ọrọ kan ti gbajugbaja akọroyin, Olusegun Adeniyi kọ nínú iwe iroyin pe omilẹgbẹ alaiṣẹ lo wa latimọle ajọ DSS.

Alukoro ajọ DSS, Ọmọwe Peter Afununanya sọ ninu atẹjade to fi sita pe erongba Adeniyi lo kọ nipa ajọ DSS buru jai, o lè ṣí ni lọna.

Alukoro DSS ni niiṣe lo yẹ ki Ọgbẹni Adeniyi fa akọsilẹ naa yọ.

"Lai ṣetan lati máa ba ọ gbọ̀rọ yii bi ẹni n gba igba ọtí, inu ajọ DSS ko dun sí ohun ọrọ ti Adeniyi kọ sinu iwe iroyin pe ogunlọgọ ọkunrin ati obinrin alaiṣẹ lo wa ni atimọle DSS nitori aṣẹ awọn eeyan kan to lagbara.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...

Mi o sọrọ nipa awọn ọlọ́pàá amọ nipa ajọ DSS, o dami loju pe ko si ẹni kankan to wa ni ahamọ DSS nitori pe ẹnikan pàṣẹ lati ibi kan.

Ajọ DSS ni ilana lawọn n tẹle, ati pe iṣẹ awọn akọroyin ni fi ẹrí ọkàn ati otitọ inu ṣiṣẹ wọn.

Àkọlé fídíò, Ọ̀pẹlọpẹ́ Ajá tí Ifa ní kí a fi ṣètùtù ní Ekiti ní 1942 ni kò jẹ́ kí ìjàmbá náà pọ̀ jù- Ol

Ko yẹ ki àwọn eeyan máa fi ẹnu tabuku ajọ DSS.

Nkan to buru ni ki akọroyin to ti wa ni ipò nlá ninu ijọba máa ṣọ iru ọrọ bayii.

Àkọlé fídíò, Bí ìjọba bá kọ̀ tí kò ṣèdájọ́, tí Ọlọ́pàá kọ̀ pé àwọn kọ́ ló paá, ẹni tó pa ọmọ mi, náà máa ...

Niṣe lo yẹ k'awọn araalu máa gbé oriyin fun ajọ DSS nitori iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe ni Naijiria.

Lootọọ, kii ṣe pe ajọ DSS ko ni abawọn kankan ṣugbọn a n gbiyanju agbara wa," alukoro ajọ DSS lo ṣalaye bẹẹ.