Kankara Abduction: Àwọn ológun ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi yọ̀nda àwọn tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé.

Ile iṣẹ ologun Naijiria ti ṣipaya awọn nkan kọọkan lorii bi wọn ṣe ri awọn akẹkọọ to le ni ojilelọọdunrun ti awọn ajinigbe ji gbe ni ileewe Kankara, ipinlẹ Katsina doola pada.
Awọn ologun ṣipaya pe ati agbara ohun ija oloro ati eyi tii kii ṣe ti ohun ija lawọn papọ fi ri i pe wọn doola gbogbo awọn ọmọ ọkunrin naa lai farapa.
Alakoso eto irorin fun ileeṣẹ ologun, Ọgagun John Enenche ati oludari ẹka ọgbọ tẹlẹ nileeṣẹ ologun, Ọgagunfẹyinti Ahmed Jibrin lo ṣe ẹkunrẹrẹ alaye bi wọn ṣe ṣe e lọjọ Abamẹta lori eto oroorọ ileeṣẹ amohunmaworan Nigerian Television Authority, NTA.
Jibrin ni lẹyin ti wọn ji awọn ọmọ naa gbe, minisita dari ikọ awọn olori awọn ologun ati olugbaninimọran nipa abo lọ si Katsina ati Kankara.
O ni minisita paṣẹ pe ki ikọ awọn ọmọ ogun ri i pe wọn doola awọn ọmọkunrin naa lai farapa ati ni kiakia.
"Kete lẹyin aṣẹ naa ni awọn ọmọ ogun gba ọna mẹrin ọtọọtọ lati doju kọ awọn ajinigbe ọhun pẹlu iranlọwọ kaakiri lati ri i pe wọn di gbogbo agbegbe ti wọn wa gbagba".
O ni awọn ajinigbe ọhun mọ pe awọn ti wa ni ahamọ awọn ologun tori wọn ni imọlara pe wọn ti wa lagbegbe lati inu afẹfẹ ati loriilẹ.
"Nigba ti wọn sunmọ ibi ti awọn ọmọ naa wa, ikọ ọmọ ogun doju kọ atako loriṣiriṣi eyi ti wn mu kuro ti wọn si tẹra mọ wiwọ inu aginju lọ".
Jibirin ṣalaye pe bo tilẹ jẹ ko si ikankan ninu awọn ọmọ wọn ba agbara ọpọlọpọ awọn ọdaran naa jẹ. "Wọn di awọn ologun lọwọ irina fun ọpọlọpọ wakati ki wọn to ri wọn bori".
O ni nigba ti awọn ọmọ ogun n ṣe tiwọn, bẹẹ naa ni idunadura ọrọ n lọ lẹgbẹ mii fun idoola wọn.
O jẹ ko di mimọ pe wọn ko lee sọ awọn ajinigbe naa di alailagbara patpapata toripe ṣe ni wọn n fi awọn akẹkọọ daabo bo ara wọn awọn ko si fẹ pa awọn ọmọ na lara.
Lorii bi Boko Haram ṣe n pariwo pe awọn lawọn ji wọn gbe, Jibrin ni irọ ni, wọn kan n wa ọna ati gbajumọ sii ni.
"(Abubakar) Shekau ko ni ọna kankan lati ji wọn gbe toripe ọpọ igbesẹ ti jade lati bẹgi dina wọn lkun Ila Oorun-Ariwa torinaa o han daju pe awọn ajinigbe lo ji awọn ọmọ naa".
Ni tirẹ, Enenche ni nkan to lewu gidi ni igbesẹ ti wọn gbe lati doola awọn akẹkọọ ọhun tori bi wọn ko ba fi ikọṣẹmọṣẹ ṣe iru iṣẹ yii, o lee yiwọ.
"Ogun ti oo le gboju le agbara rẹ ati ohun ija ni eyi bikoṣe ipa too ni lati ṣe e yanju".
"Eyi tumọ si pe o ni lati pa awọn ọta rẹ lẹnu mọ koo si gba ohun too fẹ gba lai yin ọta ibọn kan ṣoṣo".
O ni bi nkankan ba ṣe awọn akẹkọọ ọhun ni, awọn ologun naa lawọn ọmọ Naijria yoo da ẹbi rẹ le lori.
Agbẹnusọ gomina Aminu Masari fi aridaju han pe lootọ ni awọn ọmọ naa ti darapọ mọ ẹbi wọn pada lalafia lẹyin ayẹwo ilera fihan pe ara wọn pe.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Irú iṣẹ́ wo ní Funke Akindele rán sí Bukunmi Oluwasina, tó fa ariwo lórí ayélujára?
- Ẹ̀ẹ̀kan láàrin ọjọ́ méjì là ń jẹun ní ìgbèkùn, ìyà jẹ wá - Akẹ́kọ̀ọ́ Kankara ṣàlàyé
- Sé Boko Haram ń pẹ̀ka kiri Nàíjíríà ní ìjínigbé ṣe burú báyìí?
- Ọla Adedibu ní Ladoja jẹ̀ tó fi wọlé Gómìnà l‘Oyo labẹ ẹgbẹ́ PDP - Obasanjo
- Ẹ̀sìn kò fàjà! Obìnrin Mùsùlùmí ṣe ilé àlúfà ní ọ̀ṣọ́ fún Kérésìmesì
- Àwọn gómìnà nílẹ̀ Yorùbá ti kùnà láti pèsè ààbò tó péye fún aráàlú - Ẹgbẹ́ Majeobaje
Amẹ́ríkà yarí pé àwọn agbégbọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ 344 gbọ́dọ̀ fojú winá òfin
Bi afẹfẹ alafiaa ti ṣe n fẹ lu ijọba ati awọn obi tọmọ wọn jajabọ lọwọ ajinigbe ni Katsina, ijọba Amẹrika ti n kesi awọn tọrọ kan pe, ki wọn maa gbagbe lati tọ pinpin awọn to wa nidi iṣẹlẹ yi.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ asoju orileede Amẹrika to wa ni Naijiria fisita, ni ọrọ yi wa.
Ileesẹ Amẹrika wa bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ifipajinigbe awọn akẹkọọ to le ni ọọdunrun naa.
Bakan naa ni wọn ba awọn mọlẹbi tọmọ wọn sọnu kẹdun ati awọn ẹsọ alaabo to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ yii.
Amrika wa tẹpẹlẹ mọ bo ti ṣe pataki to ki ile ẹkọ jẹ aaye ifọkanbalẹ tawọn ọmọ ti le kẹkọ, ti wọn yoo si ti gbooro si.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Lakotan, Amẹrika ni o ṣe dandan ki ijọba ri wipe awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ ijinigbe naa foju wina ofin debi to lapẹrẹ.
Titi di igba ti awọn ọmọ yi fi pada de, ko si ihalẹ to milẹ lati ọdọ ijọba Katsina tabi ijọba apapọ lori pe awọn yoo fiya jẹ ẹnikẹni to ba mọ si ijingbe awọn akẹkọọ yii.
Eyi to pọ ninu ọrọ wọn ni ki wọn kọkọ ri awọn ọmọ yi lalaafia.

