Muhammadu Buhari: PDP ṣàlàyé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ààrẹ bó ṣe ń ṣàjọyọ̀ ọ̀jọ́ ìbí

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Adesina
Ẹgbẹ oselu PDP ti fi ọrọ iyanju ransẹ si aarẹ Muhammadu Buhari ni ayajọ ọjọ ibi ọdun kejidinlọgọrin to ko l'Ọjọbọ.
Atẹjade kan ti ẹgbẹ oselu PDP fisita lọjọ ayajọ aarẹ naa wa kesi Buhari lati tete wa aforijin lọwọ awọn ọmọ orilẹede yii dipo ko maa se ajọyọ ọjọ ibi.
PDP ni aarẹ sẹ awọn eeyan ẹkun iwọ oorun Naijiria pupọ, boya Ọlọrun si da si lati se ọjọ ibi ọdun kejidinlọgọrin ni, ko ba le ni anfaani lati ronu nipa awọn asise rẹ, ko si ronu piwada.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣé lóòtọ́ ni Bimpe Oyebade lóyún fún Lateef Oladimeji?
- Ìtura ìgbà díẹ̀ ni bọ́dà tí ìjọba ṣí padà, kò lóòre nínú - Onímọ̀ ọrọ̀ ajé
- Wo ìdí tí ààrẹ Buhari kìí fi ṣe ẹ̀dà Jubril láti Sudan
- Ẹ dín agbára ìjọba àpapọ̀ kù, kẹ ṣì ṣe àgbékalẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ - Tinubu bẹ̀bẹ̀
- Wo eyi to súnmọ́ ọ nínú àwọn ibùdó 203 fún ìforúkọsílẹ̀ fún NIN rẹ
- Adigunjalè méjì ko ìjàmbá ọ̀kadà lẹ́yìn ìṣẹ́ ibi n‘Ibadan, ọ̀kan kú lójijì, aráàlú dáná sun èkejì
- Àwọn ohun kàyéèfì tó le mú kí ọmọbìnrin ní oyún ìju
- Ìrẹ̀sì kò gbọdọ̀ wọlé níbáyìí ta ṣí ẹnu bodè padà - Ìjọba àpapọ̀
- Jide Kosoko forin sẹ́nu pé òun ni igi lẹ́yìn ọgbà Mr Latin lórí ipò ààrẹ TAMPAN tó wà
Atẹjade ẹgbẹ oselu PDP naa, ti akọwe ipolongo ẹgbẹ fun ẹkun iwọ oorun guusu, Lere Olayinka fọwọsi, wa mu wa siranti nipa ohun ti Buhari se awọn eeyan ẹkun iwọ oorun Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Adesina
"Aarẹ Buhari, nigba to jẹ olori Naijiria labẹ ijọba ologun, da ọkan awọn eeyan ẹkun naa laamu, to si tun kẹyin si ẹkun yii lasiko to jẹ alaga igbimọ apo asunwọn ẹdawo epo rọbi, PTF lasiko ijọba Sani Abacha."
O fikun pe ẹsẹ ti Buhari sẹ awọn eeyan ẹkun iwọ guusu Naijiria julọ ni bo se wọgile oju ọna ọkọ ayarabiasa ti wọn pe ni Metroline, tijọba Lateef Jakande gbe kalẹ.
"Isẹ lila oju ọna Metroline ti Buhari wọgile naa lo jẹ adanu fawọn eeyan ipinlẹ Eko, eyi towo rẹ to miliọnu lọna mejidinlọgọrin Dọla.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Adesina
To ba jẹ pe Buhari ko wọgile akanse isẹ oju ọna naa ni, sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ to n lu igboro ilu Eko pa bayii ko ba ti waye, ti irọrun ko ba si bawọn olugbe Eko nidi igbokegbodo ọkọ."
Ẹgbẹ oselu PDP wa ki aarẹ Buhari ku oriire ọjọ ibi ọdun kejidinlọgọrin to ko, ti wsn si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o mu aarẹ se ọjọ ibi ọdun yii.
Alfa Jamiu rèé tó lu Kọ̀ráà ní jìbìtì ₦30m àmọ́ tó fi owó ra ìfun Erin àti ẹ̀dọ̀ Ìnàkí

