Hushpuppi: Wọ́n ti ń wá Ọgá Ọlọ́pàá Abba Kyari l'Ámẹ́ríkà láti wá jẹ́jọ́ọ kí ló wà láàrin rẹ̀ àti Hushpuppi

Abba Kyari ati Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, Daily Nigerian

Ilé ẹjọ́ Amẹrika pàṣẹ kí FBI fi ṣìkún òfin mú ọ̀gá ọlọ́pàá, Abba Kyari lórí ọ̀rọ Hushpuppi

Hushpuppi: Ẹ lọ mú Abba Kyari wá láti sọ tẹnu rẹ̀ - Ilé ẹjọ́ Amẹrika

Ile ẹjọ kan nilẹ Amẹrika ti paṣẹ pe ki wọn fi ṣikun ofin mu igbakeji kọmiṣọna ọlọpaa kan ni Naijiria, Abba Kyari.

Gẹgẹ bii iwe aṣẹ ile ẹjọ naa to tẹ iwe iroyin abẹle People's Gazzett lọwọ ṣe sọ, Ortis Wright lati ile ẹjọ naa to wa ni California lo ni ki ajọ ọtẹlẹmuyẹ FBI o ṣawari Abba Kyari lati wa sọ tẹnu rẹ lori ohun to mọ nipa bi Hushpuppi ṣe n lu awọn eeyan ni jibiti.

Ṣaaju ni Hushpuppi ti kọkọ sọ fun ile ẹjọ naa pe Abba Kyari lo ba oun fi ṣikun ofin mu alatako oun ninu iṣẹ jibiti, Chibuzor Vincent, lẹyin ti Chibuzor halẹ mọ Hushpuppi pe oun yoo tu aṣiri bo ṣe lu oniṣwo kan to jẹ ọmọ ilẹ Quatar ni jibiti.

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'

Iwe ile ẹjọ naa sọ pe Hushpuppi pẹlu awọn marun un miran gbimọpọ lati lu oniṣowo kan ni gbajuẹ, lẹyin ti wọn parọ fun oniṣowo naa pe awọn n ṣiṣẹ pẹlu banki ti yoo ya oniṣowo ọhun lowo lati fi kọ ile ẹkọ lorilẹ-ede Quatar.

Lara awọn ti wọn gbimọ pọ lati lu oniṣowo naa ni jibiti gẹgẹ bii iwe ile ẹjọ ọhun ṣe ṣalaye ni Abdulrahman Juma lati Kenya, Chibuzo Vincent lati Naijiria, to fi mọ Yusuf Anifowoshe; Rukayat Fashola; ati Bolatito Agbabiaka.

Ṣugbọn wahala bẹ silẹ laarin awọn eeyan naa lẹyin ti Vincent leri pe oun yoo tu aṣiri gbajuẹ naa, eyii to mu ki Hushpuppi maa lepa rẹ.

Àkọlé fídíò, Kemi Olunloyo on Sunday Igboho: Mi ò gbè lẹ́yìn Yoruba Nation àmọ́ mo wà lẹ́yìn Sunday Igb

Iwe ile ẹjọ naa ni "Kyari jẹ ọkan lara awọn igbakeji kọmiṣọna ọlọpaa to gbajumọ gidini Naijiria, oun lo fi ṣikun ofin mu Vincent lẹyin ti Hushpupi bẹẹ lọwẹ."

Ẹwẹ, ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Facebook rẹ, Kyari sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa jibiti kankan ati eosun ti wọn fi kan oun.

O ni lootọ ni Hushpuppi ke si awọn ọlọpaa pe Vincent halẹ pe oun yoo ṣekupa awọn mọlẹbi oun ni Naijiria ṣugbọn iwadii awọn fi han pe ko si ohun to jọ bẹẹ.

Kyari tun sọ pe oun ko gba owo Kankan lọwọ Hushpuppi ati pe yatọ si ọrọ Vincent, ohunkohun ko pa awọn mejeji pọ ayafi igba ti oun juwe aranṣọ oun si, ti aransọ naa si ba ran aṣọ, eyii to fi owo iṣẹ rẹ ranṣẹ si aranṣọ naa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Hushpuppi ti tọwọ bọwe pe lootọ ni oun lu ọpọ eeyan ni jibiti lori ayelujara ati pe oun gba pe oun jẹbi awọn ẹsun gbajuẹ ti wọn fi kan oun.

Eyii to n tumọ si pe o ṣeeṣe ki Hushpupi fi aṣọ penpe roko ọba nilẹ Amẹrika fun nnkan bii ogun ọdun.

A kò bèrè fún owó kankan lọ́wọ́ Hushpuppi - Abba Kyari dá èsì padà fún ileẹjọ́ US

Kọmisana ọlọpaa Naijiria, Abba Kyari ti sọ pe ir ni ẹsun ti wọn fi kan ileeṣẹ ọlọpaa pe wọn gba owo lọwọ Raymond 'Husspuppi' Igbalode to n jẹjọ lọwọ ni United States.

