Michael Boulos, America: Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọkùnrin ará Naijiria tó fẹ́ ẹ di àna Donald Trump

Tiffany

Oríṣun àwòrán, @Tiffany Trump Inst

Michael Boulos: Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọkùnrin ará Naijiria tó fẹ́ ẹ di àna Donald Trump

Ọkan lara awọn ọmọbinrin Aarẹ Donald Trump, Tiffany, ti kede pe ọrẹkunrin rẹ atọkọ pipẹ Michael Boulos ti fun ni oruka ileri igbeyawo.

Lori ayelujara Instagram rẹ ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ọhun ti kede rẹ lọjọ ti isejọba baba rẹ wa sopin.

Àkọlé fídíò, America Inauguration Joe: Wo àwọn eré orí ìtàgé tí Donald Trump ṣe kó tó fi ipò aàrẹ sílẹ̀

Iyawo keji ti Trump fẹ, Marla Maples lo bi ọmọbinrin naa fun un.

Lati ọdun 2018 ni irinajo ifẹ Tiffany pẹlu Michael to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun ti di ilumọọka.

Olokoowo ni Michael.

Lasiko ayẹyẹ idupẹ ọlọdọọdun ilẹ America, 'Thanksgiving' lọdun 2018 ni Tiffany safihan Boulos fun ẹbí rẹ.

Ta a ni Michael Boulos?

Orilẹ-ede Lebanon ni wọn bi Michael si, sugbọn orilẹ-ede Naijiria lo dagba si, nibi ti ẹbí rẹ ni okoowo si.

Bo ṣe jẹ ọmọ orilẹ-ede Lebanon, lo tun jẹ ọmọ orilẹ-ede France.

Àkọlé fídíò, US Vice President:Ẹ wo ìtàn obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ igbákejì Ààrẹ ilẹ́ Amẹrika?

Irinajo rẹ ni Naijiria:

Nigba to wa ni ọmọde lo ko wa si Naijiria.

Tiffany

Oríṣun àwòrán, @Micheal Boulos Inst

Baba rẹ, Dokita Massad Boulos ni alamojuto okoowo wọn, iya rẹ, Sarah Boulos si jẹ Oludasilẹ 'Society for Performing Arts of Nigeria'.

Nipasẹ ẹgbẹ naa lo n pese iranlọwọ fun awọn oṣere, akọrin ati awọn to n jo lati mu afojusun wọn ṣẹ lai fi ọjọ ori wọn ṣe.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Sarah Boulos ma n sapejuwe Naijiria gẹgẹ bi ile.

O sọ ninu ifọrọwanilẹnu kan pẹlu iwe iroyin The Punch pe ẹbí oun di ara Naijiria lẹyin ti baba rẹ ra ileesẹ SCOA Nigeria Plc.

Ọkan lara awọn oludari ileesẹ SCOA ni Michael Boulos to n fẹ ọmọbinrin Trump.

Bakan naa lo tun jẹ oludari nileesẹ Fadoul Group ati Alamojuto idagbasoke ileesẹ Royalton Investment lati ọdun 2019.

Ileewe girama American International School to wa nipinlẹ Eko ni Michael lọ.

Àkọlé fídíò, Joe Biden Innauguration: Tani ìyàwó Joe Biden tí yóò jẹ obìnrin akọ̀kọ nílẹ̀ Amẹrika?

Lẹyin naa lo gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu imọ eto okoowo l'agbaye, ni Regent University nilu London.

O tun gba oye imọ ijinlẹ keji ni City University, nilu London bakan naa.