Ko ti si aridaju boya wọn sanwo idoola lati fi gba awọn ọmọ yi pada.
Amọ Gomina ipinlẹ Katsina sọ pe ẹgbẹ Miyetti Allah ko ipa ribiribi ninu idunadura ti wọn fi doola ẹmi awọn akẹkọọ naa.

Ọ̀fẹ́ ló bá dé, a kò san kọ́bọ̀ fún ìdáǹdè akẹ́kọ̀ọ́ 334 - Masari
Orin lọfẹ-lọfẹ ni baba fun wa lo gba ẹnu ijọba apapọ Naijiria kan lori itusilẹ awọn akẹkọ-kunrin ni Katsina, ti Boko Haram mu sigbekun.
Nigba to n fidi itusilẹ awọn akẹkọọ naa mulẹ, gomina ipinlẹ Katsina, Aminu Bello Masari ni koko lara awọn akẹkọ naa le, ti wọn si wa nilu Tsafe nipinlẹ Zamfara, nibi ti wọn yoo ti gbe wọn wa silu wọn Kankara loni ọjọ Ẹti.
Masari ni ikọ darandarn labẹ ẹgbẹ Miyetti Allah ati Macaban lo seranwọ lati gba idande awọn akẹkọọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣé lóòtọ́ ni Bimpe Oyebade lóyún fún Lateef Oladimeji?
- Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nìkan ni ọ̀nà abáyọ sí ìṣòro Nàìjíríà- Olusegun Obasanjo
- Buhari, o ṣẹ ilẹ̀ Yorùbá púpọ̀, ló àyájọ́ ìbí rẹ̀ láti tọrọ àforíjìn - PDP
- Ìtura ìgbà díẹ̀ ni bọ́dà tí ìjọba ṣí padà, kò lóòre nínú - Onímọ̀ ọrọ̀ ajé
- Wo ìdí tí ààrẹ Buhari kìí fi ṣe ẹ̀dà Jubril láti Sudan
- Àwọn ohun kàyéèfì tó le mú kí ọmọbìnrin ní oyún ìju
Bakan naa lo fikun pe ijọba apapọ ko san eepinni fawọn ajọmọgbe naa, idunadura lasan ni awọn se.
"Lara awọn to kopa ninu eto idunadura naa ni olugbaninimọran mi, awọn lọga-lọga lẹnu isẹ ologun, ọlọpaa ati ikọ Miyetti Allah.
Masari tun fikun pe awọn janduku agbesunmọmi lasan lo ko awọn akẹkọọ naa, wọn kii se Boko Haram.
Ijọba wa fidi rẹ mulẹ pe awọn akẹkọọ naa yoo de ọdọ awọn obi wọn ki ilẹ ọjọ Ẹti oni to su.
Ìjọbá ti dóòlà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 340 ti wọ́n jí gbé ni GSSS Kankara, ìpińlẹ̀ Katsina

