Ibrahim El-Zakzaky: Zeenat lùgbàdì covid-19 lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, IHRC rọ Buhari kó tú òun àti ọkọ rẹ̀ sílẹ̀

Adari ẹgbẹ Shiite, El-Zakzaky

Zeenat El-Zakzaky ti lugbadi arun coronavirus lọgba ẹwọn to wa pẹlu ọkọ rẹ, Ibrahim El-Zakzaky niluu Kaduna.

Ọmọkunrin kan ṣoṣo to ku fun olori awọm musulumi Shiite, Ibraheem Zakzaky ṣalaye pe iya oun ti n fi awọn apẹẹrẹ coronavirus han ki wọn to ṣe ayẹwo fun un.

Ọmọkunrin El-Zakzaky ni ayẹwo ti awọn dokita obi oun ṣe lo fihan pe mama oun ti lugbadi arun coronavirus.

O ni awọn dokita ọhun tun ṣe oriṣiiriṣii irufẹ ayẹwo miiran fun iya oun lọgba ẹwọn.

Ibraheem ni o ṣe pataki lati fidi rẹ mulẹ pe ijọba ti dena mọ iya oun lati lọ gba itọju lori arun inu egungun orunkun(arthritis) ti o mu un fun ọpọ ọdun.

Àkọlé fídíò, Lawal Ayankemi Oluwatoyin: Mo kọ̀ láti máa tọrọ owó nítorí ojú mi tó fọ́, iṣẹ́ ló wù mí

Ẹwẹ, ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, IHRC ti kepe Aarẹ Muhammadu Buhari wi pe ko da El-Zakzaky ati aya rẹ silẹ lọgba ẹwọn lati le daabo bo wọn lọwọ arun coronavirus.

Bakan naa ni ajọ ọhun tun kọwe si ajọ iṣọkan agbaye, UNO lati sọ fun ijọba orilẹede Naijria pe ko fi wọn silẹ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Ajọ IHRC ṣalaye siwaju si pe arun covid-19 ti iyawo El-Zakzaky ti ni bayii le wu awọn mii silẹ lara rẹ nitori ailera to ni.

Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan naa ni ọgba ẹwọn ti olori awọn musulumi Shiite wa le ṣakoba nla fun ilera rẹ papaa julọ bi arun covid-19 ṣe n pọ si lojoojumọ yii.

Àkọlé fídíò, LASTMA Yesufa: Àwọn dókítà gbìyànjú lórí ojú mi ṣùgbọ́n...

IHRC sọ pe iwa to buru jai ni ijọba Naijiria hu lori bi o ti ju tọkọ-taya si ọgbọn wọn nigba ti ileẹjọ ko tii sọ pe wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

El-Zakzaky ati aye rẹ Zeenat ti wa ni ẹwọn fun ọdun mẹfa bayii.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Alagba Ajibola láti Fakunle ní olùkọ́ wa lórí ètò ìró lónìí