Racheal Oniga's burial date: Ẹbí Rachael Oniga kéde ètò ìsìnkú òṣèré tó d'olóògbé

Oríṣun àwòrán, @Racheal
Ẹbi gbajugbaja oṣere Nollywood, Rachael Oniga ti kede ọjọ kẹrindinlọgbọn ati ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2021 yii.N kò mọ̀ pé àsìkò yìí ni máa dágbéré fún Rachel Oniga- Jide Kosoko
Oniga jẹ Ọlọrun nipe lọjọ Ẹti, ọgbọnjọ oṣu keje.
Aisan to niiṣe pẹlu ọkan ni wọn lo pa oṣere naa.
- ‘Ibi a gbé dàgbà níi se pẹ̀lú ìhùwàsì wa’
- Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá tí kìí ṣe ọmọ káàárọ̀ oòjíire
- Irọ́ ní ò, Adeyinka Daniel, akẹ́kọ̀ọ́ FUTA tí kú kí wọ́n tó gbé e wá sí ''health Centre'' FUTA
- Àlááfíà ni Bola Tinubu wà - Sanwo - Olu
- UAE yí ìpinnu padà,ìrìnàjò bàálù bẹ̀rẹ̀ padà láàrin Nàìjíríà àti Dubai
Ogbeni Ejike Asiegbu lo sọ eyi di mimọ nile oloogbe naa laipé.
O ni oloogbe naa ti fohun silẹ ṣaaju iku rẹ pe ipinlẹ̀ Eko ni ki wọn sin oun si ti ọlọ́jọ́ ba de.
Nitootọ, Oloye ni Racheal Oniga ni ipinlẹ̀ Delta.
Asiegbu ni oun ati oloogbe ti di ọrẹ bii ọmọ iya lati ọdun pipẹ wa ati aladuroti nigba iṣoro.
O ni oun ni baba okeere fun ọmobinrin Oniga to ti pe ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn bayii.
Asiegbu ni Georgina, to jẹ akọbi ọmọbinrin Racheal Oniga fidiẹ mulẹ fun oun pe ikọlu si ọkan ẹni lojiji lo pa iya oun kii ṣe Covid 19 bi awọn kan ṣe kọkọ sọ.
Awọn eekan nipinlẹ̀ Eko bii Desmond Eliot, Femi Branch Segun Arinze, Victor Osuagwu, Femi Durojaiye, Emeka Rising Ibe, Don Pedro -Agambi, ati Abubakar Sanusi ti kan si ile oloogbe lati ba wọn kédun ni Magodo
A gbọ pe Oniga ti n ṣe aisan fun igba diẹ ki ẹlẹmi to gba a.
Wọn bi Oniga ni Ebute Metta nipinlẹ Eko lọdun 1957 amọ ọmọbibi ilu Eku nipinlẹ Delta ni awọn obi rẹ.
Oniga bẹrẹ ere ṣiṣe lọdun 1996 nigba to kopa ninu ere "Onome."
Lẹyin naa lo tun kopa ninu oniruuru ere bíi "Sango" ati "Super Story."
- Ẹ fún wa ní oṣù márùn ún láti fí lé àwọn ajínigbé Fulani kúrò nínú igbó- Olórí Fulani
- Kí ló mú kí géńdé múra bí obìnrin láti bá ọ̀rẹ́bìrin rẹ̀ kọ ìdánwò?
- Ṣàǹgbá fọ́! Ìrètí Nàìjíríà fún góòlú, Adekuroye pòfo nínú ìjànkadì ní Tokyo 2020
- Ilé ẹjọ́ fún Sunday Igboho ní ànfààní láti rìn ní òmìnira láàrin ìlú
- Ìwádìí ní gómìná New York fipá k'ẹnu ìfẹ́ sáwọn obìnrin, Biden rọ̀ ọ́ pé kó fipò sílé















