Abba Kyari, Hushpuppi: Wo àmí ẹ̀yẹ tí Abba Kyari tí gba gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagìrì ọlọ́pàá kí wọ́n tó fi ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu kàn án

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abba Kyari
Iroyin to ti kale ka oko ni pe gbajugbaja ọlọpaa ti gbogbo eniyan mọ si kogberegbe, Abba Kyari ti lọ rokun nile fun ẹsun iwa ajẹbanu.
Eyi ko ṣẹyin iwadii ti ẹka iwadii orilẹede Amerika gbe jade lẹyin ti Hushpuppi to jẹwọ lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara fi lede be Abba Kyari ti fi igba kan ran ohun lọwọ lati mu olubaṣiṣẹpọ ohun, ki wọn si tii mọle.
Lara awọn ẹsun wọnyii ni orilẹede Amerika fi kan Abba Kyari ti wọn si pe fun ifipanpẹ mu u, ki o lọ jẹjọ lorilẹede Amerika.
G̣ẹgẹ bi otẹlẹmuyẹ, o ti gba ọpọlọpọ ami ẹyẹ moriwu lorilẹede Naijiria ati ni oke okun fun iṣẹ takuntakun to ṣe ni ẹka ọlọpaa.
- Àwọn ohun mẹ́rin tó yẹ kí ẹ ko mọ nípa Ramoni Igbalode tí gbogbo ayé ń pè ní Hushpuppi
- Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá, ẹ ríi dájú pé ẹ tú gbogbo àṣírí nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Abba Kyari àti Hushpuppi - Àpapọ̀ Agbẹjọ́rọ̀.
- Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́nu mẹ́rin ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìwádìí Abba Kyari àti Ramoni Igbalode
- Hushpuppi: Ẹ lọ gbé Abba Kyari wá jàǹtò láti sọ tẹnu rẹ̀ - Ilé ẹjọ́ Amẹrika
- Ẹ wo Ọmọ Nàìjíríà mẹ́ta míì tí FBI Amẹ́ríkà tún ti mú báyìí tó ń bá Hushpuppi ṣiṣẹ́ òlè àgbáyé tó ń jà

Wo ami ẹyẹ ti wọn ti fi da Abba Kyari lọla lẹnu iṣẹ;
- Igba mẹta lo gba ami ẹyẹ iṣẹ takuntakun (IGP Commendation Medal for courage 2012, 2013, 2014)
- Igba mẹta lo gba ami ẹyẹ Gomina ipinlẹ Eko fun ọlọpaa to tayọ julọ(Lagos State Governor's award for Gallantry, Leadership and Service excellence 2011, 2012, 2013).
- Ami ẹyẹ kọmiṣọnna ọlọpaa to yege julọ (Lagos State Commissioner of Police Commendation Award for courage 2011).
- Ọlọpaa to gbogun ti iwa ọdaran julọ ni iha iwọ oorun Afrika (Best Anti-Crime Police Officer in West Africa from Security Watch Africa)
- Ami ẹyẹ Star Award lati ọwọ CRAN 2011, 2012, 2013, 2014, 2015, 2016 & 2017
- Ami ẹyẹ Star Award fun ọlọpaa to fakọyọ julọ ni ilẹ Afrika (Outstanding Gallantry In Africa 2018 by Security watch Africa)
- Ọtẹlẹmuyẹ to fakọyọ julọ ni ilẹ Afrika ni ọdun 2018 (Africa's Best Detective Of the Year 2018).
- Ọlọpaa to fakọy julọ laarin ọdun mẹwa (The best Police officer of the Decade Award)
- Ami ẹyẹ 2018 HERO of the year Award by Silverbird Group
- Ami ẹyẹ aarẹ fun akọni lati ọwọ aare Buhari ni ọdun 20216.
Wo nkan to yẹ ki ẹ mọ nipa Abba Kyari
- DCP Abba Kyari wa lati ẹya Kanuri ni ipinḷẹ Borno, to wa ni Ila Ariwa orilẹede Naijiria, ti wọn si bi ni Ọjọ Kẹtadinlogun, Oṣu Kẹta, Ọdun 1975. Ọdun 2005 lo darapọ mọ awọn ọlopaa ko gbere gbe, ti wọn si gbe wa si ẹka ileeṣẹ wọn to wa ni ipinlẹ Eko.
- Ọga Abba Kyari ka iwe gba oye ninu imọ Geography ko to di pe o darapọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria gẹgẹ bi Cadet ni ọdun 2000 lẹyin to kuro ni ileẹkọ awọn ọlọpaa, Police Academy ni Wudil, ni ipinlẹ Kano.
- Ọkan lara awọn iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ to ṣe ti okiki rẹ fi kan ni bi o ṣe fi panpẹ ọlọpaa mu ogbontagiri ole, ti wọn pe orukọ rẹ ni Ndagi, ti inagijẹ rẹ si n jẹ Spirit. Spirit lo ti ko ilu Numan ni papamọra ni ipinlẸ Anambra fun ọpọlọpọ ọdun, ki ọwọ to tẹ ẹ.
- Amọ ọdun 2020 ni wọn tu SARS ka lori ẹsun ipaniyan ati fifi ẹtọ awọn ọmo Naijiria dun wọn paapaa awọn afurasi. Ọdun marun un lo fi wa pẹlu SARS ki wọn to tuwọnka.
- O mu ogbontagiri ajinigbe ti orukọ rẹ n jẹ Chukwudumeme Onwaumadike Aka Evans ni ipinlẹ Eko ati awọn olubaṣiṣẹpọ rẹ.
- O fi panpẹ mu awọn to pa adari ọmọogun ofurufu tẹlẹ, Air Marshal Alex Badeh 'rtd' ni opopona Keffi-Gitata Kaduna.
- O fi panpẹ ọba mu ọga awọn ikọ Boko Haram Umar Abdulmalik ati awọn mẹjọ miran
- Awọn ikọ ọmọogun Boko Haram to ji awọn ọmọ ileẹ̀kọ́ Chibok gbẹ ni ọdun 2014.


