Bakan naa, wọn fẹsun kan pe Hushpuppi fun Abba Kyari ni owo abẹtẹlẹ.

Ẹka to n ri si idajọ nilẹ Amẹrika sọ pe awọn ti fi panpẹ ofin mu ọmọ orilẹede Naijiria mẹta bayii ni Amẹrika to n ran Hushpuppi Abbas lọwọ to fi ji miliọnu owo Dollar $1.1m ni ọna idigunjale wiwọke owo jade.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita lati ẹka ile ẹjọ naa ni ọjọ kejidinlọgbn oṣu keje, 2021 sọ pe Hushpuppi jẹwọ to si gba pe lootọ ni oun jẹbi ẹsun jiji owo gọbọi atawọn ẹsun mii to lu mọ eto akanṣe katakara "Business Email Compromise Schemes".

Atẹjade ẹka idajọ ilẹ Amẹrika ọhun (DoJ) tun ṣafihan rẹ pe yatọ fun Abba Kyari, hushpuppi tun san owo abẹtẹlẹ fun igbakeji kọmisana ọlọpaa Naijiria lati lee fi panpẹ ofin mu akẹgbẹ rẹ ninu jiji owo, Kelly Chibuzo Vincent to jẹ ẹni ogoji ọdun.

Eyi waye gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọọ, lẹyin ti Vincent gbiyanju lati tu aṣiri iṣ ti wọn ṣe to si s fun afurasi naa ohun ti wọn ṣe sii.

"Ninu iwe naa, Kyari jẹ ọga onipo giga Kọmisana ileeṣẹ Ọlọpaa Naijiria ti wọn fẹsun kan pe o ṣe eto bi wọn yoo ṣe fofin mu Vincent ki wọn si juu si ẹwọn labẹ aṣẹ Abbas ti wọn yoo si fi awọn fọ́tò rẹ ranṣẹ si Abbas lẹyin ti wọn ba gbaa mu.

Amọ Abba Kyari ti fi ọrọ sita pe bẹẹ kọ lori oun ko si gba owo kankan lọwọ Hushpuppi.

Àkọlé fídíò, Ọmọ Ìjọ Deeper Life Pọ́ńbélé ni ìyà mi àti bàbá mi, mo sì dàgbà síbẹ̀ àmọ́ bíbọ Èṣù ọ̀dàrà lọ́nà tó tọ́ -

Esi Abba Kyari ree

ẹsun ti wọn fi kan Abba Kyari pe o da lori ẹri ti Hushpuppi gbe wa siwaju ile ẹjọ Amẹrika gẹgẹ bi ọkan lara nkan to fẹ fihan.

BBC gbiyanju lati kan gbọ latẹnu Abba Kyari gangan lori ọrọ yii ṣugbọn pabo lo ja si.

Ẹwẹ, o fi atẹjade sita loju opo facebook rẹ ninu eyi ti akọṣẹmọṣẹ ọga ọlọpaa naa kọọ sita pe lootọ o Hushpuppi kan si oun amọṣa ko tilẹ si labẹ ofin iṣẹ rara tori pe Vincent bẹrẹ si ni fi iku dẹru balẹ.

Kyari ni ọlọpaa pada tu Vincent silẹ lẹyin ti iwadii fihan pe ko jẹbi.

"Ẹyin ara ati ọrẹ, Abbas ti a pada wa mọ si Hushpuppi pe ọfiisi wa ni nkan bii ọdun meji sẹyin lati sọ pe eeyan kan ni Naijiria to fẹ gba mi oun o si fi nọmba ipe ẹni naa ranṣẹ o tun bẹbẹ pe ki wọn gbe igbesẹ ki ẹni naa to lọ ṣekọlu si mọlẹbi ohun.

A tọpinpin a si fi ofin mu afurasi naa amọ lẹyin iwadii ni gbogbo wa rii pe ko tilẹ si ẹni to n dẹru bolẹ lati gba ẹmi ẹnikẹni to si ni ọrẹ atijọ lawọn amọ ija owo wa laarin awọn. La ba pada tu afurasi naa silẹ pẹlu beeli".

"Ko sẹni to gba owo kobo lọwọ Abbas Hushpuppi. Afojusun wa ni lati gba ẹmi awọn eeyan la. Ipe idẹrubani nikan la maa n pe". Abba Kyari sọrọ.

Àkọlé fídíò, 'N10 la ṣì ń ta Ọṣẹ Aboke látayédáyé! Òòṣà ni àrùn ìgbóná, gbogbo yín lẹ sì níi lára, èèwọ̀ rẹ̀ rèé o'