Oríṣun àwòrán, Facebook/EFCC
Ọwọ awọn agbofinro EFCC ti tẹ alfa kan torukọ rẹ n jẹ Jamiu Isiaka, to sọ ara rẹ di ọga ti n gba aṣọ alaṣọ bora nipa pipe ara rẹ ni alukoro fun aarẹ Buhari, Fẹmi Adeṣina.
Lati ipasẹ fifi ara ẹni pe ẹlomiran yii, lo ti lu oyinbo Koraa kan ni jibiti owo to to Ọgbọn miliọnu naira niye.
Bakan naa ni Alfa Jamiu tun dibọn pe oun ni oludari agba tẹlẹ fun ileeṣẹ ipọnpo rọbi orilẹede Naijiria, NNPC, lati ṣe gbajuẹ fun oyinbo Koraa naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ dín agbára ìjọba àpapọ̀ kù, kẹ ṣì ṣe àgbékalẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ - Tinubu bẹ̀bẹ̀
- Wo ìdí tí ààrẹ Buhari kìí fi ṣe ẹ̀dà Jubril láti Sudan
- Wo eyi to súnmọ́ ọ nínú àwọn ibùdó 203 fún ìforúkọsílẹ̀ fún NIN rẹ
- Adigunjalè méjì ko ìjàmbá ọ̀kadà lẹ́yìn ìṣẹ́ ibi n‘Ibadan, ọ̀kan kú lójijì, aráàlú dáná sun èkejì
- Àwọn ohun kàyéèfì tó le mú kí ọmọbìnrin ní oyún ìju
- Ìrẹ̀sì kò gbọdọ̀ wọlé níbáyìí ta ṣí ẹnu bodè padà - Ìjọba àpapọ̀
- Jide Kosoko forin sẹ́nu pé òun ni igi lẹ́yìn ọgbà Mr Latin lórí ipò ààrẹ TAMPAN tó wà
- Ó pé ọdún mẹ́wàá tí Barrister kú; wo ǹkan tó yẹ láti mọ̀ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olórin, tẹ̀wé-tẹ̀wé, akọ̀wé àti sọ́jà
- Àìmọ̀kan ló mú mi hu ìwà tí mo hù kọjá sẹ́yìn, Jonathan dárí jì mí - Dino Melaye
Nigba ti wọn n foju rẹ han faye ri, EFCC ni oniruuru ọgbọn arumọjẹ ni Jamiu ti fi gba oyinbo Koraa naa, ti orukọ rẹ n jẹ, Keun Sig Kim lati orilẹede South Korea.

Oríṣun àwòrán, Instagram/EFCC Nigeria
Jamiu ni oun fẹ ba eebo Kọraa naa gba aṣẹ lọwọ ajọ elepo rọbi NNPC, lati maa ra epo rọbi ni Naijiria.
Nigba ti wọn bii, Afaa Jamiu ni gbogbo owo ti oun gba lọwọ arakunrin naa, ẹbọ ati etutu ni oun fi ṣe fun un.
O ni ẹyẹ igun, awọ erin, ifun erin, ori ẹkun ati ẹdọ inaki loun fi owo gbajuẹ ọhun ra.
Amọṣa EFCC ni iwadii awọn fihan pe, ile nla ni Afaa Jamiu kọ silu Ilọrin lara owo to gba lọwọ oyinbo Koraa, Keun Sig Kim.
Ni ọjọ kẹrinla oṣu kẹfa ọdun 2019, ni ajọ EFCC kọkọ fi oju Afaa Jamiu ba ile ẹjọ lori ẹsun mẹrin ọtọọtọ to nii se pẹlu iwa gbajuẹ ati jibiti lilu.














