Cholera Outbreak: Bí ènìyàn Ọ̀ọ́dúnrún ṣe fò ṣán'lẹ̀ kú rèé torí ààrùn onígbà méjì ní Kano ati Jigawa

Awọn eeyan to n gba itọju nile iwosan

Oríṣun àwòrán, Ministry of Health

O le ni eniyan ọgọrun kan to ti dagbere fun duniyan bi aarun onigba meji (Cholera) se n gbilẹ si ni Naijiria lat bi ọsẹ mẹrin sẹyin.

Dokita Salihu Mu'azu to je akowe ile ise eto ilera lo salaye ọrọ yii ni Dutse ti se oluulu Jigawa.

O ni eniyan bi ẹgbẹrun marun lo ti wa ni idaduro nile iwosan.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ "Ni ọjọ Aiku to kọja ati ni akọsilẹ eniyan ọgọrun to ti ku ti awọn egberun marun miiran si wa ni ile iwosan, ijọba ibilẹ mọkandilogun ninu mẹtadinlọgbọn lo ti de.

Bakan naa lo ni aarun naa tete n gbilẹ nitori omi ti ko mò gaara ti wọn n mu ati bi wọn kii se fọ eso ati ewebẹ wọn daradara, ati pe ọpọ ni igbeaye imọtoto jina si.

O ni ajọ UNICEF ti dide iranwọ lati mojuto adinku aarun naa.

Inu fu aya fu naa ni awọn eniyan ipinlẹ Rivera wa paapaa julọ Bille Kingdom ni ijoba ibilẹ Degema lẹyin ti ajakalẹ aarun naa bẹsilẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe ko si akọsilẹ pe ẹnikẹni ku, sugbọn ọpọ lo fi àpẹrẹ aisan naa han

Alaga ijoba ibilẹ naa Michael Williams ti saaju lati ko awon eleto ilera lọ sibẹ lti mọ bi ọrọ naa se ri.

O ni Gomina Nyesom Wike ti pa alasẹ fun ile isẹ eto ilera ipinle naa ati awọn ile miiran ro niṣe pẹlu rẹ lati lọ mojuto isẹlẹ naa

Orileede Naijiria ti n koju aarun Kọlẹra lọdọọdun paapaa julọ lasiko ojo, sugbọn bi o se n seku pa awọn eniyan ni ọdun yii ju ti atẹyin wa lọ

Gẹgẹ bi akọroyin BBC Ishaq Khalid to n jabo lati ilu Abuja se sọ o ni, ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun ni Naijiria, NCDC ti fi idi rẹ mulẹ pe aarun Kolẹra ti tan ka awọn ipinlẹ ro le ni odaji gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria.

NCDC fi kun pe ẹgbẹgbẹrun ni awọn to ri lugbadi aarun naa ti awọn akaimọye ọgọrun eniyan si ti ku, ti ọpọ wọn si jẹ ọmọde pẹlu.

Ajọ naa ni iha Arewa Naijiria ni ọrọ naa ka n ju, o si ti bẹrẹ lati inu oṣu kẹta ọdun, sugbọn o tun n peleke si lati bi ọsẹ diẹ sẹyin.

Bakan naa ni o salaye pe, eyi tun darapọ mọ bi aarun Covid-19 ṣe n pọ si ati bi awọn dokita se daṣẹ silẹ.

Pẹlu bi gbogbo eto ilera se n dẹnukọlẹ awọn alaṣẹ n tiraka lati fi opin si itankalẹ aarun kọlẹra.

Apẹrẹ aisan naa ni ki eniyan maa bi ki o si maa ya igbẹ gbuuru bakan naa ni omi yoo maa gbẹ lara.

Eniyan le lugbadi aarun naa ti o ba mu omi ti kokoro kọlẹra ti wọ nipa iwa ai ni imọtoto.

Ti aarun naa ba mi de oju ẹ ti ko si si itọju to yẹni asiko, eniyan le ku laarin wakati diẹ.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...