Lady stabs Sugar Daddy: Wọ́n fẹ̀sùn kan afurasí náà pé ó jí ọkọ̀ olóògbé náà lẹ́yìn tó gbẹ̀mi rẹ̀ tán

girl kill sugar in Uyo

Oríṣun àwòrán, anaedoonline

Ọdọbinrin kan ti ko si gbaga ọlọpaa lori ẹsun pe o ṣa ọrẹkunrin rẹ pa niluu Uyo.

Iroyin ni ọdọbinrin naa gbe ọkọ ayẹkẹlẹ Mercedes Benz oloogbe naa sa lọ, tohun ti awọn ojulowo iwe ọkọ ọhun.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, oloogbe naa ni ọmọkunrin kan ṣoṣo ti awọn obi rẹ bi, o si jẹ oniṣowo to maa n ko ọja wọle lati oke okun si Naijiria.

Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ ṣugbọn ti ko fẹ ki awọn akọroyin fi orukọ oun lede sọ pe lẹyin ti gbogbo igbiyanju awọn ọrẹ oloogbe naa lati kan si ja si pabo ni wọn wa lọ ki wọn to ṣawari rẹ ninu agbara ẹjẹ to wa.

O ni "lẹyin naa wọn ṣawari ọkọ Mercedes Benz rẹ pẹlu ẹrọ olutọpa "tracker" to wa lara ọkọ naa."

"Ile itura kan ni wọn ti ba ọrẹbinrin naa ti wọn furasi pe oun lo pa ọkunrin naa, ile itura yii kan naa ni wọn ti ri ọkọ ayọkẹlẹ ọhun."

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...

Nigba ti BBC kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom, SP Odiko S. Ogbeche-Macdon, o ni lootọ ni awọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa.

Ogbeche-Macdon sọ pe awọn ko tii le sọ ni pato ohun gan to ṣokunfa iku oloogbe naa.

O fi kun pe awọn ti fi ṣiku ofin mu afurasi kan ti awọn gbagbọ pe o lọwọ ninu iku oloogbe naa, awọn si ti bẹrẹ iwadii.

Àkọlé fídíò, Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde