Is Bola Tinubu still alive: Sanwo-Olu ní ìròyìn ikú Tinubu ló mú òun ṣàbẹ̀wò si ní London

Oríṣun àwòrán, @JUBRIL
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sọ pe alaafia ni eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu wa.
Tinubu lo sọ ọrọ naa lẹyin to ṣe ifilọlẹ awọn katakata mejilelọgọrun un ati ọkọ ikolẹ ọgọrun un ti ileeṣẹ kolẹ-kodọti ipinlẹ Eko, LAWMA, ṣẹṣẹ ra.
Gomina ọhun to ti kọkọ ṣabẹwo si Tinubu niluu London sọ pe "Eredi ti mo fi ṣabẹwo si olori wa ko ṣẹyin awọn iroyin iku ti mo n gbọ nipa rẹ."
"Alaafia lo wa, a sọrọ lori awọn ohun to n ṣelẹ ninu ẹgbẹ wa ati ni Naijiria lapapọ."
Sanwo-Olu tẹsiwaju pe "Alaafia lo wa nitori mo fi oju mi ganni rẹ, ko sì sí wahala kankan."
Ti ẹ ko ba gbagbe, oniruru iroyin lo ti kọkọ jade pe Tinubu ti jade laye.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe o wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun nile iwosan, lawọn mii n sọ pe o ti ku loke okun.
Awọn kan tilẹ sọ pe o ti to nnkan bii ọsẹ meji ti adari ẹgbẹ oṣelu APC naa ti jade laye.
Ẹwẹ, agbẹnusọ oloṣelu naa, Tunde Rahman sọ ninu atẹjade kan pe ko si nnkankan to ṣe Tinubu. "Tinubu ò kú o, àlááfíà ló wà, àmọ́..."
Ninu atẹjade naa lo ti sọ pe lootọ ni Tinubu ko si ni Naijiria lọwọ yii, ṣugbọn ko ṣaisan, bẹẹ si ni ko si nile iwosan kankan.
Kílódé tí àwọn eèyàn fi ń tẹnumọ pé Tinubu ti kú?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹnu ọjọ mẹta yii iroyin kan gbode lori ayelujara pe eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ti jade laye. "Tinubu ò kú o, àlááfíà ló wà, àmọ́..."
Iroyin ọhun mi ori ayelujara titi nitori irufẹ ẹni ti oloṣelu naa jẹ lawujọ, paapaa ninu ẹgbẹ APC to wa lori aleefa ijọba.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti iroyin yoo jade pe Tinubu ti ku, tabi pe o wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun nile iwosan.
- Irọ́ ní ò, akẹ́kọ̀ọ́ FUTA tí kú kí wọ́n tó gbe wá sí ''health Centre'' iléèwé ''
- ''Ìròyìn òfegè lásán ni! Tinubu kò lùgbàdí coronavirus''
- Tinubu ló lè ṣeé lọ́dún 2023, Pa Fasoranti àti Oba Osemawe Ondo sọ̀rọ̀ sókè
- Ìjọba Amẹ́ríkà ti kó abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 mílíọ̀nù mẹ́rin fún Nàìjíríà
- Taní Wolí rẹ̀? Èmí ti jèrè ''Minister''; Woli Joshua Iginla fí ọkọ̀ ńla ta mí lọ́rẹ- Alaseyori tó kọ orin Oniduromi
- Njẹ́ o mọ̀ pé bíi ọdún 700 sẹ́yìn ni wọ́n ti ń bọ Osun-Osogbo? Mọ̀ síi nípa ìtàn ojúbọ̀ nàá
- Ta ni Tunji Disu ti wọ́n kéde láti rọ́pò Abba Kyari?
- Dáa padà! Àwa kìí ṣe ẹgbẹ́ kan náà pẹ̀lú APC tó dojú Nàìjíríà kodò -PDP sí Jega
Ṣugbọn lẹyin ti awọn iroyin bẹẹ ba ti n ja lori ayelura ni Tinubu maa n yọju si awọn ọmọ Naijria, ti yoo si sọ pe lakọ ni oun wa bi ibọn.
Awọn wo lo n fọnrere iku Tinubu?
Lara awọn to n fọnrere iku Tinubu ni gbajugbaja sọrọsọrọ loju opo Instagram ati Facebook, Esther Asabi Aboderin, ti ọpọ mọ si Esabod.
Esabod tun kọrin o di gbere o Tinubu......
Koda, o tun bu gbogbo awọn to n sunkun fun Tinubu pe o ti ku.

