Nollywood Yoruba epic movies: Wo àwọn sinimá mẹ́wàá tó gbé sinimá Yorùbá sáyé lọ́pọ́ ọdún sẹ́yìn

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ọpọlọpọ awọn ere itage ati sinima lawọn agba oṣere ni ilẹ Yoruba ti gbe jade eleyi to ti mi orilẹede Naijiria ati oke okun tititi.
Ṣaaju asiko yii, itan ati agbekalẹ ere Yoruba maa n mu ọpọlọpọ lọkan to bẹẹ gẹ ti awọn ti kii ṣe ọms Yoruba.
Bẹẹ, wọn ko si gbọ Yoruba pẹlu nigba naa maa n joko ti awọn eeyan to ba gbọ lati maa tu ohun ti wọn ba sọ nitori igbesẹ ṣisẹ n tẹle awọn ere sinima naa, a maa fa eeyan to ba n wo o lọkan, yala o gbọ ede Yoruba ti wọn n sọ ni tabi ko gbọ.
Ni awọn nnkan bii ọgbọn ọdun si ogoji ọdun sẹyin, awọn ere manigbagbe kan to jẹ Yoruba pọ lọ biba, ṣugbọn mẹwaa ninu wọn la o maa gbe yẹwo ninu akọsilẹ yii.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ogbori Ẹlẹmọṣọ
Ko si aniani bi eeyan ba sọ pe sinima ogbori ẹlẹmọṣọ wa lara awọn sinima to jade ni ilẹ Yoruba to si jẹ manigbagbe. Sinima ti ọwọja rẹ tan kalẹ kọja orilẹede Naijiria ni ti ọpọ ẹya ati ede si wo o.
Iṣe ati itan ere naa pẹlu awọn oṣere to ṣe ni wọn dun un wo.Itan iṣẹdalẹ ilu Ogbomọṣọ ni, Ogbori Ẹlẹṣọ, ni ipa ti Lalude ko ninu ere naa , ti Lere Paimọ si ko ipa Ṣọun Ogunlọla nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ti Oluwa nilẹ
Ere kan ti ọpọ ọmọ Yoruba, paapaajulọ awọn onworan sinima Yoruba ni sinima "Ti Oluwa nilẹ".
Ninu sinima yii ni Alhaji Kareem Adepọju ti ọpọ mọ si Baba Wande ti di ilu mọọka. Sinima to kọ ẹkọ to si tun panilẹrin ni.
Ti Oluwa nilẹ da lori pataki ti Yoruba so mọ awọn dukia ilu, paapaa ilẹ Oriṣa.
Ohun to gbe soke ni bi Yoruba ṣe maa n bọwọ fawọn ohun iṣẹdalẹ rẹ pẹlupẹlu idukoko aṣa ọlaju.
Awọn eeyan kan fẹ ra ilẹ fi ṣe owo nla ni wọn ba kan si oloye ilu naa kan, iyẹn Oloye Ọtun (Baba Wande)
Wọn gbe owo gọbọi fun lẹyin o rẹyin gbogbo awọn to lọwọ si tita ilẹ naa loriṣa ilu naa pa.
Adapọ awada laarin ẹkọ ti wọn fẹ fi sinima naa gbe jade tun jẹ ki ọpọlọpọ onworan o tun gbadun sinima naa pẹlu awọn eekan alawada bii Kayọde Ọlaiya (Adẹrupọkọ)
Tunde Kelani lo dari ere naa naa lọdun 1993, Kareem Adepoju lo kọ ọ. Awọn agba oṣere bii
Dele Odule, Lekan Oladapo, Yemi Shodimu, Yetunde Ogunsola, Oyin Adejobi, Gbolagbade Akinpelu, Jide Oyegunle, Akin Sofoluwe naa kopa ninu ere naa.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
O le ku
Ọkan lara awọn iwe akagbadun ti Ọjọgbọn Akinwunmi Iṣhọla kọ ni ọdun 1974 ni "O leku". O le ku yii ni eekan onisinima, Alagba Tunde Kelani sọ di sinima ni ọdun 1997.
Itan ere ifẹ laarin ololufẹ Aṣakẹ, Lọla ati Ṣade ti wọn fẹ fẹ Ajani ni nnkan bii aadọta ọdun sẹyin ni iwe ati sinima yii. Gbogbo ohun elo ti wọn si lo nibẹ lo ṣe afihan eyi.
Sinima yii lo si ṣe agbende iro ti ko ju orokun lọ tawọn eeyan n lo ni aye igbaun pada sagbo faari eyi ti a wa n pe ni ole ku.
Ajani jẹ akẹkọ ipele aṣekagba ni fasiti to n wa afẹsọna nitori ipe iya rẹ to n fẹ ko ṣe igbeyawo ni kiakia.
Sinima yii rinlẹ lasiko to jade nigba naa.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Koto aye
Ọkan lara awọn ere to gbilẹ ni nnkan bii ọgbọn ọdun sẹyin ni ere yii.
Oloogbe Ajilẹyẹ lo ṣe. Nigba naa, awọn ere to ṣe afihan igbagbọ Yoruba ninu aye akamara ni oloogbe Ajilẹyẹ maa n ṣe nigba naa.
Ija laarin awọn awọn ẹlẹyẹ funfun ati dudu ni sinima naa da le lori.
Awọn agba oṣere bii Oloogbe Ajilẹyẹ, Oyiboyi, Kọledowo, oloogbe Oriṣabunmi, Abija ati bẹẹbẹl lọ lo wa ninu sinima yii.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Yemi my lover
Ọkan lara awọn ere sinima to milẹ nigba to jade ree. Ere ifẹ ni Alagba Yẹmi Ayebọ maa n saba n ṣe nigba naa pẹlu awọn orin ifẹ ninu rẹ.
Lẹyin ipapoda Ade Love, ko fi bẹẹ si awọn sinima ifẹ to ni alafibọ orin ninu mọ ki Yẹmi Ayebọ to de pẹlu sinima Yẹmi my Lover. Sinima naa da lori omidan Moji ati Yẹmi ṣugbọn ti o ba inira diẹ pade.
Lọdun 1990 ni ere naa jade, awọn osere bii Abija, Yẹmi lukuluku, Thompson, Alabi yellow ati bẹẹbẹẹlọ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ẹran iya Oṣogbo
Ere miran niyi to tun gbajumọ lọpọ ọdun sẹyin.
Alhaji Yẹkini Ajilẹyẹ lo gbe sinima naa jade nigba naa. Itan Ewurẹ abami kan to n hu iwa buruku ni sinima yii da le lori.
Awọn agbagb oṣere bii Grace Oyin-Adejọbi (Iya Osogbo), Kọledowo, ati bẹẹbẹlọ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Owo Blow.
Ọkan lara awọn gbajumọ ere sinima to waye laarin ogun ọdun si ọgbọn ọdun sẹyin ni sinima Owoblow jẹ.
Ọpọ onwoye sinima Yoruba lo si n sọ pe ere yii gan lo sọ Taiwo Hassan (Ogogo) ati Yinka Quadri(kura) di gbajugbaja.
Sinima naa da lori ọdọkunrin kan to di janduku ati ọlọsha lẹyin ti wahala awọn ẹbi rẹ tii sita.
Awọn agbofinro ran baba rẹ lọ sẹwọn, ileewe si lee jade nitori aile san owo ileewe.
Wọle gbiyanju ohun gbogbo to lee ṣe lati tọju iya rẹ atawọn aburo rẹ ṣugbọn ko bọ si ki o to di ajẹgboro lẹyin ti wọn koo mọ "roga" ti ko si fẹ pada lọ ba iya rẹ mọ nitori ojuti.
Awọn eekanosere to kopa ninu rẹ ni Racheal Oniga, Bayo Bankole, Adebayọ Salami (Ọga Bello), Adewale Ẹlẹṣọ, Kayọde Odumoṣu, Binta Ayọ Msgaji, Sam Loco Efe, Bimbọ Akintọla, Ọmọọba Leke Ajao