Oríṣun àwòrán, Boko Haram
Ìròyìn tó tẹ ilé iṣẹ́ BBC lọ́wọ́ sọ pé, àwọn ọmọ tó lé ni ọ̀ọ́dúnrún ni ilé ìwé GSSS Kankara ti wọ́n jí gbé tí gba òmìnir báyìí.
Gẹ́gẹ́ bi àkọwé àgbà fún ìpínlẹ̀ Katsina Alhaji Mustapha Inuwa ṣe sọ, àwọn ọmọ náà ti wà ni Tsafe, ní ìpínlẹ̀ Zamfara to pa ààlà pẹ̀lú Katsina.
Ó fi kun pé, àwọn ọmọ náà yóò de ìpínlẹ̀ Katsina ni alẹ́ òní pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹlétò ààbò tí wọ́n yóò wọ́n yóò sì fójú kan ààrẹ.
Ìrìnàjò Tsafe sí Zamfara tí kílomita ìgba àti díẹ̀, èyí yóò gbà wọ́n ni wákàtí mẹ́tà kí wọ́n tó débẹ̀ nítóri ipò tí ọ̀nà náà wà nígbà ti Tsafe sí kankara jẹ́ kílòmítà mẹ́tàlélọ́gọ́rín
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà ti àwọn ọmọ náà ti wà ni ọwa àwọn ajínigbe.
Abike Dabiri ní akẹ́kọ̀ọ́ 333 tí gba ìtúsílẹ, àmọ́ kò pẹ́ ló tún pahùndà

Oríṣun àwòrán, Katsina govt
Àwọn aláṣẹ ìjọba ni Nàìjíríà ti kéde pé àwọn ọmọ tó lé ní ọ̀ọ̀dúrún tí àwọn ajínígbé kó nílé ìwé ìjọba ni ìlú Kankara nípìnlẹ̀ Katsina, ti gba ìtússílẹ̀
Lórí àtẹ̀jíṣẹ́ twitter lọ́sàn òní ni, alága àjọ tó n ri sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ okere Abike Dabiri Erewa sàlàye pé, àwọn ti rí àwọn ọmọ náà gbà.

Oríṣun àwòrán, Dabiri
Sáájú àsìkò yìí, ní fọ́nran kan jẹyọ níbi ti àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ ti wọ́n jí gbé náà ti n bẹ ìjọba pé, ko dá isẹ idoola ẹmi to n se duro, ko si ko gbogbo àwọn sójà pàda si bareke.
Bakan naa ni ọmọ to sọrọ ninu fidio naa ni ki ijọba mase gbiyanju lati wá tu àwọn sílẹ̀ ni ahamọ Boko Haram.

Oríṣun àwòrán, Boko Haram
Ọmọkunrin náà wa bẹ́ ìjọba pé ko bá àwọn ajínígbé sọ̀rọ̀ lórí ǹkan tí wọ́n ba fẹ́ gbà kí àwọn le lọ ilé àwọn ni àlááfíà.
Ẹ̀wẹ́, Abike Dabiri ti tún kọ sórí àtẹjíṣẹ́ twitter rẹ̀ pé, kìí ṣe òun ni òun kọ àkọlé pé àwọn ọmọ náà ti gba ìtúsílẹ̀ àti pé, ó ṣeeṣe kó jẹ́ àwọn ènìyàn tó ló àtẹ̀jísẹ́ òfégè ni orúkọ òun ló kọ̀ọ́.

