Sunday Igboho: Ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n lọ wá onídùró wá

Ilẹ ẹjọ giga kan niluu Abuja ti gba beeli awọn eeyan mejila ti ajọ ọtẹmulẹ DSS fi ṣikun ofin mu nile oloye Sunday Igboho niluu Ibadan.
Akọroyin BBC Yoruba to wa nile ẹjọ naa jabọ pe wọn gba beeli mẹjọ lara awọn eeyan naa pẹlu miliọn mẹjọ naira.
Nigba ti ile ẹjọ ni ki wọn gba bẹẹli awọn mẹrin to ku ni miliọnu mẹwaa naira.
Agbẹjọro Sunday Igboho to n ṣoju awọn eeyan naa, Pelumi Olajengbesi sọ pe inu oun dun pe wọn fun awọn eeyan ọhun ni ominira to yẹ wọn.
- N8M tán yán-yán ni Abba Kyari gbà lọ́wọ́ Hushpuppi - FBI Amẹríkà
- Ilé ẹjọ́ fún Sunday Igboho ní ànfààní láti rìn ní òmìnira láàrin ìlú
- Ẹ fún wa ní oṣù márùn ún láti fí lé àwọn ajínigbé Fulani kúrò nínú igbó- Olórí Fulani
- Àwọn ọmọ Sunday Igboho mẹ́jọ̀ nínú méjìlá níkan ní DSS gbé wá sí iléẹ̀jọ́ - Agbẹjọrò
- Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ ní Benin níbi ìgbẹ́jọ́ Sunday Igboho nìyí
- Wọ́n ti fi ẹ̀sùn míì kan Sunday Igboho ní ìlú Benin! - Agbẹ́jọ́rò Igboho
- Tóò bá ń dédé sọ fótò tàbí fídíò nù lórí fóònù, Watssap ló gbé ètò tuntun jáde ó!
Gẹgẹ bo ṣe sọ, "Ile ẹjọ ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe awọn eeyan ri idajọ ododo gba ṣugbọn o ku ni ibọn n ro."
Ile ẹjọ naa sọ siwaju si pe ki awọn eeyan naa lọ wa oniduro wa, oniduro naa si gbọdọ jẹ ẹni to n san owo ori rẹ dede, o kere tan, lati ọdun meji sẹyin.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ sọ pe mẹjọ lara awọn eeyan naa ni yoo gba ominira, nigba ti awọn mẹrin to ku yoo ṣi wa ni ahamọ ṣugbọn ọrọ yi pada nile ẹjọ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021 yii ni DSS fi ṣikun ofin mu awọn eeyan naa nile Sunday Igboho to wa niluu Ibadan, nibi ti wọn ti pa awọn meji, ti wọn si ba ọpọlọpọ dukia jẹ.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
A le gba béélì àwọn mẹ́jọ nínú èèyàn Igboho 12 tí a kó, kó ku mẹ́rin - DSS

Agbẹjọro awọn oluranlọwọ Sunday Igboho mejila ti awọn oṣiṣẹ ajọ DSS fi si ahamọ, Pelumi Olajengbesi ti bẹ ile ẹjọ lati tu awọn onibaara rẹ silẹ.
Lasiko ti igbẹjọ naa n waye nile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa nilu Abuja, Olajengbesi tako bi ajọ DSS ṣe ni oun le gba beeli eeyan mẹjọ ninu awọn eniyan naa, nitori pe iwaddi fihan pe ipa ti wọn ko ninu kiko awọn nkan ijagun pamọ nile Sunday Igboho, ati awọn ẹsun iwa ọdaran miran, kere.
Ajọ DSS fikun ọrọ rẹ pe awọn mẹrin yooku ko ipa pataki ninu bi ibọn AK-47 meje, Pump Action mẹta, Stomp Gun kan, ati ọta ibọn 1295, ṣe wa nile Igboho.
Wọn ni awọn nilo ọjọ mẹrinla si i, lati pari iwadii lori awọn mẹrin naa.
DSS sọ pe o sẹesẹ ki awọn eniyan naa gba beeli tan, ki wọn o si salọ , eyi to le ṣe idiwọ fun iwadii to n lọ lọwọ.
"Bi Sunday Igboho to jẹ olori wọn, ti ijọba kede pe oun n wa ba le gbiyanju lati sa kuro ni Naijiria, dipo ko farahan, ko si aridaju pe awọn ọmọ ẹyin rẹ mẹrin yii ko ni i salọ."
Ṣugbọn ṣa, agbẹjọro awọn eniyan naa, Olajengbesi sọ pe titẹsiwaju lati fi awọn onibaara oun si atimọle tako ofin Naijiria ati ẹtọ ọmọniyan.
O ni "bi ajọ DSS ṣe n fi ọrọ ẹnu lasan sọ nile ẹjọ pe ki wọn fun oun ni anfaani ọjọ mẹrinla si i lati fi awọn eniyan naa si ahamọ ko ba ofin mu.
"O yẹ ki wọn o kọwe beere fun eyi lọtọ ni, kii ṣe ninu igbẹjọ ti a n ṣe lọwọ."
Ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021 ni awọn oṣiṣẹ ajọ DSS ko awọn eeyan mejila naa lasiko ti wọn kọlu ile Sunday Adeyemo Igboho nilu Ibadan.
Wọn si fi ẹsun kan wọn pe wọn ko nkan ijagun pamọ lọna ti ko ba ofin mu, ati awọn ẹsun iwa ọdaran miran.
Wọn kò jẹ́ kí àwọn akọ̀ròyìn wọlé sí ilé ẹjọ́ tí wọ́n kó àwọn olùrànlọ́wọ́ Igboho lọ ní Abuja
Awọn oṣiṣẹ alaabo ọtẹlẹmuyẹ DSS lo kun ile ẹjọ giga ijọba apapọ nibi ti igbẹjọ yoo ti waye lori ẹsun ti wọn fi kan awọn oluranlọwọ mejila fun Sunday Igboho.
Akọroyin BBC to wa ni ile ẹjọ naa jabọ iroyin pe wọn ko faaye gba akọroyin kankan lati wọle sinu gbọngan igbẹjọ naa.
Koda, o ni ọna ẹyinkule ni wọn ko awọn afurasi naa gba wọle si gbọngan igbẹjọ.

