University of Calabar: Ẹ wó bí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn ṣe rí òkú ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú kílásìí...

Enya Egbe

Oríṣun àwòrán, Enya Egbe

Arakunrin Enya Egbe ti sọ iriri rẹ pẹlu bi o ṣe sa kuro ni kilaasi ti wọn ti n kọ nipa ẹya ara eniyan lẹyin to ri oku ti wọn fun un lati lo fun iṣẹ amurele.

Arakunrin, ẹni ọdun mẹrindingbọn sọ ohun ti oju rẹ ri ni ọdun meje ṣẹyin ni fasiti Calabar nibi ti awọn akẹkọọ nimọ iṣegun ti pejọ lati ṣiṣẹ pẹlu oku mẹta ti wọn fun wọn lati ṣiṣẹ le lori.

Amọ, iyalẹnu lo jẹ fun un nigba ti o ri pe oku ti wọn fun oun lati ṣiṣẹ le lori jẹ oku ọrẹ oun timọ timọ fun ọdun meje, Divine ti wọn si ti n wa.

O ni awọn jọ ma n lọ si ile igbafẹ ni alẹ ni, to si sọ wi pe oju ibọn meji ni oun ri ni igba aya rẹ.

Ọkan lara awọn akẹkọọ ti wọn tẹle sare jade ni Oyifo Ana, ti o si ba nibi ti o ti n sun ẹkun.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..

''Ọpọlọpọ awọn oku ti a ma n lo ni ileewe lati fi kọ ẹkọ ni iho ibọn wa nibẹ, to si ṣeeṣẹ ki awọn eniyan naa ma hu iwa ọdaran.''

''Mo ti lẹ ti ri awọn ọlọpaa ti wọn n gbe oku awọn eniyan wa si ileewe wa nitori o ni ile igbokusi.''

Awọn afẹhọnuhan EndSars

Oríṣun àwòrán, AFP

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni Egbe wa ranṣẹ si ẹbi awọn ọrẹ rẹ Divine lati wa gbe oku rẹ ti wọn ti n wa tipẹ tipẹ.

Iroyin nipe awọn obi Divine ti n wa lati agọ ọlọpaa kan si omiran lẹyin ti ọlọpaa mu oun ati awọn ọrẹ rẹ ti wọn lọ gbafẹ.

Àkọlé fídíò, Ọmọ Ìjọ Deeper Life Pọ́ńbélé ni ìyà mi àti bàbá mi, mo sì dàgbà síbẹ̀ àmọ́ bíbọ Èṣù ọ̀dàrà lọ́nà tó tọ́ -

Awọn obi Divine pada gba oku naa,ti wọn si ṣewadii ọlọpaa ti o ṣekupa a, ti wọn si yọ niiṣẹ.

Iṣẹlẹ naa mi Egbe titi, to fi mu u padanu ọdun kan lẹnu ẹkọ rẹ, ti ko si le e ba awọn ara rẹ jade fasiti nigba kan naa.

Ọdun to kọja kaakiri orilẹede Naijiria ni awọn ọdọ bọ sita lati ṣe ifẹhọnuhan Endsars tako bi awọn ọlọpaa ṣe n pa awọn ọdọ Naijiria ati bi wọn ṣe n fi iya jẹ wọn lọna aitọ.

An afẹhọnuhan Endsars

Oríṣun àwòrán, AFP