Oríṣun àwòrán, Abike/ Dabiri
Èyí ti mú kí ọ̀pọ ọmọ Nàìjíríà máá pé alága NICOM síta pe opurọ ni.
Koda, awọn kan ni ipilẹ orilẹede naijiria ni wọn fi irọ mọ, tawọn kan si ni igbe aye ayederu gan ni Abike Dabiri n gbe funrarẹ.

Oríṣun àwòrán, Abike dabiri
Wayi o, ko sẹni to ti le fi okodoro ọrọ mulẹ boya lootọ ni awọn akẹkọkunrin to le ni ọọdunrun naa ti ri idande gba abi bẹẹ kọ.
Sugbọn bo ba se jẹ, a ko ni jẹ ki eti yin di nipa isẹlẹ naa.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara ti pàṣẹ kí wọ́n gbé iléèwé mẹ́wàá tìpa lẹ́yìn ìkọlù Katsina

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@BELLOMATAWALLE1
Ijọba ipinlẹ Zamfara ti fofin sita ni kiakia pe ki wọn gbe awọn ileewe ti awọn akẹkọọ ti n gbe ninu ọgba ileewe atawọn ileewe alalọde kan tipa ni ipinlẹ naa.
Agbẹnusọ fun gomina Zailani Bappah lo fidi ọrọ̀ yii mulẹ fun BBC.
Iroyin taa gbọ ni Ọgbẹni Ibrahim Abdullahi to jẹ Kọmisọna eto ẹkọ ṣe ikede yii nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ nilu Gusau, olu ilu ipinlẹ naa.
O ṣalaye pe awọn ileewe to fara gba aṣẹ yii pa aala pọ pẹlu ipinlẹ Katsina ti wọn ti ṣẹṣẹ ji awọn akẹkọọto le lọọdunrun gbe, ipinlẹ Kaduna ati Sokoto.
Kọmisọna ọhun jẹ ko di mimọ pe awọn ipinlẹ mẹtẹta yii sun mọ bebe idigunjale to si ni ipinu yii ṣe pataki lati dena ikọlu mii si awọn ileewe ọhun.
- Ṣé lọ́òtọ́ ni ọlọ́pàá dàwátì torí àti dóòlà aráa India méjì tí wọ́n jígbé?
- Ìròyìn ayọ̀! Omah Lay, Ms. Tems ti gba ìtúsílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Uganda
- Wọ́n ní kí ọ̀gá àgbà "Ede Poly" lọ rọ́kún nílé lórí ẹ̀sùn pé ó kan bẹ́ẹ̀dì sí ọ́fíìsì
- Wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìpàdé àwọn èèkàn Yorùbá láti mú kẹ́ẹ dìbò fún Tinubu ní 2023
O fi kun un wipe igbesẹ ọhun gan ṣe pataki nitori iṣoro aabo to wa lorilẹede yii ati lati dena iru nkan to ṣẹlẹ nileewe Girama Government Science Secondary School ni ilu Kankara, ipinlẹ Katsina.
Abdullahi fi da awọn obi ati alagbatọ loju pe aabo awọn akẹkọọ lo ṣe koko si ijọba ipinlẹ to fi mu wọn gbe igbesẹ naa.
O fi lede pe ijọba ti pari gbogo eto bi wọn yoo ṣe ko awọn oṣiṣẹ alaabo lọ maa ṣọ awọn ileewe to ku ti wọn ko tipa.
Lara awọn ileewe to fara gba aṣẹ tuntun yii ni ileewe meje tawọn akẹkọọ n gbe ninu ọgba rẹ atawọn ileewe alalọde mii.
Awọn ileewe ti akẹkọọ n gbe nibẹ ni G.S.S. Tsafe, G.S.S. Magaji, G.A.S.S. Zurmi, G.G.S.S. Moriki, Science Secondary School Shinkafi, Science Secondary School Dansadau, ati Science Secondary School ni Bukkuyum.
Bakan naa, awọn ileewe alalọde to wa lara wọn ni G.D.S.S. ni Nasarawa Mailayi, G.D.S.S Gusami, ati G.D.S.S. Gurbin Bore.
Ta gan ló jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ GSSS Kankara, àwọn jàǹdùkú tíjọba mọ̀ ni tàbí Boko Haram?