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Larinlọọdu
Ere awada ni Larinlọọdu jẹ. ọkan lara awọn eekan alawada igba naa, Babatunde Omidina (Baba Suwe) ati aya rẹ oloogbe Monsurat Omidina (Mọladun).
Gbajugbaja agbe sinima sita ni, Shan George, Jide Kosọkọ, Yọmi King (Ọpẹbẹ), Yẹmi Ẹlẹshọ, Dele Odul.
BMuka Ray, Rẹmi Surutu, Doris Simeon, oloogbe Henrietta Kosokọ, oloogbe Alaaran, oloogbe Yọmi Ogunmọla, Gbenga Adewusi naa ba wọn lọwọ si sinima naa nigba naa.
Itan rẹ da lori Baba onile kan (Baba suwe)

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Abẹla pupa
Ara awọn sinima ti alagba Ọlaiya gbe sita ni. oloogbe Ajidara ko ipa manigbagbe ninu sinima yii.
Sinima naa da lori fifi ipa wa owo pẹlu awọn alafibọ awada ninu rẹ.
Awọn eekan oṣere bii Branch, Bimbọ ọshin, Ajidara, Ọlaiya ati bẹẹbẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Saworoidẹ
Ara awọn sinima ti Tunde Kelani gbe jade ni Saworo idẹ. Itan to yannana ipo eto oṣelu lorilẹede Naijiria nigba naa ni Saworoidẹ.
Lasiko ti orilẹede Naijiria wa labẹ iṣejọba ologun to si n gbaradi fun ijọba alagbada ni.
Awọn eekan oṣere bii Kọla Oyewọ, Lere Paimọ, Bukky Wright, Kunle Bamtẹfa, Kọla Ọlaiya (Adẹrupọkọ), oloogbe Bayọ Faleti, Ọjọgbọn Akinwunmi Ishọla,
Ere yii lo gbe Kunle Afọlayan ati Kabirat Kafidipẹ jade faye ri.





