Ìgbẹ́jọ́ n tẹ̀síwájú lórí àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho méjìlá tí DSS kó nílè rẹ̀

Igbẹjọ yoo ma a tẹsiwaju lonii, nile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa nilu Abuja, lori ẹsun ti ajọ DSS fi kan awọn amugbalẹgbẹ gbajugbaja ajijagbara, Sunday Igboho, ti wọn ko nile rẹ nilu Ibadan.
Igbẹjọ kan waye ni ọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu Kẹjọ, ṣugbọn adajọ to n gbọ ẹjọ naa, Obiora Egwuatu sun igbẹjọ siwaju.
Eyi ko ṣẹyin bi ajọ DSS ṣe kuna lati ko gbogbo awọn afurasi naa wa si ile ẹjọ, to si jẹ pe orukọ to wa ninu iwe ipẹjọ tun yatọ si orukọ awọn eniyan naa.
Mejila ni awọn eeyan naa to jẹ tọkunrin-tobinrin ni wọn ko, ṣugbọn awọn mẹjọ pere ni wọn ko wa sile ẹjọ.
Agbẹjọro wọn, Pelumi Olajengbesi ni ajọ DSS n tẹ oju ofin mọlẹ pẹlu bi wọn ko ṣe mu awọn mejila naa wa si ile ẹjọ.
- Àwọn ọmọ Sunday Igboho mẹ́jọ̀ nínú méjìlá níkan ní DSS gbé wá sí iléẹ̀jọ́ - Agbẹjọrò
- Sunday Igboho, ìsáǹsá rẹ̀ kò lé sá mọ́ wa lọ́wọ́, mímú lá mú ọ - DSS fọwọ́ gbáyà
- Ó tó gẹ́, Sunday Igboho fẹ́ gbé ìjọba lọ ilé ẹjọ́ bí wọn kò bá tú àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀
- "DSS yin ọta ìbọn 48 sí Adogan, kò sì kú, ni wọn bá fi ọmọ odó fọ lórí"
- Ẹ wó bí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn ṣe rí òkú ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú kílásìí...
Olajengbesi ni orukọ awọn mẹjọ ti wọn ko wa naa ko ba ara wọn mu lasiko ti wọn n pe orukọ wọn ni ileẹjọ lasiko ti Adajo Obiora n ṣe ayẹwọ orukọ wọn.
Iroyin ni wọn ti gba beeli awọn kan, amọ agbẹjọro wọn ni ko si ohun to jọ ọ, ati wi pe eniyan mẹrin ninu wọn ni DSS jẹ ki wọn ri lasiko ti awọn lọ si ihamọ ti wọn wa.
Adajọ Obiora wa paṣẹ fun ikọ DSS lati pada lọ ṣe ifilọlẹ orukọ wọn silẹ daradara, ki wọn si ri pe awọn mejila naa ni wọn ko wa si ileẹjọ ni Ọjọọru, ọṣẹ yii ti igbẹjọ yoo tẹsiwaju.



