Oríṣun àwòrán, @Aminu Bello Masari
Ìjọba ní àwọn jàǹdùkú ló jí akẹ́kọ̀ọ́ ní Kankara, Boko Haram tún ti jáde pé àwọn ni, èwo gan an lèwo?
Awọn ọmọ ikọ agbesunmọmi Boko Haram ti fi ohun sita pe awọn lawọn ji awọn akẹkọọ ni girama Kankara ni ipinlẹ Katsina.
Ninu fọnran agbohunsilẹ kan ti olori ẹgbẹ naa, Abubakar Shekau fi sita, lẹyin ọjọ mẹta ti wọn ji awọn ọmọ naa gbe.
Eyi waye lasiko ti ijọba ipinlẹ Katsina n sọ pe awọn janduku lo ji awọn akẹkọọ ileewe girama Dankara Science Secondary School naa gbe ati pe ijiroro ti n lọ laarin ijọba atawọn janduku naa lori ohun ti wọn fẹ fun itusilẹ awọn ọmọ naa.
Eyi ti fa ọpọlọpọ ariyanjiyan ati ibeere pe ta gan an lo ji awọn ọmọ yii gbe?
Ijọba ni awọn janduku agbebọn kan ti kan si awọn pe awọn lawọn ṣiṣẹ laabi naa ti wọn si ti bẹrẹ idunadura, pẹlu bi ikọ Boko Haram tun ṣe sọ tirẹ yii, ewo lewo ni ibeere to gbẹnu ọmọ kan.
Gomina Bello Masari ṣalaye lasiko to ba aarẹ Buhari lalejo nileerẹ nilu Daura pe awọn ileeṣẹ alaabo ati ologun ti ri ibuba awọn janduku naa wọn si ti n gbe igbesẹ lori rẹ.

Oríṣun àwòrán, @Aminu Bello Masari
Àwọn tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ GSSS gbé ní Kankara ti kàn sí wa - Masari
Gomina ipinlẹ Katsina, Bello Masari ti sọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari pe awọn to ji awọn akẹkọọ ile iwe girama to wa ni Kankara, ni ipinlẹ naa ti kan si awọn.
Oluranlọwọ pataki si Aarẹ, Garba Shehu lo fi ọrọ naa lede lẹyin abẹwo ti Masari ṣe si Aarẹ Buhari ni ilu Daura.
O ni "gomina ọhun, tohun ti igbakeji rẹ, Manir Yakubu sọ pe awọn agbebọn naa ti kan si wọn, ati pe idunadura ti n lọ lori bii awọn akẹkọọ naa yo ṣe pada wale."
O ṣalaye pe awọn ẹṣo alabo ti mọ agbegbe ibi ti awọn ọmọ naa wa, ati pe awọn ọmọ Naijiria yoo gbọ iroyin ayọ nipa awọn ọmọ naa laipẹ.
Gomina Masari sọ pe afojusun Aarẹ Buhari ni lati ṣawari awọn ọmọ ọhun.
Oru ọjọ Ẹti to kọja ni awọn janduku agbebọn kan ṣadede kọlu ileewe naa to wa fun awọn akẹkọọ ọkunrin nikan, ti wọn si ji awọn akẹkọọ kan gbe, nigba ti awọn miran sa asala fun ẹmi wọn.
Ṣaaju ni ariyanjiyan ti kọkọ waye lori iye awọn akẹkọọ to poora ni pato, ṣugbọn lẹyin ọjọ meji ni gomina Masari sọ pe nnkan bii ọọdunrun akẹkọọ lo di awati.
Akẹ́kọ̀ọ́ 333 ni a kò tíì le sọ nípa wọn nílé ẹ̀kọ́ Kankara Katsina- Ìjọba Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @Aminu Bello Masari
Akẹ́kọ̀ọ́ 333 ni a kò tíì le sọ nípa wọn nílé ẹ̀kọ́ Kankara Katsina- Ìjọba Nàìjíríà
Iroyin tuntun nipa awọn akẹkọọ girama GSSS Kankara Katsin nipe pupọ ninu awọn akẹkọọ naa ni ko ti i di riri lẹyin ọjọ kẹta.
Gomina ipinlẹ Katsina, Aminu Bello Masari sọ fun awọn akọroyin pe, akẹkọọ 333, ni awọn ko ti i ri pada.
O sọ ọrọ naa lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn eleto aabo ni alẹ ọjọ Aiku.
Gomina naa ṣalaye pe 849 ni gbogbo akẹkọọ to wa ni ile ẹ̀kọ́ naa. Inu ọgba ile ẹ̀kọ́ ni awọn ọmọ naa n gbe.
Alẹ ọjọ Ẹti ni awọn afurasi janduku kọlu ile ẹ̀kọ́ náà, eyi to fa awuyewuye jakejado Naijiria.
Ijọba orilẹ-ede Naijiria si ti sọ pe awọn ọmọ ogun ti yi agbegbe ti wọn fura si pe ibẹ ni awọn agbebọn naa fi ara pamọ si.

