El-Zakzaky IMN judgement: Ilé ẹjọ́ ti dá el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, @imnigeria_org
Gẹgẹ bi ile ẹjọ giga kan nipinlẹ Kaduna, ṣe ti da Olori ìjọ ẹsin Islam Shia (Islamic Movement in Nigeria), Ibrahim El-Zakzaky ati iyawo rẹ silẹ, ajọyọ ti n lọ lọtun losi.
Kete ti wọn pari ẹjọ naa ni wọn fi ọkọ gbe El-Zakzaky ati iyawo rẹ kuro ninu ọgba ile ẹjọ naa to si kọwọ rin pẹlu agbẹjọro rẹ, Femi Falana.
"O jẹ Idajọ to mu iṣẹgun lẹyin gbogbo ipamọra ti olori ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Musulumi shitte yii ṣe lati ibẹrẹ ẹjọ naa". Ẹgbẹ IMN lo sọ bẹẹ.
Ẹgbẹ Islamic Movement in Nigeria, gboriyin fun eto idajọ loriḷede Naijiria lẹyin idajọ to tu El-Zakzy silẹ lẹyin ọdun mẹfa ni ọgba ẹwọn.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ IMN naa fi lede ni idajọ naa fi idi ẹgbẹ wọn mulẹ, to si fi idi otitọ mulẹ, lati tapa si ijọba amunipa ti ko fẹ ki otitọ jọba.
''Pẹlu idajọ to waye loni, o fihan pe ko si otitọ kankan ninu ẹsun ti wọn fi kan El-Zakzaky ati iyawo rẹ'. Nitori naa o dara lati ni ifarada loju ogun ati ijọba amunisin nitori ni igbẹyin otitọ ni yoo leke''.
Ni ọdun 2015 ni ijọba fi panpẹ ọba mu El-Zakzaky lẹyin ti awọn ọmọ ẹyin rẹ kolu awọn ikọ ọmọogun Naijiria ni ilu Zaria, nipinlẹ Kaduna.
Ileẹjọ giga nipinlẹ Kaduna ti paṣẹ ki ijọba apapọ fi Sheikh Ibrahim El-Zakzaky ati iyawo rẹ, Zeenat silẹ lati ma a lọ ni alaafia nitori wọn ko jẹbi ẹsun kankan.
Gẹgẹbi agbẹjọro El-Zakzaky, Sadau Garba ṣe sọ, ileẹjọ tu wọn silẹ ni ọjọru ḷyin ti ẉn da gbogbo ẹsun onigun mẹjọ ti ijọba ipinlẹ Kaduna pe mọ wọn nu.
''Ileẹjọ ni awọn ẹsun naa ko fi ẹsẹ mulẹ''
Sadau ni bawo ni ileẹjọ yoo ṣ e fi ẹsun kan awọn eniyan ni ọdun 2015, ti wọn si ṣẹṣẹ gbe ofin kalẹ lori ẹsun naa ni ọdun 2017.
Akọroyin ileeṣẹ BBC to wa nibẹ ni wẹrẹ ti ileẹjọ da ẹjọ naa tan ni El-Zakzaky ati iyawo rẹ ko si inu ọkọ ti wọn si lọ si ile, lai da awọn akọroyin lohun ibeere ti wọn n bi wọn.

Oríṣun àwòrán, other
Titi di asiko yii, ijọba ipinlẹ Kaduna ko i tii sọ boya awọn n gbe ẹjọ naa lọ si ileẹjọ kotẹmilọrun.
Ni ọdun 2015 ni ijọba fi panpẹ ọba mu El-Zakzaky lẹyin ti awọn ọmọ ẹyin rẹ kolu awọn ikọ ọmọogun Naijiria ni ilu Zaria, nipinlẹ Kaduna.
Ni Osu Kẹfa, ọdun 2020 ni ileẹjọ ijọba apapọ paṣẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa san miliọnu marundinlogun naira gẹgẹ bi owo gba ma binu fun awọn ọmọlẹyin Sheik Ibrahim El-Zakzaky lẹyin ti wọ pa awọn mẹta ninu awọn alatilẹyin rẹ to n fẹhọnu han ni ilu Abuja.
Awọn mejeeji n jẹjọ lori ẹsun to nii ṣe pẹlu dida wahala silẹ laarin ilu, ati kikorajọpọ lọna ti ko ba ofin mu.Sugbọn awọn ẹsun naa ti ijọba ipinlẹ Kaduna fi kan wọn, ni ile ẹjọ ti danu, to si pàṣẹ pe ki wọn o tu wọn silẹ ni kiakia.
- 'Nàiìjíríà ti pèsè ''Private jet'' tí yóò gbé Igboho padà sílé láti Cotonou sílẹ̀ kí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀'
- Ẹbí gba ẹ̀mí ọmọdébìnrin kan nítorí ó wọ ṣokoto "jeans"
- Kí ni Ọ̀gágunfẹ̀yìntì Buratai ń ṣe ní Benin Republic, ìlú tí Sunday Igboho ti ń jẹ́jọ́?
- Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà dá Akeredolu láre lórí ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo
Ọdun 2015 ni ọwọ tẹ el-zakzaky lẹyin rogbodiyan nla to waye laarin awọn ọmọ ijọ rẹ ati awọn ọmọ ogun Naijiria nilu Zaria.Awọn ajafẹtọ sọ pe o le ni ọọdunrun ọmọ ijọ zakzaky ti awọn ọmọ ologun pa lasiko naa.Lẹyin naa ni ijọba Naijiria pe ijọ naa ni ẹgbẹ agbesunmọmi.

Oríṣun àwòrán, other