Oríṣun àwòrán, Esabod Instagram
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan ni ko faramọ irufẹ awọn ọrọ ti Esabod maa n sọ lori afẹfẹ, pupọ awọn eeyan lo maa n tẹti si ọrọ rẹ ni gbogbo igba to ba n ṣeto rẹ lalalẹ ọjọ Aiku.
Ninu ọkan lara awọn eto naa lo ti sọ pe "Tinubu ti ku, o ti rin jina."
Esabod ni "Tinubu ti ku o, o ti ku lati ọsẹ meji sẹyin."
Esabod tun ni ki Tinubu ba oun ki iya ati baba oun ni ọrun.
Obinrin naa tun tẹnumọ pe "Tinubu ti ku o, koda awọn angẹli ti n da seria fun bayii lori bo ṣe ta iran Yoruba fun awọn Fulani."
Yatọ si Esabod, ileeṣẹ iroyin kan to tun n sọrọ nipa iku tabi aisan Tinubu ni Sahara Reporters.
Ninu iroyin kan ti wọn fi lede, Sahara Reporters ni "Tinubu ti wa nile iwosan kan bayii nilẹ Amẹrika, o si n ṣaisan gidi."
Iroyin naa tẹsiwaju pe ara rẹ ti ko da ni ko jẹ ko kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ to waye lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun yii, atawọn ayẹyẹ mii to yẹ ko yọju si.
- Ẹ wó bí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn ṣe rí òkú ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú kílásìí...
- Dáa padà! Àwa kìí ṣe ẹgbẹ́ kan náà pẹ̀lú APC tó dojú Nàìjíríà kodò -PDP sí Jega
- Wo àmí ẹ̀yẹ tí Abba Kyari tí gba gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagìrì ọlọ́pàá kí wọ́n tó fi ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu kàn án
- Wo iná olójú mẹ́rìndínlógún, arugbá àtàwọn ohun míì tí yóò wáyé l'Ọdún Osun Osogbo 2021
Ki ni Tunde Rahman sọ?
Ẹwẹ, agbẹnusọ oloṣelu naa, Tunde Rahman sọ ninu atẹjade kan pe ko si nnkankan to ṣe Tinubu. "Tinubu ò kú o, àlááfíà ló wà, àmọ́..."
Ninu atẹjade naa lo ti sọ pe lootọ ni Tinubu ko si ni Naijiria lọwọ yii, ṣugbọn ko ṣaisan, bẹẹ si ni ko si nile iwosan kankan.
O pari atẹjade naa pe Ọlọrun nikan lo le sọ igba ti ẹnikẹni le jade laye.
Ki ni awọn eeyan n sọ?
Lẹyin ti ileeṣẹ BBC Yoruba jabọ pe Tinubu ko ku gẹgẹ bii atẹjade ti Tunde Rahman to jẹ agbẹnusọ rẹ fi lede, ni ọpọ awọn ọmọ Najiria ti bẹrẹ si n sọ erongba wọn lori iroyin iku ọhun.

Bi awọn kan ṣe n ṣadura fun Tinubu pe Ọlọrun yoo lọra ẹmi rẹ, ni awọn kan n sọ pe ko si ohun to n jẹ iku fun oloṣelu naa lasiko yii.

Bẹẹ naa ni awọn mii sọ pe ko gbọdọ ku bayii, ayafi to ba mu awọn araalu kuro ninu iya to fi wọn si.

Gbogbo ẹ gbogbo ẹ, awọn araalu kan ti n sọ pe o yẹ ki oloṣelu naa yọju sita lati ba awọn eeyan sọrọ to ba jẹ lootọ lo ṣi wa laaye ti ko si ṣaisan.

Oríṣun àwòrán, @Jubril
Awon wo lo ti wa ri Tinubu bayii?
Lalẹ ana ni fọto yii ati awọn miran to safihan aworan yii jade lori ayelujara.
Ninu awọn fọto naa ni a ti ri gomina Sanwo Olu to n tukọ ipinlẹ Eko pẹlu Oloye Bola Tinubu.
Ninu fọto naa ni awọn kan ti ni o hande pe o fẹ rẹ baba diẹ bẹẹ naa ni awọn mii ni eyi ṣa ti fihan pe o ṣi wa laye.
- Ẹ wó bí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn ṣe rí òkú ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú kílásìí...
- Dáa padà! Àwa kìí ṣe ẹgbẹ́ kan náà pẹ̀lú APC tó dojú Nàìjíríà kodò -PDP sí Jega
- Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbajúmò ọlọ́pàá, Abba Kyari tí wọ́n kó pọ̀ mọ́ "rógà" pẹ̀lú Hushpuppi?
- Àwọn dókítà da iṣẹ́ sílẹ̀ káàkiri Naijiria, ilé ìwòsàn dá páròpáro!
- Taní Wolí rẹ̀? Èmí ti jèrè ''Minister''; Woli Joshua Iginla fí ọkọ̀ ńla ta mí lọ́rẹ- Alaseyori tó kọ orin Oniduromi
