Oríṣun àwòrán, @Aminu Bello Masari
Gomina Bello Masari fi kun ọrọ rẹ pe oun ti ṣe ipade pẹlu awọn lọga-lọga nileesẹ ologun, lẹyin ti oun ṣe abẹwo si ile ẹ̀kọ́ naa, ati aarin ilu to wa.
Gomina naa ni: ni ipade naa jẹ akitiyan ijọba lati le gba ẹ̀mí awọn ọmọ naa la.
Sugbọn, tako nkan ti Gomina Masari sọ, agbenusọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu, sọ fun BBC pe awọn ọmọkùnrin to raaye sa mọ agbebọn naa lọwọ sọ pe ọmọ mẹwaa lo si wa ni ọdọ awọn agbebọn.

Oríṣun àwòrán, @Aminu Bello Masari
Iye àwọn ti Shehu sọ yii kere si nkan ti awọn oṣiṣẹ ile ẹ̀kọ́ naa ti kọkọ sọ.
Igba lara wọn lo ti pada sile, sugbọn Ọgbẹni Shehu sọ pe ijọba ń gbiyanju lati mọ iye akẹkọọ to ṣe e ṣe ko fọn kaakiri agbegbe naa, lẹyin ti wọn sa lasiko ikọlu to waye.
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣoro ní Ijebu Ode, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sọnù
- Ara mi rẹwà ló jẹ́ kí n máa ṣí ara sílẹ̀- Victoria Kolawole
- Èyí ni àwọn aṣíwájú ìjọba tí ajé ìwà ìjẹkújẹ ti ṣí mọ́ lórí láàrin ọdún 1960 sí àsìkò yí
- Mo ti kúrò ní ààfin Oyo, kí ìròyìn tó ò jáde pé èmi àti Wasiu Ayinde n fẹ́ ara wa - Olori Badirat
- Ṣé lóòtọ́ ni tírélà ti gba ààrín Ronke Odusanya àti bàbá ọmọ rẹ̀, Jago? Nkan tí a mọ̀ nìyíì
Awọn eleto aabo sọ pe bi ọjọ ṣe n gun ori ọjọ, ni didoola àwọn ọmọ naa yoo ma a ṣòro si, paapa ti awọn ọmọ naa ba ti tuka, tabi ti awọn agbebọn ba ko wọn si ibi ọtọọtọ.
Ọpọ eeyan lo si ti n bu ẹnu ẹtẹ lu Aarẹ Muhammadu Buhari, nitori pe ko yọjú si ile ẹ̀kọ́ naa, bo tilẹ jẹ pe o wa lẹnu ìsinmi nipinlẹ Katsina.
Dipo bẹ ẹ, igbimọ aṣoju lati ilu Abuja, ni Buhari ran lọ.
Irinajo to le diẹ ni wakati meji ni Kankara si ilu Daura ti Buhari wa.
Ẹwẹ, àwọn obinrin kan ti ṣe iwọde, nipinlẹ Katsina, lati beere fun ominira àwọn akẹkọọ ile ẹ̀kọ́ GSSS, Kankara.
- Ogun abẹ́lé tó ń ja Akeredolu l'Ondo, òní la ó mọ̀ bóyá yó borí rẹ̀
- Wo àwọn ohun tí Amotekun kò ní le è ṣe mọ́ ní ìpínlẹ̀ Oyo...
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣoro ní Ijebu Ode, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sọnù
- Ara mi rẹwà ló jẹ́ kí n máa ṣí ara sílẹ̀- Victoria Kolawole
- Ṣé lóòtọ́ ni tírélà ti gba ààrín Ronke Odusanya àti bàbá ọmọ rẹ̀, Jago? Nkan tí a mọ̀ nìyíì
























