Sudan removed from terrorist list: America yọ Sudan kúrò nínú ìwé orílẹ̀-èdè tó ń ṣagbátẹrù ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí lágbàyé

Oríṣun àwòrán, @Suribelle1
Ọọfisi ijọba ilẹ Amẹrika to wa ni Khartoum ti kede pe wọn ti yọ orukọ orilẹ-ede Sudan kuro lara awọn orilẹ-ede to n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ agbesumọmi lagbaye.
Ninu atẹjade kan ti ijọba Amẹrika fi lede loju opo Facebook rẹ lo ti kede ipinu naa.
Ikede naa ni "lẹyin ifitonileti ọlọjọ marundinlaadọta, akọwe ijọwe ijọba ti buwọlu adehun ti a fi yọ orilẹ-ede Sudan kuro lara awọn orilẹ-ede to n ṣagbatẹru iṣerubalu lagbaye."
Ṣaaju ni Aarẹ Donald Trump ti kọkọ kede loṣu Kẹwaa pe jọba Amẹrika yoo yọ orukọ Sudan kuro lara awọn orilẹ-ede agbesumọmi naa lẹyin to ba ti san owo itanra $335 miliọnu fun awọn ẹbi atawọn eeyan to fara gba ninu akọlu ẹgbẹ al-Qaeda si ọọfisi ijọba Amẹrika lọdun 1998.

Oríṣun àwòrán, US embassy Khartoum
Olori ijọba orilẹ-ede Sudan, Abdalla Hamdok si ti fesi pe wọn ti fi owo naa ranṣẹ.
Wọn fi orukọ Sudan sinu iw gẹgẹ bii ọkan lara awọn orilẹ-ede to n ṣagbatẹru awọn ẹgbẹ agbesumọmi lọdun 1993 pẹlu Iran, North Korea ati Syria.
Ijọba Amẹrika gbe igbesẹ naa lẹyin ti adari ikọ al-Qaeda, Osama Bin Laden fi orilẹ-ede naa ṣebugbe lọdun naa lọhun, gẹgẹ bii alejo ijọba.










